“Àjàgà Mi Jẹ́ Ti Inúrere Ẹrù Mi Sì Fúyẹ́”
“Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi.”—MATTEU 11:29.
1, 2. (a) Kí ni ohun tí o ti ní ìrírí rẹ̀ nínú ìgbésí-ayé tí ó ti fún ọ ní ìtura? (b) Kí ni ohun tí ẹnì kan gbọ́dọ̀ ṣe láti lè rí ìtura tí Jesu ṣèlérí gbà?
WÍWẸ omi tútù ní òpin ọjọ́ gbígbóná tí ó sì móoru, tàbí oorun alẹ́ àsùngbádùn lẹ́yìn ìrìn-àjò gígùn tí ń kó àárẹ̀ báni—óò, ẹ wo bí ó ti tunilára tó! Bẹ́ẹ̀ ni ó ń rí nígbà tí a bá gbé ẹrù-ìnira kúrò tàbí nígbà tí a bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrélànàkọjá jini. (Owe 25:25; Ìṣe 3:19) Ìtura tí irú àwọn ìrírí amúniláyọ̀ bẹ́ẹ̀ ń mú wá ń sọ okun wa dọ̀tun, ó sì tún fún wa ní agbára láti máa tẹ̀síwájú.
2 Gbogbo àwọn tí wọ́n nímọ̀lára pé ẹrù wọ̀ wọ́n lọ́rùn tí ó sì ti rẹ̀ wọ́n lè wá sọ́dọ̀ Jesu, nítorí ohun tí ó ṣèlérí fún wọn gan-an nìyẹn—ìtura. Bí ó ti wù kí ó rí, láti rí ìtura tí ó fani lọ́kàn mọ́ra náà, ohun kan wà tí ẹnì kan níláti múratán láti ṣe. “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi,” ni Jesu wí, “ẹ̀yin yoo sì rí ìtura fún ọkàn yín.” (Matteu 11:29) Kí ni àjàgà yìí? Báwo ni ó ṣe ń mú ìtura wá?
Àjàgà Inúrere
3. (a) Irú àwọn àjàgà wo ni a lò ní àsìkò Bibeli? (b) Ìtumọ̀ ìṣàpẹẹrẹ wo ni a so pọ̀ mọ́ àjàgà?
3 Nítorí pé wọ́n gbé nínú ẹgbẹ́ àwùjọ tí ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀, Jesu àti àwọn olùgbọ́ rẹ̀ mọ àjàgà dáadáa. Níti gidi, àjàgà jẹ́ ìtì igi gbọọrọ pẹ̀lú ibi àkámọ́ méjì lábẹ́ láti fi bọ ọrùn àwọn ẹranko méjì tí ń fa ẹrù, èyí tí ó sábà máa ń jẹ́ ọ̀dá màlúù, láti so wọ́n pọ̀ láti fa ohun-èèlò ìtulẹ̀, ọmọlanke, tàbí àwọn ẹrù mìíràn. (1 Samueli 6:7) Àwọn àjàgà ti ènìyàn ni a lò pẹ̀lú. Ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ìtì tàbí òpó tí kò wúwo tí a gbé dábùú èjìká pẹ̀lú ẹrù tí a so mọ́ ìpẹ̀kun méjèèjì. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ wọn, ó ṣeé ṣe fún àwọn lébìrà láti gbé àwọn ẹrù tí ó wúwo. (Jeremiah 27:2; 28:10, 13) Láti inú ìsopọ̀ tí ó ní pẹ̀lú ẹrù-ìnira àti òpò, àjàgà ni a sábà máa ń lò lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nínú Bibeli láti dúró fún ìjẹgàba àti ìtẹ̀lóríba.—Deuteronomi 28:48; 1 Awọn Ọba 12:4; Ìṣe 15:10.
