ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 10/15 ojú ìwé 21-24
  • ‘Ẹ Jẹ Ki Awa Pẹlu Mú Gbogbo Ẹrù Wiwuwo Kuro’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ẹ Jẹ Ki Awa Pẹlu Mú Gbogbo Ẹrù Wiwuwo Kuro’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wíwá Okunfa Naa
  • Oju Iwoye Wiwadeedee Nipa Awọn Nǹkan Ti Ara
  • Ilọgbọn-ninu Ṣekoko
  • Jẹ́ Amẹ̀tọ́mọ̀wà Ninu Biba Ọlọrun Rin
  • Jehofa Ńràn Wá Lọwọ Lati Gbé Ẹrù Naa
  • “Àjàgà Mi Jẹ́ Ti Inúrere Ẹrù Mi Sì Fúyẹ́”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ó Ń Rẹ̀ Wá Àmọ́ A Kì í Ṣàárẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • “Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi, . . . Màá sì Tù Yín Lára”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Oògùn Ajẹ́bíidán Fún Másùnmáwo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 10/15 ojú ìwé 21-24

‘Ẹ Jẹ Ki Awa Pẹlu Mú Gbogbo Ẹrù Wiwuwo Kuro’

“Inu mi bàjẹ́ gan an mo sì rẹwẹsi,” ni Maria kedaaro. Ni titọka si awọn ẹru iṣẹ Kristẹni, Kristẹni obinrin yii fi kun un pe: “Mo nri ti awọn ọrẹ nniriiri ìtánlókun. Emi pẹlu nimọlara àárẹ̀ ati ikimọlẹ naa. Ẹ jọwọ ẹ ran mi lọwọ lati loye idi rẹ̀.”

IWỌ pẹlu ha nimọlara pe o wà labẹ ikimọlẹ, ti o rẹ̀ ọ́ jù lati bojuto awọn ẹru iṣẹ ti iṣakoso Ọlọrun rẹ lọna ti o kun oju iwọn bi? Nigba miiran o ha jọ bi ẹni pe iṣẹ-ojiṣẹ Kristẹni jẹ́ ẹrù wiwuwo kan, ẹru inira kan ti o ṣoro lati farada? Ọpọlọpọ awọn Kristẹni oluṣotitọ nla awọn sáà irẹwẹsi kọja, nitori a yí wa ká nigba gbogbo nipasẹ awọn ipá alaigbeniro ti o le dín ayọ wa kù. Jijẹ ojulowo Kristẹni kan lonii jẹ ipenija kan nitootọ. Nipa bayii, nigba miiran awọn kan le nimọlara pe iṣẹ-ojiṣẹ Kristẹni jẹ́ ẹrù wiwuwo kan.

Wíwá Okunfa Naa

Iwe mimọ mu ki ó ṣe kedere pe Jehofa kò tii gbe awọn ibeere alaibọgbọnmu kà wá lori. Apọsiteli Johanu wi pe ‘awọn ofin Ọlọrun ko nira.’ (1 Johanu 5:3) Jesu sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ bakan naa pe: “Ẹ gba ajaga mi si ọrùn yin, ki ẹ si maa kọ́ ẹkọ lọdọ mi; nitori oninututu ati onirẹlẹ ọkan ni emi; ẹyin yoo sì ri isinmi fun ọkan yin. Nitori ajaga mi rọrun, ẹrù mi si fuyẹ.” (Matiu 11:29, 30) Ni kedere kii ṣe ifẹ inu Jehofa pe ki a nimọlara pe a dẹ́rù pa wá tabi wọ̀ wá lọrun ninu iṣẹ-isin wa si i.

Bawo, nigba naa, ni Kristẹni oluṣotitọ kan ṣe le wo awọn ẹrù-iṣẹ́ Kristẹni rẹ̀ bi ẹrù inira wiwuwo kan? Boya, awọn koko melookan wepọ mọ ọn. Ṣakiyesi awọn ọrọ apọsiteli Pọọlu wọnyi: “Ẹ jẹ ki awa pẹlu mu gbogbo ẹru wiwuwo . . . kuro, ẹ si jẹ ki a fi ifarada sa ere ije ti a gbé ka iwaju wa.” (Heberu 12:1, NW) Awọn ọrọ Pọọlu fihan pe Kristẹni kan nigba miiran le gbe awọn ẹru ti ko pọndandan kari araarẹ. Eyi ko fi dandan mu awọn ẹṣẹ wiwuwo lọwọ. Ṣugbọn Kristẹni kan le ṣe awọn aṣiṣe ninu idajọ ti o mu igbesi-aye rẹ̀ lọ́júpọ̀ lọna tí ó lékenkà, ti o mu ki o ṣoro fun un gan an lati sa ere ije ti a ti gbé ka iwaju wa.

