Iwọ Ha Le Layọ Pẹlu Pupọ Lati Ṣe Bi?
ỌPỌJULỌ ninu wa ngbe igbesi-aye ti o kún fọ́fọ́, lọpọ igba ti o kun fun igbokegbodo. Ikimọlẹ alaidawọ duro ti igbesi-aye ode oni nbeere pe ki awa lo isapa ti nbaa lọ kiki lati tẹ̀ siwaju. Awọn ọkọ ati awọn baba gbọdọ bojuto awọn ẹru iṣẹ aigbọdọmaṣe wọn si idile, awọn agbanisiṣẹ wọn ati awọn ẹlomiran. Awọn iyawo ati iya gbọdọ bojuto awọn aini agbo idile wọn ti wọn si tun gbọdọ siṣẹ ounjẹ oojọ nigba miiran. Awọn ọdọ pẹlu wa labẹ ikimọlẹ lati maa baa lọ ni ṣiṣe iru awọn iṣẹ aigbọdọmaṣe pato kan ninu ile nigba ti wọn nṣakitiyan lati jere ẹkọ kan ti yoo mura wọn silẹ fun ojuṣe ameso jade ninu awujọ.
Ṣugbọn ki ni nipa ti awa ti a ti ya igbesi-aye wa si mimọ fun Jehofa Ọlọrun ti a si jẹ Ẹlẹrii rẹ ti a ti baptisi? Ni afikun si gbogbo awọn ohun abeere fun miiran ti o nbeere afiyesi wa, a fun wa ni iṣileti apọsteli Pọọlu yii pe: “Nitori naa ẹyin ara mi olufẹ, ẹ maa duro ṣinṣin, laiyẹsẹ, ki ẹ maa pọ sii ninu iṣẹ Oluwa nigba gbogbo, niwọn bi ẹyin ti mọ pe iṣẹ yin kii ṣe asan ninu Oluwa.” (1 Kọrinti 15:58) Bẹẹni, ọpọlọpọ awọn afikun ẹru iṣẹ jẹ apakan ohun ti ijọsin tootọ beere fun. Bawo ni awa ṣe le mu awọn iṣẹ aigbọdọmaṣe wọnyi ṣẹ ki a si ni alaafia ọkan ati irisi alayọ?
Aṣeyọri Nmu Ayọ Wa
Ayọ—imọlara alaafia ara tabi itẹlọrun—ni ibatan timọtimọ pẹlu aṣeyọrisi rere ninu bibojuto awọn ẹru iṣẹ igbesi-aye. Bi o ba ṣeeṣe fun wa lati doju ìlà awọn iṣẹ aigbọdọmaṣe ojoojumọ wa ni ọna ti o gbeṣẹ ti o si bọgbọn ironu mu ni ṣiṣe awọn nǹkan ni akoko ati letoleto, awa yoo ni imọlara aṣeyọri ati itẹlọrun. Bi o ṣe yẹ ki o ri niyẹn, abajade rẹ si nṣafikun ayọ wa.
Jehofa Ọlọrun ko figba kan ri lae nilọkan pe bibojuto awọn ẹru iṣẹ wa nilati jẹ ẹru wiwuwo ti nninilara. Kaka bẹẹ o ti figba gbogbo jẹ idaniyan rẹ pe ki a ‘yọ ayọ ki a si ri rere ninu gbogbo iṣẹ aṣekara wa.’ (Oniwaasu 3:12, 13) Nigba ti a ba layọ ninu iṣẹ wa, awa yoo figba gbogbo maa meso jade. Awa yoo ṣetan lati gba itọni ti a o si fi alaafia ba awọn ẹlomiran ṣe pọ. Lọwọ keji ẹwẹ, bi awa ko ba layọ, iṣẹ wa yoo wa di eyi ti nganilara—aláṣetúnṣe ṣaa, ti nsuni, ti o tilẹ ndẹru pa ero imọlara paapaa. Eyi yoo ṣamọna si ọna igbaṣiṣẹ alaileso ati ipo ọka ti o gbòdi. Igbesi-aye yoo di ijakadi ojoojumọ bi awa ṣe ngbiyanju lati koju awọn ohun abeere fun ti o nbeere afiyesi wa. Bi o ti wu ki o ri, bi awa ba le wa ọna lati jẹ alayọ ninu ohun ti awa nṣe, o tubọ ṣeeṣẹ ki a niriiri ọna igbesi-aye alaṣeyọri ti o si nmu èrè wa.