4. Kí ni àjàgà tí Jesu nawọ́ rẹ̀ sí àwọn wọnnì tí wọ́n bá wá sọ́dọ̀ rẹ ṣàpẹẹrẹ?
4 Nígbà náà, kí ni àjàgà tí Jesu késí àwọn tí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ìtura láti gbà sọ́rùn wọn? Rántí pé ó sọ pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi.” (Matteu 11:29) Akẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn. Nítorí náà, láti gba àjàgà Jesu wulẹ̀ túmọ̀ sí láti di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. (Filippi 4:3) Bí ó ti wù kí ó rí, èyí ń béèrè ju wíwulẹ̀ mọ àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ níti èrò-orí. Ó béèrè fún ìgbésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú wọn—ní ṣíṣe iṣẹ́ tí ó ṣe àti gbígbé ayé lọ́nà tí òun gbà gbé e. (1 Korinti 11:1; 1 Peteru 2:21) Ó béèrè fún ìjuwọ́sílẹ̀ àfínnúfíndọ̀ṣe fún ọlá-àṣẹ rẹ̀ àti fún àwọn wọnnì tí ó fi ọlá-àṣẹ fún. (Efesu 5:21; Heberu 13:17) Ó túmọ̀ sí dídi Kristian tí ó ṣe ìyàsímímọ́, tí a sì batisí, tí ó sì tẹ́wọ́gba gbogbo àǹfààní àti ẹrù-iṣẹ́ tí ń bá irú ìyàsímímọ́ bẹ́ẹ̀ rìn. Àjàgà tí Jesu nawọ́ rẹ̀ sí gbogbo àwọn tí ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ìtùnú àti ìtura nìyẹn. Ìwọ ha múratán láti gbà á bí?—Johannu 8:31, 32.
5. Èéṣe tí kì yóò fi jẹ́ ìrírí tí ó lekoko láti gba àjàgà Jesu?
5 Gbígba àjàgà láti rí ìtura—ìyẹn kì í ha ṣe ìtakora bí? Níti gàsíkíá kò rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí Jesu ti sọ pé àjàgà òun jẹ́ ti “inúrere.” Ọ̀rọ̀ yìí ní ìtumọ̀ àìlekoko, dídùnmọ́ni, wíwuni. (Matteu 11:30; Luku 5:39; Romu 2:4; 1 Peteru 2:3) Gẹ́gẹ́ bí káfíńtà amọṣẹ́dunjú, ó ṣeé ṣe kí Jesu tí ṣe àwọn ohun-èèlò ìtúlẹ̀ àti àjàgà, òun yóò sì mọ bí a ṣe níláti gbẹ́ àjàgà láti ṣe wẹ́kú kí iṣẹ́ tí ó pọ̀ tó baà lè ṣeé ṣe bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó rọrùn tó. Ó lè fi aṣọ tàbí awọ tẹ́ àjàgà náà nínú. Ọ̀pọ̀ ni a ń ṣe lọ́nà bẹ́ẹ̀ kí wọn má baà dégbò síni lọ́rùn, tàbí yun ọrùn púpọ̀ jù. Ní ọ̀nà kan náà, àjàgà ìṣàpẹẹrẹ tí Jesu nawọ́ rẹ̀ sí wa jẹ́ ti “inúrere.” Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mú àwọn iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe àti ẹrù-iṣẹ́ kan pàtó lọ́wọ́, kì í ṣe ìrírí lílekoko tàbí aninilára ṣùgbọ́n ọ̀kan tí ó tunilára. Àwọn àṣẹ Baba rẹ̀ ọ̀run, Jehofa, kì í ṣe ìnira pẹ̀lú.—Deuteronomi 30:11; 1 Johannu 5:3.
6. Kí ni ohun tí Jesu níláti ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín”?
6 Ohun kan tún wà tí ó mú kí àjàgà Jesu jẹ́ ti “inúrere,” tàbí rọrùn láti gbà. Nígbà tí ó sọ pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín,” ó ti lè ní ọ̀kan nínú ohun méjì lọ́kàn. Bí ó bá jẹ́ pé àjàgà onílọ̀ọ́po méjì ni ó ní lọ́kàn, ìyẹn ni pé, irú èyí tí ó ń so àwọn ẹranko méjì tí ń fa ẹrù pọ̀ láti fa ẹrù, nígbà náà òun ń késí wa láti wá sábẹ́ àjàgà kan náà pẹ̀lú òun. Ẹ wo irú ìbùkún tí ìyẹn yóò jẹ́—láti ní Jesu lẹ́gbẹ̀ẹ́ wa tí ń bá wa fa ẹrù wa! Ní ìdàkejì, bí ó bá jẹ́ pé àjàgà tí a fi ọ̀pá gbọọrọ ṣe tí àwọn lébìrà máa ń lò ni Jesu ní lọ́kàn, nígbà náà ó ń nawọ́ ohun-èèlò nípasẹ̀ èyí tí a fi lè mú kí ẹrù èyíkéyìí tí a gbọ́dọ̀ gbé rọrùn tàbí kí ó ṣeé gbé. Èyí tí ó wù kí ó jẹ́, àjàgà rẹ̀ jẹ́ orísun ìtura gidi kan nítorí tí ó fi dá wa lójú pé: “Nitori onínú tútù ati ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni emi.”