Oju Iwoye Wiwadeedee Nipa Awọn Nǹkan Ti Ara

Fun apẹẹrẹ, mu ọran iṣẹ ounjẹ oojọ. Ni ọpọlọpọ ilẹ, awọn ipo ọrọ̀-ajé le fi Kristẹni kan silẹ pẹlu yíyàn tí kò pọ̀ bikoṣe lati ṣiṣẹ fun wakati gigun. Bi o ti wu ki o ri, niye igba, awọn eniyan ngba iṣẹ kiki lati gba ipo iwaju tabi kó awọn ohun eelo faaji jọ. Nipa títún awọn aini wọn gan-an gbeyẹwo, awọn Kristẹni kan ti ri i pe o bọgbọnmu lati ṣe awọn atunṣebọsipo ninu ọran iṣẹ wọn. Eyi ri bẹẹ pẹlu Debbie ati ọkọ rẹ̀, tí awọn mejeeji jẹ Ẹlẹ́rìí Jehofa. O wi pe: “Ipo ọ̀ràn inawo wa ti yipada, ko sì sí idi gidi kan mọ fun mi lati maa baa lọ ni ṣiṣiṣẹ alakooko kikun. Ṣugbọn o ṣoro lati dawọ rẹ̀ duro.” Laipẹ o bẹrẹ sii nimọlara ikimọlẹ nini ohun pupọ jù lati ṣe. O ṣalaye pe: “Satide nikan ni ọjọ ti o ṣí silẹ fun mi lati ṣe iṣẹ ile. Niye igba emi kii wulẹ nimọlara bi ẹni pe ki njade lọ sinu iṣẹ-isin pápá. Mo nimọlara ti ko dara nipa eyi, ẹ̀rí ọkan mi si nyọ mi lẹnu, sibẹ mo nifẹẹ iṣẹ mi! Nikẹhin, mo nilati dojukọ otitọ gidi. Ojutuu kanṣoṣo ni o wà. Mo fi iṣẹ naa silẹ.” Ki a gba pe, iru atunṣebọsipo nla kan bẹẹ lè má ṣeeṣe fun awọn kan. Bi o ti wu ki o ri, ayẹwo kínníkínní ti itolẹsẹẹsẹ iṣẹ rẹ le ṣipaya idi fun awọn iyipada kan pato.

Awọn ọna miiran lè wà ti a lè gbà já araawa gbà kuro lọwọ awọn ẹrù inira ti ko pọndandan. Ki ni nipa didin irin-ajo igbafẹ lemọlemọ, awọn igbokegbodo ere idaraya, tabi awọn faaji miiran kù—ti o ní ninu akoko ti a lò ni wiwo tẹlifiṣọn? Ani lẹhin ti ọwọ ba ti tẹ ìwàdéédéé ti a fẹ́ ninu awọn agbegbe wọnyi paapaa, ó lè beere fun atunṣebọsipo lóòrèkóòrè lati pa iru ìwàdéédéé bẹẹ mọ́.

Ilọgbọn-ninu Ṣekoko

Ilọgbọn-ninu ninu iru awọn ọran bẹẹ yoo ran wa lọwọ lati yipada si awọn ipo titun bi wọn ti njẹyọ. Nipa bayii, a le pa oju iwoye onifojusọna fun rere mọ ninu iṣẹ-ojiṣẹ wa.—Efesu 5:15-17; Filipi 4:5.

Iwọ ha ri araarẹ labẹ ikimọlẹ lati maa ba ìṣísẹ̀rìn ni ìyára kan naa lọ pẹlu ohun ti awọn ẹlomiran nṣe ninu iṣẹ-isin Ọlọrun bi? Eyi pẹlu le fi aniyan ati ijakulẹ kun igbesi-aye rẹ. Nigba ti apẹẹrẹ rere awọn ẹlomiran le fun ọ niṣiiri lati ṣe pupọ sii dajudaju, ilọgbọn-ninu yoo ran ọ lọwọ lati gbe awọn gongo ti o ṣee lébá ni ibamu pẹlu awọn ayika ipo ati agbara tirẹ funraarẹ ka iwaju. Iwe mimọ sọ fun wa pe: “Ki olukuluku ki o yẹ iṣẹ araarẹ wò, nigba naa ni yoo sì ni ohun iṣogo nipa ti araarẹ nikan, ki yoo si ṣe nipa ti ọmọnikeji rẹ̀. Nitori olukuluku ni yoo ru ẹru ti ara rẹ.”—Galatia 6:4, 5.

