Ìwọ́ Ha Jẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà Tí Ó Wà Déédéé Bí?
OJÚ bàbá náà kún fún ayọ̀ bí ó ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣísẹ̀ rìn fún ìgbà àkọ́kọ́. Bí ó ti ṣubú lójijì, bàbá náà fún un níṣìírí láti gbìyànjú lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó mọ̀ pé kì yóò pẹ́ tí yóò fi lè rìn dáadáa, tí yóò sì ní okun.
Ní ọ̀nà jíjọra, òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà tuntun kan lè nílò àkókò àti ìṣírí kí ó tó jèrè ìwàdéédéé tí ó nílò láti kẹ́sẹ járí gẹ́gẹ́ bí alákòókò kíkún olùpòkìkí Ìjọba. Ọ̀pọ̀ aṣáájú ọ̀nà ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ sìn tayọ̀tayọ̀ fún àwọn ẹ̀wádún. Àwọn mélòó kan kò wà déédéé nítorí àyíká ipò wọn tí ó yí padà lójijì. Àwọn kan tilẹ̀ pàdánù ayọ̀ wọn. Ní orílẹ̀-èdè kan, ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún nínú àwọn tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà dáwọ́ dúró láàárín ọdún méjì àkọ́kọ́ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún wọn. Kí ni ó lè mú aṣáájú ọ̀nà kán kúrò nínú iṣẹ́ ìsìn aláyọ̀ jù lọ yìí? Ohunkóhun ha wà tí a lè ṣe láti yẹra fún àwọn ohun ìdènà wọ̀nyí bí?
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àìlera, àìní ní ti ìṣúnná owó, àti ẹrù ìdílé lè mú kí àwọn kan fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún sílẹ̀, ohun ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn mìíràn ti jẹ́ ìkùnà láti pa ìwàdéédéé dáradára mọ́ láàárín onírúurú ojúṣe Kristian. Ìwàdéédéé túmọ̀ sí “ipò kan nínú èyí tí kò sí apá kan, ipa kan, kókó abájọ kan, tàbí ipá ìdarí kan tí ó tẹ̀wọ̀n ju ìkejì tàbí tí kò ṣe rẹ́gí pẹ̀lú àwọn yòókù.”
Jesu Kristi fi han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n ṣe ní láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Ó tún ṣàkàwé bí a ṣe ń pa ìwàdéédéé mọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Jesu fi hàn pé àwọn aṣáájú ìsìn Júù kò wà déédéé, ní sísọ fún wọn pé: “Ẹ ń fúnni ní ìdámẹ́wàá efinrin ati ewéko dílì ati ewéko kumini, ṣugbọn ẹ̀yin ṣàìka awọn ọ̀ràn wíwúwo jùlọ ninu Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo ati àánú ati ìṣòtítọ́. Awọn ohun wọnyi pọndandan ní ṣíṣe, síbẹ̀ awọn ohun yòókù ni kí ẹ máṣe ṣàìkà sí.”—Matteu 23:23.
Ìlànà yìí wúlò bákan náà lónìí, pàápàá fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Bí a ti sún wọn pẹ̀lú ìtara ọkàn àti ète ìsúnniṣe rere, àwọn kan ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà láìmúra ní kíkún fún un, tàbí láìronú lórí gbogbo ohun tí ó ní nínú. (Luku 14:27, 28) Àwọn mìíràn ti fi ara wọn fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá débi tí wọ́n fi gbójú fo àwọn apá ṣíṣe pàtàkì yòókù nínú ìsìn Kristian. Báwo ní ọwọ́ wọn ṣe lè tẹ ìwàdéédéé, kí wọ́n sì máa bá a nìṣó?
Máa Bá A Nìṣó Ní Jíjẹ́ Alágbára Nípa Tẹ̀mí!