7, 8. Àṣìṣe wo ni àwọn kan máa ń ṣe nígbà tí wọ́n bá nímọ̀lára másùnmáwo?
7 Nígbà náà, kí ni a níláti ṣe bí a bá nímọ̀lára pé ẹrù ìṣòro ìgbésí-ayé tí a ń gbé ń di èyí tí kò ṣeé múmọ́ra mọ́ tí a sì ń fà wá tantan dé ipò jíjá? Àwọn kan lè fi àṣìṣe ronú pé àjàgà jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu Kristi nira gan-an tàbí pé ó béèrè ohun púpọ̀ jù, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àbójútó ìgbésí-ayé ojoojúmọ́ ni ohun tí ń rìn wọ́n mọ́lẹ̀. Àwọn kọ̀ọ̀kan nínú ipò yẹn ṣíwọ́ wíwá sí àwọn ìpàdé Kristian, tàbí wọ́n fàsẹ́yìn nínú lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́, bóyá ní ríronú pé àwọn yóò jèrè ìtura díẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àṣìṣe ńláǹlà ni ìyẹn jẹ́.
8 A mọrírì rẹ̀ pé àjàgà tí Jesu nawọ́ rẹ̀ jẹ́ ti “inúrere.” Bí a kò bá gbà á sọ́rùn dáradára, ó lè dégbò sí wa lọ́rùn. Bí èyíinì bá ṣẹlẹ̀ a níláti fún àjàgà tí ó wà ní èjìká wa ní àfiyèsí. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé fún àwọn ìdí kan, àjàgà náà béèrè àtúnṣe tàbí a kò so ó dáradára, kì í ṣe pé lílò ó yóò béèrè ìsapá púpọ̀ síi ní ìhà ọ̀dọ̀ wa nìkan ni ṣùgbọ́n yóò fa ìrora díẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àbájáde rẹ̀. Ní èdè mìíràn, bí àwọn ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọrun bá bẹ̀rẹ̀ sí dàbí ẹrù-ìnira fún wa, a gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò láti wò bóyá a fọwọ́ tí ó tọ́ mú wọn. Kí ni ìsúnniṣe wa fún ohun tí a ń ṣe? A ha múrasílẹ̀ dáradára nígbà tí a bá lọ sí àwọn ìpàdé bí? A ha ti múrasílẹ̀ nípa ti ara àti ti èrò-orí nígbà tí a bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá bí? A ha ń gbádùn ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ tí ó sì dára pẹ̀lú àwọn mìíràn nínú ìjọ bí? Àti, ju gbogbo rẹ̀ lọ, báwo ni ipò-ìbátan wa pẹ̀lú Jehofa Ọlọrun àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi ṣe rí?
9. Èéṣe tí àjàgà Kristian kò fi gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrù-ìnira tí kò ṣeé gbé?
9 Nígbà tí a bá fi tọkàntọkàn gba àjàgà tí Jesu nawọ́ rẹ̀ tí a sì kọ́ láti gbé e dáradára, kò sí ìdí kankan fún un láti dàbí ẹrù-ìnira tí kò ṣeé múmọ́ra. Níti tòótọ́, bí a bá lè fi ojú inú wo ipò náà—Jesu lábẹ́ àjàgà kan náà pẹ̀lú wa—kò nira fún wa láti rí ẹni náà tí ń gbé apá tí ó pọ̀ jùlọ nínú ẹrù-ìnira náà níti gidi. Ó jọ ti ọmọ àfànítẹ̀ẹ̀tẹ́ tí ó rọ̀ mọ́ ọwọ́ kẹ̀kẹ́ rẹ̀, tí ó rò pé òun ń tì í síwájú, ṣùgbọ́n níti gidi, gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí, òbí náà ni ẹni tí ń ṣe é. Gẹ́gẹ́ bíi Baba onífẹ̀ẹ́, Jehofa Ọlọrun mọ ibi tí agbára wa mọ dáadáa àti àlèébù wa, ó sì ń dáhùnpadà sí àwọn àìní wa nípasẹ̀ Jesu Kristi. Paulu wí pé: “Ọlọrun . . . yoo pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní yín dé ìwọ̀n ọrọ̀ rẹ̀ ninu ògo nípasẹ̀ Kristi Jesu.”—Filippi 4:19; fiwé Isaiah 65:24.