Wà Deedee
Bi awa ba nilati jẹ alayọ koda bi a tilẹ ni ọpọlọpọ lati ṣe, awa nilati wa deedee. Ki ni wiwa deedee jẹ? O jẹ “iduro deedee ti ero ori ati imọlara.” Ẹnikan ti o wa deedee yoo sakun lati wa letoleto ninu awọn igbokegbodo rẹ̀. Oun wéwèé ṣaaju, o si nyẹra fun isunsiwaju, oun si wa niwọntunwọnsi ninu ihuwasi. Oun nfi ikora ẹni nijaanu han ninu jijẹ, mimu, akoko igbafẹ, awọn iṣẹ afipawọ, ati ere inaju. Dajudaju, oun ‘nfi ikora ẹni nijanu han ninu ohun gbogbo’!—1 Kọrinti 9:24-27, NW; fiwe Titu 2:2.
Adura ko ipa pataki ninu didi iwọntunwọnsi Kristian mu titi lọ. Iranṣẹ Jehofa le gbadura fun ẹmi mimọ Ọlọrun ati fun iranlọwọ Baba rẹ ọrun ninu mimu awọn eso rẹ dagba, ti o ni ikora ẹni nijaanu ninu. (Luuku 11:13; Galatia 5:22, 23) Ni pataki julọ ni Kristian kan nilati wo ọdọ Ọlọrun ninu adura nigba ti awọn adanwo ba dótìí ti o si nhalẹ lati ṣediwọ fun iwa deedee rẹ. “Fi ọna rẹ le Oluwa [“Jehofa,” NW] lọwọ; gbẹkẹle e pẹlu; oun o si mu un ṣẹ,” ni onisaamu naa Dafidi wi. (Saamu 37:5) Ni awọn igba miiran awa le fẹ lati gbadura gẹgẹ bi Dafidi ti ṣe nigba ti o bẹbẹ pe: “Óò Ọlọrun, gbe igbesẹ ni kiakia nitori mi. Iwọ jẹ iranwọ mi ati Olupese asala fun mi. Óò Jehofa, maṣe pẹ ju.” (Saamu 70:5, NW) Maṣe gbagbe lae pe nipasẹ adura o ṣeeṣe lati pa ìwàdéédé mọ ati lati gbadun ‘alaafia Ọlọrun ti o ju imọran gbogbo lọ, ti yoo ṣọ ọkan ati ero wa.’—Filipi 4:6, 7.
Nitori pe oun gbẹkẹle Jehofa ti o si ngbadun alaafia Ọlọrun, Kristian kan ti o wà deedee yoo jipepe ninu ero inu. (Titu 2:11, 12) Eyi wa lati inu nini oye awọn ilana Bibeli ni kikun ati nipa fifi wọn silo ninu igbesi-aye rẹ. Iru ẹni yii kii ṣe alagabagebe, tabi ẹni ti nyara kankan ninu idajọ. Jijẹ onisuuru mu un fasẹhin fun jijẹ aṣetinu ẹni tabi olori kunkun. Oun di oju iwoye oniwọntunwọnsi mu nipa ara rẹ ati itootun rẹ, eyi si mu ki o ṣeeṣe fun un lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn miiran. (Mika 6:8) Lọna ti o fani lọkan mọra, iwa ẹda naa ti o ran ẹnikan lọwọ lati jẹ ẹni ti o wadeedee tun wà lara awọn animọ ti a beere lọwọ awọn wọnni ti a yan sipo lati ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alaboojuto ninu ijọ Kristian.—1 Timoti 3:2, 3.
Awa le fikun ayọ wa lọna titobi nipa sisakun lati tubọ jẹ ẹni ti o wadeedee ninu awọn igbokegbodo wa ojoojumọ. Nipa ṣiṣaṣefihan awọn animọ ti o sopọ mọ iwadeedee rere, awa le ṣe awọn nǹkan ti o pọndandan laisi irẹwẹsi lilekoko nipa ti ara tabi ti ero imọlara. Ọna aṣa igbesi-aye wa yoo fi ẹri ifẹsẹ mulẹ ti o pọ̀ sii han, awa yoo si ṣaṣeyọri pupọ sii. Awọn miiran yoo ri alekun igbadun sii ninu ikẹgbẹpọ pẹlu wa, awa yoo si niriiri itẹlọrun ati ayọ ti o tubọ pọ sii. Ṣugbọn ki ni awọn ọna ti o gbeṣẹ lati pa ìwàdéédé mọ?