Jesu kò kóyán ipò rẹ̀ nípa tẹ̀mí kéré rí. Bí àwọn èrò tí wọ́n wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì wá gba ìwòsàn tilẹ̀ ń gba púpọ̀ nínú àkókò rẹ̀, ó wá àkókò fún àdúrà onírònú jinlẹ̀. (Marku 1:35; Luku 6:12) Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà tí ó wà déédéé lónìí pẹ̀lú ń béèrè pé kí ẹnì kan lo gbogbo ìpèsè tí a ṣe ní kíkún láti lè máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí. Paulu sọ pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, ǹjẹ́ iwọ, ẹni tí ń kọ́ ẹlòmíràn, kò kọ́ ara rẹ?” (Romu 2:21) Dájúdájú, yóò jẹ́ àṣìṣe láti fi gbogbo àkókò wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, kí a sì fojú tín-ínrín wíwá àkókò tí ó tó fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti àdúrà déédéé.
Kumiko ti jẹ́ aṣáájú ọ̀nà fún ogún ọdún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní ọmọ mẹ́ta àti ọkọ aláìgbàgbọ́, ó ti mọ̀ nípasẹ̀ ìrírí pé àkókò tí ó dára jù lọ fún un láti ka Bibeli, kí ó sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ jẹ́ ṣáájú kí ó tó lọ sùn. Bí ó ti ń kẹ́kọ̀ọ́, ní pàtàkì, ó máa ń kíyè sí àwọn kókó tí ó lè lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ ojoojúmọ́ rẹ̀ lè jẹ́ ojúlówó, kí ó sì fani mọ́ra. Àwọn aṣáájú ọ̀nà míràn tí wọ́n ti ṣàṣeyọrí máa ń tètè jí ṣáájú àwọn yòókù nínú ìdílé láti gbádùn ìsọdọ̀tun nípa tẹ̀mí ní àwọn wákàtí òwúrọ̀ tí ó pa rọ́rọ́. O lè ya àwọn àkókò yíyẹ mìíràn sọ́tọ̀ láti múra fún àwọn ìpàdé, kí o sì dojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn ìtẹ̀jáde Kristian tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. Bí o bá fẹ́ láti pa ayọ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà mọ́, ìkẹ́kọ̀ọ́ ara ẹni kì í ṣe ohun kan tí a lè kánjú ṣe tàbí pa tì.
Mímú Kí Ẹrù Ìdílé Wà Déédéé
Àwọn òbí tí ń ṣe aṣáájú ọ̀nà tún ní láti fi sọ́kàn pé ohun tí ó jẹ́ “ìfẹ́-inú Jehofa” jù lọ fún wọn kan bíbójú tó àìní ìdílé wọn nípa ti ara, ti èrò ìmọ̀lára, àti nípa tẹ̀mí. (Efesu 5:17; 6:1-4; 1 Timoteu 5:8) Nígbà míràn pàápàá, alábàáṣègbéyàwó tí ó gbà gbọ́ àti àwọn mẹ́ḿbà ìdílé lè bẹ̀rù pé wọn kì yóò rí ìtùnú àti ìtìlẹyìn gbà láti ọ̀dọ̀ ìyàwó àti ìyá náà mọ́, bí ó bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú ọ̀nà. Irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ máa ń yọrí sí ìdáhùnpadà tí ó lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti di aṣáájú ọ̀nà. Bí ó ti wù kí ó rí, bí ìwéwèé dáradára àti ìrònújinlẹ̀ ṣáájú bá wa, ìwàdéédéé lè ṣeé ṣe.