10. Kí ni ó ti jẹ́ ìrírí ẹnì kan tí ó ti mú iṣẹ́ sísọni di ọmọ-ẹ̀yìn bí ohun tí ó ṣe pàtàkì?
10 Ọ̀pọ̀ àwọn Kristian olùṣèyàsímímọ́ ti wá mọrírì èyí nípasẹ̀ ìrírí ara-ẹni. Fún àpẹẹrẹ, Jenny jẹ ẹnì kan, tí ó ríi pé ṣíṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣooṣù àti ṣíṣiṣẹ́ fún gbogbo àkókò níbi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí ń múni wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ tí ó ga fi í sábẹ́ másùnmáwo tí ó peléke. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó nímọ̀lára pé iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ran òun lọ́wọ́ láti pa ìwàdéédéé òun mọ́. Ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bibeli àti rírí wọn bí wọ́n ti ń yí ìgbésí-ayé wọn padà láti jèrè ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun—èyí ni ohun tí ó mú ìdùnnú-ayọ̀ tí ó tóbi jùlọ wá fún un nínú ìgbésí-ayé rẹ̀ tí ó dí fọ́fọ́. Ó gbà tọkàntọkàn pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ òwe tí ó sọ pé: “Ìbùkún Oluwa níí múnií là, kì í sìí fi làálàá pẹ̀lú rẹ̀.”—Owe 10:22.
Ẹrù Tí Ó Fúyẹ́
11, 12. Kí ni ohun tí Jesu ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ pé: “Ẹrù mi . . . fúyẹ́”?
11 Ní àfikún sí ṣíṣèlérí àjàgà tí ó jẹ́ ti “inúrere” fún wa, Jesu fi dá wa lójú pé: “Ẹrù mi . . . fúyẹ́.” Àjàgà tí ó jẹ́ ti “inúrere” ti mú kí iṣẹ́ náà rọrùn tẹ́lẹ̀; bí ẹrù náà pẹ̀lú bá tún fúyẹ́, iṣẹ́ náà jẹ́ ìgbádùn ní tòótọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, kí ni Jesu ní lọ́kàn nípa sísọ gbólóhùn yẹn?
12 Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí àgbẹ̀ kan yóò ṣe nígbà tí ó bá fẹ́ láti pààrọ̀ iṣẹ́ fún àwọn ẹranko rẹ̀, jẹ́ kí a sọ pé láti inú títu ilẹ̀ sí fífa ọmọlanke. Yóò kọ́kọ́ yọ ohun-èèlò ìtúlẹ̀ náà kúrò lẹ́yìn náà yóò so ọmọlanke mọ́ ọn. Kì yóò bọ́gbọ́nmu lójú rẹ̀ láti so ohun-èèlò ìtúlẹ̀ àti ọmọlanke pọ̀ mọ́ àwọn ẹranko náà. Bákan náà, kì í ṣe pé Jesu ń sọ fún àwọn ènìyàn náà láti gbé ẹrù tirẹ̀ lé orí èyí tí wọ́n ti ń gbé tẹ́lẹ̀. Ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kò sí ìránṣẹ́ ilé tí ó lè jẹ́ ẹrú fún ọ̀gá méjì.” (Luku 16:13) Nípa báyìí, Jesu ń fún àwọn ènìyàn náà ní yíyàn kan. Wọn yóò ha máa báa lọ láti gbé ẹrù-ìnira tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀, tàbí wọn yóò ha gbé ìyẹn sílẹ̀ kí wọ́n sì tẹ́wọ́gba èyí tí ó ń nawọ́ rẹ̀ sí wọn? Jesu fún wọn ní ìṣírí onífẹ̀ẹ́: “Ẹrù mi . . . fúyẹ́.”
13. Ẹrù wo ni àwọn ènìyàn ń gbé ní ọjọ́ Jesu, pẹ̀lú ìyọrísí wo sì ni?