Awọn aṣa adugbo ati igbagbọ atọwọdọwọ tun le fikun awọn ẹrù inira wa. Ni ọjọ Jesu awọn eniyan ni a dá lágara lati inu igbiyanju lati ṣegbọran si ọpọ awọn ilana isin ati ẹkọ atọwọdọwọ tí awọn eniyan gbe kalẹ. Lonii, awọn eniyan Jehofa ni a ti tú silẹ kuro ninu awọn ẹkọ atọwọdọwọ isin eke. (Fiwe Johanu 8:32.) Sibẹ, ọwọ́ Kristẹni kan lè dí pẹlu awọn aṣa adugbo jù bi o ti yẹ lọ. Fun apẹẹrẹ, nigba miiran awọn iṣẹlẹ iru bii ayẹyẹ igbeyawo ni awọn aṣa ti o pọ rẹpẹtẹ maa nyika. Awọn aṣa wọnyi le má jẹ́ eyi ti kò tọ́, wọn tilẹ le jẹ aṣa atijọ ti o fanimọra ti o sì gbadunmọni paapaa. Bi o ti wu ki o ri, awọn Kristẹni le ma ni akoko tabi agbara niti ọ̀ràn inawo lati ṣe gbogbo iru awọn nǹkan bẹẹ, tí sisakun lati ṣe bẹẹ sì le fikun awọn ẹru inira miiran ti ko pọndandan.

Gbe ohun ti o ṣẹlẹ yẹ̀wò nigba ti Jesu bẹ obinrin kan wò ti orukọ rẹ njẹ Mata. Dipo jijanfaani ni kikun lati inu ọgbọn atọrunwa rẹ̀, “Mata nṣe iyọnu ohun pupọ.” Oun ni ọpọlọpọ awọn kulẹkulẹ wọ̀ lọrun. (Luuku 10:40) Ṣugbọn Jesu fi inurere damọran pe ó le mu awọn iṣeto ounjẹ gbígbọ́ rẹ̀ rọrun ki o baa le janfaani lati inu ẹkọ rẹ̀. (Luuku 10:41, 42) Eyi ṣapejuwe daradara pe idajọ rere ati ilọgbọn-ninu yoo ran ọ lọwọ ninu níní ìwàdéédéé ti o bojumu ninu iṣẹ-ojiṣẹ Kristẹni rẹ.—Jakobu 3:17.

Idajọ rere ni a tun beere nigba ti a ba nyan awọn alabaakẹgbẹ. Owe 27:3 kilọ pe: “Okuta wuwo, yanrin sì wuwo, ṣugbọn ibinu aṣiwere wuwo ju mejeeji lọ.” Lọna ti kò yatọ, awọn olubakẹgbẹ timọtimọ rẹ yoo ni agbara idari ti ó lagbara lori ọna ti o ngba ronu. Kikẹgbẹpọ pẹlu awọn wọnni ti wọn tete nri aleebu ti wọn sì nṣe lameyitọ awọn ẹlomiran ninu ijọ le gbin irugbin irẹwẹsi ati ironu ti kò tọ́ sinu rẹ. (1 Kọrinti 15:33) Bi iwọ ba woye pe eyi jẹ iṣoro kan, awọn iyipada ọlọgbọn diẹ ninu ẹgbẹ ti iwọ nko le mu ẹru rẹ fuyẹ.

Jẹ́ Amẹ̀tọ́mọ̀wà Ninu Biba Ọlọrun Rin

Ni Mika 6:8 (NW), a ri ibeere arùrònúsókè yii: “Ki ni Jehofa nbeere pada lọdọ rẹ bikoṣe . . . lati jẹ amẹ̀tọ́mọ̀wà ninu biba Ọlọrun rẹ rin?” Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ni a tumọ gẹgẹ bi mimọ awọn ààlà ara ẹni. Awọn wọnni ti wọn ko mọ awọn ààlà araawọn le fi ọpọlọpọ ẹrù iṣẹ bo araawọn mọlẹ. Eyi ti ṣẹlẹ si awọn Kristẹni ogboṣaṣa, ani awọn alaboojuto paapaa, ti nyọrisi irẹwẹsi, ijakulẹ, ati ipadanu ayọ. Kenneth, Kristẹni alagba kan, gbà pe: “Mo ri araami ti mo nlọ sinu ikarisọ, mo si wi pe, ‘Emi ko ni jẹ ki eyi ṣẹlẹ si mi.’ Nitori naa mo mu diẹ lara awọn ẹrù iṣẹ mi mọniwọn mo sì pọkanpọ sori ohun ti mo le ṣe.”