Ọ̀pọ̀ aṣáájú ọ̀nà ń sakun láti ṣe gbogbo iṣẹ́ ìwàásù wọn nígbà tí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé kò bá sí nílé. Kumiko, tí a mẹ́nu kan ní ìṣáájú, máa ń wà pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń jẹ oúnjẹ òwúrọ̀, ó máa ń dágbére fún ọkọ àti àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń jáde lọ ní òwúrọ̀, ó sì ti máa ń padà sílé kí wọ́n tó dé. Ó máa ń lo ọjọ́ Monday láti se ọ̀pọ̀ oúnjẹ sílẹ̀ ṣáájú, kí ó baà lè sinmi, kí ó sì jẹun pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ dípò kíkún fún iṣẹ́ pẹrẹwu nínú ilé ìdáná. Ṣíṣe iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí ó ju ẹyọ kan lọ lẹ́ẹ̀kan, irú bíi iṣẹ́ ilé mìíràn nígbà tí ó bá ń se oúnjẹ, tún ṣèrànwọ́ pẹ̀lú. Ní ọ̀nà yẹn, Kumiko tilẹ̀ ń rí àyè láti ké sí ọ̀rẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ilé wọn, kí ó sì ní àkànṣe ìjíròrò pẹ̀lú wọn.
Bí àwọn ọmọ ti ń dàgbà dé àwọn ọdún ọ̀dọ́langba wọn, wọ́n nílò àfikún àfiyèsí láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn látìgbàdégbà láti lè kojú àwọn èrò ìmọ̀lára tuntun, ìfẹ́ ọkàn, iyè méjì, àti ìbẹ̀rù tí ń bò wọ́n mọ́lẹ̀. Èyí ń béèrè fún ìwàlójúfò àti ìyípadà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ òbí kan tí ó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Gbé ọ̀ràn Hisako, ìyá ọlọ́mọ mẹ́ta tí ń ṣe aṣáájú ọ̀nà, yẹ̀ wò. Kí ni ó ṣe nígbà tí ọmọbìnrin rẹ̀ àgbà bẹ̀rẹ̀ sí í fi àìláyọ̀ àti àìnítara hàn fún àwọn ìpàdé Kristian àti iṣẹ́ ìsìn pápá, nítorí agbára ìdarí àwọn ọ̀rẹ́ ayé ní ilé ẹ̀kọ́? Ohun tí ọmọbìnrin rẹ̀ nílò ní ti gidi ni láti sọ òtítọ́ di tirẹ̀, kí ó sì mọ̀ dájú ṣáká pé yíyà sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé ní ọ̀nà tí ó dára jù lọ.—Jakọbu 4:4.
Hisako sọ pé: “Mo pinnu láti kọ́ àwọn ẹkọ́ ṣíṣe kókó nínú ìwé Walaaye Titilae pẹ̀lú rẹ̀, lẹ́ẹ̀kan sí i lójoojúmọ́. Lákọ̀ọ́kọ́, a lè kẹ́kọ̀ọ́ fún kìkì ìwọ̀nba ìṣẹ́jú díẹ̀, tí ọmọbìnrin mi yóò sì máa ṣàròyé nípa inú rírun àti ẹ̀fọ́rí líle koko nígbà tí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ bá ti to. Ṣùgbọ́n mo ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà déédéé. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, ìhùwàsí rẹ̀ yí padà gidigidi, ó sì ṣamọ̀nà sí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi rẹ̀ láàárín àkókò kúkúrú.” Nísinsìnyí, Hisako àti ọmọbìnrin rẹ̀ ń gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún pẹ̀lú.
Àwọn bàbá tí ń ṣe aṣáájú ọ̀nà pẹ̀lú ní láti ṣọ́ra kí wọ́n má baà fi ara wọn fún bíbójú tó àwọn olùfìfẹ́hàn nínú pápá, àti àwọn ojúṣe wọn nínú ìjọ débi tí wọn yóò fi kùnà láti fún àwọn ọmọ wọn tí ń dàgbà ní ìtìlẹ́yìn lílágbára ní ti èrò ìmọ̀lára àti ìdarísọ́nà tí wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí. Èyí kì í ṣe ohun kan tí ọkùnrin kan ní láti taari sí aya rẹ̀. Kristian alàgbà kan tí ó kún fún iṣẹ́ pẹrẹwu, tí ó ti jẹ́ aṣáájú ọ̀nà fún àkókò pípẹ́, tí ó sì ń bójú tó òwò kékeré kan pẹ̀lú máa ń wá àkókò láti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rin lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. (Efesu 6:4) Ní àfikún, ó máa ń múra fún àwọn ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú ìdílé rẹ̀. Àwọn aṣáájú ọ̀nà wíwà déédéé kì í ṣàìnáání ìdílé wọn nípa ti ara tàbí nípa tẹ̀mí.