Awọn Ọna gbigbeṣẹ lati Pa Ìwàdéédé Mọ
Ki o ba le ṣeeṣe lati pa ìwàdéédé mọ, awa nilati gbiyanju lati pa akoko mọ ki a si wa letoleto ninu bibojuto awọn nǹkan ti ara ẹni. Awa nilati wéwèé ṣaaju, ni bibojuto awọn ọran letoleto, ni ṣisẹntẹle. Awọn wọnni ti wọn ṣalaini iṣeto daradara ti wọn si nfẹ lati maa sún awọn nǹkan siwaju nmu ki igbesi-aye wọn lọjupọ pẹlu awọn pákáǹleke ati aniyan ti nga roke sii. Aṣeyọrisi rere ni apa igbesi-aye yii yoo ran wa lọwọ lati nimọlara pe awa ni o nṣakoso dipo ti a o maa fi nimọlara pe awa jẹ ojiya ipalara alainiranlọwọ lọwọ ipo ti o yi wa ká.
Awa ko gbọdọ gbiyanju lati ṣe ohun gbogbo funraawa. Awọn wọnni ti wọn ko fẹ lati tẹwọgba iranlọwọ lati ọdọ awọn miiran lọpọ igba maa nsan iye owo wiwuwo ni ọna itanlokun ati ijakulẹ. Oriṣiriṣi awọn iṣẹ ni wọn wa ti awọn ẹlomiran le bojuto. Nitori naa, o lọgbọn ninu lati lo anfaani itootun awọn wọnni ti wọn fẹ lati pese iranlọwọ. Yatọ si mimu ẹru awa funraawa fuyẹ, eyi le jẹ afunni niṣiiri fun awọn wọnni ti wọn ndaniyan lati fà sunmọ wa pẹkipẹki.
O jẹ iwa alailọgbọn lati fi ara wa we awọn wọnni ti wọn le lagbara lati ṣe pupọ si. Gbigbiyanju lati dabi awọn wọnni ti a mọ gbangba pe wọn le ṣe ọpọlọpọ sii ju wa lọ maa nkorẹwẹsi bani, ti o nmu ki a nimọlara jijẹ ẹni ẹhin ati alaitootun. Iru ironu wọnyi maa npanirun ti o si le jin ipinnu ati igbẹkẹle ara ẹni lẹsẹ. Pọọlu kọwe pe, “Ki olukuluku ki o yẹ iṣẹ ara rẹ wo, nigba naa ni yoo si ni ohun iṣogo nipa ti ara rẹ nikan, kii yoo si ṣe nipa ti ọmọnikeji rẹ.” (Galatia 6:4) Ranti pe oṣiṣẹ ti o ṣe e gbiyele julọ ni eyi ti ngba itọni, ti o jẹ adurosinṣin ati olootọ, ti o si nṣe awọn iṣẹ ti o jojulowo. Bi awa ba dabi eyi, iṣẹ wa ni a o mọriri ti a o si maa beere fun.—Owe 22:29.
Awa nilati bojuto ilera wa daradara. O jẹ ọkan ninu awọn ohun ini wa ṣiṣeyebiye julọ, nitori laisi i kiki iwọnba kekere ni yoo le ṣeeṣe fun wa lati ṣe. Nipa bayi, awa nilati gbiyanju lati pa itolẹsẹẹsẹ ounjẹ afunni nilera mọ nipa jijẹ awọn ounjẹ eleroja afunni lokun. O yẹ ki awa ni iwọn isimi ti a nilo, ni lilọ si ori ibusun ni wakati ti o bọgbọn mu ni alẹ. Nigba ti aarẹ lilekoko ba mu wa tabi ti a ba nimọlara pe aisan nbọwa, awa ko nilati maa baa lọ ni fifipa mu ara wa sisẹ; awa le san iye owo wiwuwo kan.
O ṣe pataki lati ṣọra lodisi mimu ẹmi irahun dagba. Bi awa ba fun ironu odi laaye falala lati ṣakoso, awa le ri ohun aleebu o fẹrẹẹ jẹ ninu ohunkohun tabi ẹnikẹni. Eyi jẹ ọna ti o daju kan ti a le gba ja ara wa ati awọn ẹlomiiran lole idunnu. Kaka ti a o maa fi ṣofofo tabi rahun nipa ohun ti a nimọlara pe o ṣaitọ, a nilati sọ fun awọn ti wọn wa ni ipo ẹru iṣẹ lati bojuto ọran naa ki a si fi silẹ fun wọn lati ṣatunṣe awọn nǹkan. (Fiwe 1 Kọrinti 1:10-12.) Awa jẹ ọlọgbọn lati ni ẹmi ifojusọna fun rere, ki a maa figba gbogbo lepa ki a si maa reti lati ri rere ninu awọn ẹlomiiran ati ninu awọn iṣẹlẹ ti o ngbe igbesi-aye wa ro.—Fiwe Juuda 3, 4, 16.