Ani Mose wolii onirẹlẹ naa ni iṣoro ninu mimọ awọn ààlà araarẹ. Nitori naa Jẹtiro, àna rẹ̀, nilati ran Mose lọwọ lati ronu ni kedere nipa àpọ̀jù iṣẹ ti o ngbiyanju lati bojuto funraarẹ. “Ki ni eyi ti iwọ nṣe fun awọn eniyan yii?” ni Jẹtiro beere. “Eyi ti iwọ nṣe nì kò dara. Dajudaju iwọ yoo dá araarẹ lagara . . . nitori ti nǹkan yii wuwo fun ọ; iwọ nikan ki yoo le ṣee tikaraarẹ. Iwọ . . . ṣà ninu gbogbo awọn eniyan yii awọn ọkunrin ti o tó, . . . yoo sì ṣe, gbogbo ẹjọ nla ni ki wọn ki o maa mu tọ̀ ọ́ wá, ṣugbọn gbogbo ẹjọ keekeeke ni ki wọn ki o maa dá: yoo si rọrun fun iwọ tikalaraarẹ, wọn o si maa bá ọ ru ẹrù naa.” Lọgan Mose bẹrẹ sii yan diẹ lara awọn iṣẹ rẹ̀ fun awọn ẹlomiran, ni titipa bayii rí itura kuro ninu ẹrù kan ti o ti ndi aláìṣeégbé fun un.—Ẹkisodu 18:13-26.

Ni akoko miiran Mose sọ fun Jehofa pe: “Emi nikan kò le ru gbogbo awọn eniyan yii, nitori ti wọn wuwo ju fun mi.” Lẹẹkan sii, idahun naa ni lati yan aṣoju. Eyi pẹlu le jẹ ojutuu si ipo iṣoro rẹ bi o ba nimọlara pe ọpọlọpọ awọn ẹrù iṣẹ ti bò ọ mọlẹ.—Numeri 11:14-17.

Jehofa Ńràn Wá Lọwọ Lati Gbé Ẹrù Naa

Jesu sọ pe ajaga oun rọrun ẹru oun sì fuyẹ ṣugbọn kii ṣe aláìlọ́rìn. Ajaga ti Jesu kesi wa lati gbà sọ́rùn araawa kii ṣe ajaga olooraye. Ó jẹ ajaga iyasimimọ pipe si Ọlọrun gẹgẹ bi ọmọ-ẹhin Jesu Kristi. Nitori naa, ìwọ̀n ọ̀rìn tabi ikimọlẹ diẹ nba jijẹ ojulowo Kristẹni kan rin. (Matiu 16:24-26; 19:16-29; Luuku 13:24) Bi awọn ipo aye ti nburu sii, awọn ikimọlẹ npọ sii. Bi o ti wu ki o ri, a ni idi lati jẹ olufojusọna fun rere ninu oju iwoye wa nitori pe ikesini Jesu tumọsi pe awọn ẹlomiran le bọ si abẹ ajaga rẹ̀ pẹlu rẹ̀ ati pe oun yoo ran wọn lọwọ.a Nipa bayii, niwọn igba ti a ba ti tẹle idari Kristi, ẹru wa yoo maa ṣee gbé nitori pe oun yoo ran wa lọwọ.

Ọlọrun bikita fun awọn wọnni ti wọn nifẹẹ rẹ̀, oun sì ntọ ọkan-aya ati agbara ero ori gbogbo awọn ti wọn fi taduratadura gbe ẹru inira wọn lọ sọdọ rẹ̀. (Saamu 55:22; Filipi 4:6, 7; 1 Peteru 5:6, 7) “Olubukun ni Oluwa [“Jehofa,” NW], ẹni ti nru ẹru wa lojoojumọ; Ọlọrun naa ni igbala wa,” ni onisaamu naa wi. (Saamu 68:19) Bẹẹni, ni idaniloju pe Ọlọrun yoo bá ọ gbé ẹrù rẹ lojoojumọ bi iwọ ba mu gbogbo ẹru wiwuwo kuro ti o si fi ifarada sa ere ije ti a gbeka iwaju rẹ.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Itumọ akiyesi ẹsẹ iwe ni: “Bọ sabẹ ajaga mi pẹlu mi.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Awọn alagba ọlọgbọn nmuratan lati yan awọn iṣẹ diẹ funni ati lati pin awọn ẹru wọn funni

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́