13 Ní ọjọ́ Jesu, àwọn ènìyàn náà ń jìjàkadì lábẹ́ ẹrù tí ó wúwo tí àwọn alákòóso Romu aninilára àti àwọn aláfẹnujẹ́, aṣáájú ìsìn alágàbàgebè gbé kà wọ́n lórí. (Matteu 23:23) Nínú ìgbìyànjú láti gbé ẹrù Romu kúrò, àwọn ènìyàn kan gbìyànjú láti yanjú ọ̀ràn náà fúnra wọn. Wọ́n lọ́wọ́ nínú ìjàkadì olóṣèlú, kìkì láti wá sí òpin oníjàábá. (Ìṣe 5:36, 37) Àwọn mìíràn pinnu láti mú kí ipò nǹkan wọn túbọ̀ sunwọ̀n síi nípa kíkó wọnú ìsapá onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì bámúbámú. (Matteu 19:21, 22; Luku 14:18-20) Nígbà tí Jesu nawọ́ ọ̀nà sí ibi ìtura fún wọn nípa kíké sí wọn láti di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kì í ṣe gbogbo wọn ni ó múratán láti gbà. Wọ́n lọ́tìkọ̀ láti gbé ẹrù tí wọ́n ń rù kalẹ̀, bí ó ti wúwo tó nì, kí wọ́n sì gba tirẹ̀. (Luku 9:59-62) Ẹ wo bí ó ti jẹ́ àṣìṣe amúnibanújẹ́ tó!
14. Báwo ni àníyàn ìgbésí-ayé àti ìfẹ́-ọkàn nǹkan ti ara ṣe lè di ẹrù wọ̀ wá lọ́rùn?
14 Bí a kò bá ṣọ́ra, a lè ṣe irú àṣìṣe kan náà lónìí. Dídi ọmọ-ẹ̀yìn Jesu yọ wá kúrò nínú lílé góńgó àti ìjẹ́pàtàkì kan náà kiri gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ayé ti ń ṣe. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ṣì níláti ṣiṣẹ́ kára láti ní àwọn ohun kòṣeémánìí ojoojúmọ́, a kò fi àwọn ohun wọ̀nyí ṣe kókó pàtàkì ìgbésí-ayé wa. Síbẹ̀, àníyàn ìgbésí-ayé àti ìtànjẹ ìgbádùn ti ara lè wà wá mú lọ́nà tí ó lágbára. Bí a bá fàyè gbà á, irú àwọn ìfẹ́-ọkàn bẹ́ẹ̀ lè fún òtítọ́ tí a ti háragàgà tẹ́wọ́gbà pa. (Matteu 13:22) Ọwọ́ wa lè dí fún mímú irú àwọn ìfẹ́-ọkàn bẹ́ẹ̀ ṣẹ débi pé àwọn ẹrù-iṣẹ́ Kristian wa á wá di àìgbọdọ̀máṣe tí ń súni tí a kàn fẹ́ ṣe é kí a sì mú un kúrò lọ́nà kíákíá. Dájúdájú a kò lè retí kí ìtura kankan wá láti inú iṣẹ́-ìsìn wa sí Ọlọrun bí a bá ṣe é pẹ̀lú irú ẹ̀mí yẹn.
15. Ìkìlọ̀ wo ni Jesu fúnni nípa ìfẹ́-ọkàn nǹkan ti ara?
15 Jesu ṣàlàyé pé ìgbésí-ayé onítẹ̀ẹ́lọ́rùn ń wá, kì í ṣe nípa lílàkàkà láti dójú ìwọ̀n gbogbo àìní wa, ṣùgbọ́n nípa mímójútó àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbésí-ayé. Ó gbà wá níyànjú pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn nipa ọkàn yín níti ohun tí ẹ̀yin yoo jẹ tabi ohun tí ẹ̀yin yoo mu, tabi nipa ara yín níti ohun tí ẹ̀yin yoo wọ̀. Ọkàn kò ha ṣe pàtàkì ju oúnjẹ ati ara ju aṣọ lọ?” Lẹ́yìn náà ó pe àfiyèsí sí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ó sì sọ pé: “Wọn kì í fún irúgbìn tabi ká irúgbìn tabi kó jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pamọ́; síbẹ̀ Baba yín ọ̀run ń bọ́ wọn.” Nígbà tí ó ń tọ́ka sí àwọn òdòdó lílì pápá, ó wí pé: “Wọn kì í ṣe làálàá, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú; ṣugbọn mo wí fún yín pé àní Solomoni pàápàá ninu gbogbo ògo rẹ̀ ni a kò ṣe ní ọ̀ṣọ́-ẹ̀yẹ bí ọ̀kan lára awọn wọnyi.”—Matteu 6:25-29.