Ìwàdéédéé Ní Ti Ìṣúnná
Ojú ìwòye títọ́ nípa àwọn àìní ojoojúmọ́ jẹ́ agbègbè míràn níbi tí àwọn aṣáájú ọ̀nà ti ní láti sakun láti pa ìwàdéédéé mọ́. Níhìn-in lẹ́ẹ̀kan sí i, a lè kọ́ ohun púpọ̀ láti inú àpẹẹrẹ àti ìmọ̀ràn àtàtà Jesu. Ó kìlọ̀ lòdì sí ṣíṣàníyàn jù nípa àwọn nǹkan ti ara. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níṣìírí láti fi Ìjọba náà ṣe àkọ́kọ́, ní ṣíṣèlérí pé Ọlọrun yóò bójú tó wọn, bí ó ti ń ṣe fún àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ yòókù. (Matteu 6:25-34) Nípa títẹ̀ lé ìmọ̀ràn rere yìí, ó ti ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ọ̀nà láti wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fún ọ̀pọ̀ ọdún, Jehofa sì ti bù kún ìsapá wọn láti rí ‘búrẹ́dì fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.’—Matteu 6:11.
Aposteli Paulu gba àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nímọ̀ràn láti ‘jẹ́ kí ìfòyebánilò wọn di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.’ (Filippi 4:5) Dájúdájú, ìfòyebánilò yóò béèrè pé kí a bójú tó ìlera wa lọ́nà yíyẹ. Àwọn aṣáájú ọ̀nà wíwà déédéé ń sa gbogbo ipá wọn láti fi ìfòyebánilò hàn nínú ọ̀nà ìgbésí ayé wọn àti nínú ẹ̀mí ìrònú wọn nípa àwọn nǹkan ìní ti ara, ní mímọ̀ pé àwọn ẹlòmíràn ń wo ìwà wọn.—Fi wé 1 Korinti 4:9.
Àwọn èwe tí wọ́n tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà gbọ́dọ̀ fà sẹ́yìn nínú yíyọ́fà ìwà ọ̀làwọ́ àwọn òbí wọn. Bí wọ́n bá ń gbé ilé àwọn òbí wọn, yóò jẹ́ fífi ìwàdéédéé rere àti ìmọrírì hàn láti lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ilé, àti láti ní àbọ̀ṣẹ́ kan tí yóò jẹ́ kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ nínú gbígbọ́ bùkátà ilé.—2 Tessalonika 3:10.
Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Wíwà Déédéé, Ojúlówó Ìbùkún Kan
O lè jẹ́ aṣáájú ọ̀nà tí ń ṣiṣẹ́ taratara láti ní ìwàdéédéé yíyẹ. Ní ìgbọkànlé pé o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọmọ kékeré ṣe nílò àkókò láti kọ́ bí òún ṣe lè dúró déédéé, kí ó sì rìn, ọ̀pọ̀ aṣáájú ọ̀nà adàgbàdénú sọ pé, ó gbà wọ́n lákòókò láti ní ìwàdéédéé nínú bíbójú tó gbogbo ojúṣe wọn.
Ṣíṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́, bíbójú tó àwọn mẹ́ḿbà ìdílé, àti pípèsè àwọn àìní wọn ní ti ara wà lára àwọn agbègbè tí àwọn aṣáájú ọ̀nà ti ń là kàkà láti wà déédéé. Ìròyìn fi hàn pé ọ̀pọ̀ aṣáájú ọ̀nà ń ṣàṣeparí ẹrù iṣẹ́ wọn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Ní tòótọ́, wọ́n jẹ́ ìbùkún fún mùtúmùwà, wọ́n sì jẹ́ ìyìn fún Jehofa àti ètò àjọ rẹ̀.