Ni wiwewee awọn igbokegbodo wa, awa nilati ranti pe itẹsiwaju ti a fi isapa ṣe le mu ni ṣe aṣeyọri titayọlọla, ṣugbọn ti o ṣoro lati pa mọ fun akoko gigun. Kii ṣe kiki pe fifi igba gbogbo ṣiṣẹ kọja aala yoo ṣamọna si imuniṣaarẹ patapata ṣugbọn o le mu irẹwẹsi wá pẹlu ti o le jìn ipinnu wa lati maa tẹsiwaju lẹ́sẹ̀. Nipa bayii, ẹ jẹ ki a gbe ọna iṣisẹrin kan kalẹ ti awa le pa mọ. Fun apẹẹrẹ, o ṣe pataki lati gbe itolẹsẹẹsẹ igbokegbodo ti o ṣe fisilo kalẹ fun lilọwọ ninu iṣẹ iwaasu ile de ile ati awọn apa miiran ninu iṣẹ ojiṣẹ Kristian deedee. A nilati gba akoko laaye fun isinmi ati ere itura ti ngbeniro. Awa yoo si ri pe o ṣanfaani lati sọrọ pẹlu awọn eniyan ti o dagba ti wọn ti ni iriri fun ọpọlọpọ ẹwadun, nitori wọn ti le kẹkọọ bi a ṣe le ṣe awọn nǹkan ti o pọndandan laisi títán ara ẹni lokun patapata nipa ti ara tabi ti imọlara.
Lo Idajọ Rere
O bojumu lati nimọlara iṣẹ aigbọdọ maṣe ati idaniyan lati mu awọn ẹru iṣẹ wa gbogbo ṣẹ, ti o ni ti aarin ijọ awọn eniyan Jehofa ninu. Ọlọrun ni inudidun si awọn oṣiṣẹ alaapọn ti wọn si ṣee gbẹkẹle. (Fiwe Matiu 25:21; Titu 2:11-14.) Ṣugbọn Iwe mimọ rọni pe: “Pa ọgbọn ti o yẹ, ati imoye mọ.” (Owe 3:21) Ifisilo awọn ọgbọn Bibeli naa yoo ṣanfaani fun wa, awa si nilati lo ọgbọn ori ati idajọ rere, ni fifi iṣọra ṣe awọn iwewee wa ki a si pa ara wa mọ saaarin aala agbara tí a ní.
Iṣileti naa lati ni ọpọlọpọ lati ṣe ninu iṣẹ Oluwa ni a nilati mu wa deedee pẹlu ikilọ ti a damọran ninu Oniwaasu 9:4. Nibẹ a ka pe: “Aaye aja san ju oku kinniun.” Bẹẹni, aja ti o walaaye kan, bi o tilẹ jẹ pe awọn diẹ tẹmbẹlu rẹ, o san lọpọlọpọ ju oku kinniun, ẹranko kan ti ọpọlọpọ ka si ọlọla. Bi awa ba nṣamulo ìwà ní deedee ti a si bojuto ilera wa lọna ti o bojumu, awa yoo walaaye ti a o si maa baa lọ lati maa ṣe awọn nǹkan. Awọn oku ko tun ni ipin kan siwaju sii mọ ninu igbokegbodo eyikeyii. Idajọ rere le ran wa lọwọ lati ṣaṣeyọri awọn nǹkan ti o pọndandan laiṣe pe a padanu ayọ wa.
Nitori naa, nini pupọ lati ṣe ko tumọsi pe awa ko le jẹ alayọ nigba naa. Awọn eniyan ti ọwọ wọn ndi julọ le wa lara awọn wọnni ti wọn layọ julọ ti wọn ba jẹ́ ọlọgbọn ti wọn pa oju iwoye ti o dara mọ, ti wọn nlo idajọ rere ki o ba le ṣeeṣe lati pa iwadeedee daradara mọ. Awa le niriiri ayọ ti o tobijulọ ti o ṣeeṣe bi awa ba fi ọgbọn han, ti a ṣe awọn iṣẹ rere, ti a si gbe ireti wa ka Jehofa Ọlọrun.—1 Timoti 6:17-19.