16. Kí ni ìrírí ti fi hàn nípa ipa tí ìlépa nǹkan ti ara ń ní?
16 A ha lè kẹ́kọ̀ọ́ ohun kankan lára ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n ṣókí tí ó gbéṣẹ́ yìí bí? Ìrírí tí ó wọ́pọ̀ ni pé bí ẹnì kan bá ti ń làkàkà láti mú ipò rẹ̀ nípa nǹkan ti ara nínú ìgbésí-ayé sunwọ̀n síi tó, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe máa kó wọnú ìlépa nǹkan ti ayé tó, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ẹrù-ìnira tí ó wà ní èjìká rẹ̀ yóò ṣe wúwo tó. Ayé kún fún àwọn oníṣòwò tí wọ́n ti jìyà ìdílé tí ó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, ìgbéyàwó tí ó dojúdé, ìlera tí ó bàjẹ́, àti ọ̀pọ̀ nǹkan nítorí àṣeyọrí nǹkan ti ara. (Luku 9:25; 1 Timoteu 6:9, 10) Albert Einstein tí ó ti gba ẹ̀bùn Nobel sọ nígbà kan rí pé: “Ohun-ìní, àṣeyọrí tí ó ṣe é fojúrí, òkìkí, ìṣefàájì—lójú tèmi nígbà gbogbo ni àwọn wọ̀nyí ti jẹ́ ohun ìyọṣùtìsí. Mo nígbàgbọ́ pé ìgbésí-ayé tí ó mọníwọ̀n tí ó jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì ni ó dára jùlọ fún gbogbo ènìyàn.” Èyí wulẹ̀ sọ ní àsọtúnsọ ohun tí aposteli Paulu gbaniníyànjú ní ṣókí pé: “Ó jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá, ìfọkànsin Ọlọrun yii papọ̀ pẹlu ẹ̀mí ohun-moní-tómi.”—1 Timoteu 6:6.
17. Irú ìgbésí-ayé wo ni Bibeli dámọ̀ràn rẹ̀?
17 Apá pàtàkì kan wà tí a kò níláti gbójú fò dá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé “ìgbésí-ayé tí ó mọníwọ̀n tí ó jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì” ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní, kì í ṣe ohun tí ń mú ìtẹ́lọ́rùn wá fúnra rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà tí àyíká ipò ti mú ìgbésí-ayé wọn mọníwọ̀n ní ọ̀ranyàn, síbẹ̀ wọn kò nítẹ̀ẹ́lọ́rùn tàbí láyọ̀ rárá. Bibeli kò rọ̀ wá láti kọ ìgbádùn nǹkan ti ara kí a sì gbé ìgbésí-ayé aláhàámọ́. Kókó ìtẹnumọ́ náà ni ìfọkànsìn Ọlọrun, kì í ṣe ẹ̀mí ohun-moní-tómi. Kìkì ìgbà tí a bá mú méjèèjì papọ̀ ni a lè ní “ọ̀nà èrè ńlá.” Èrè wo? Síwájú síi nínú lẹ́tà kan náà, Paulu tọ́ka síi pé àwọn wọnnì tí wọ́n “gbé ìrètí wọn, kì í ṣe lé ọrọ̀ àìdánilójú, bíkòṣe lé Ọlọrun” ni yóò “fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn-ọ̀la, kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ gidi mú gírígírí.”—1 Timoteu 6:17-19.
18. (a) Báwo ni ẹnì kan ṣe lè rí ìtura tòótọ́? (b) Ojú wo ni a níláti fi wo àwọn ìyípadà tí a bá níláti ṣe?
18 Ìtura yóò wá sọ́dọ̀ wa bí a bá kọ́ láti gbé ẹrù ti ara-ẹni wa tí ó wúwo tí a ń gbé kalẹ̀ kí a sì gbé ẹrù tí ó fúyẹ́ tí Jesu fi lọ̀ wá. Ọ̀pọ̀ tí wọ́n ti tún ìgbésí-ayé wọn tò kí wọ́n baà lè nípìn-ín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ síi nínú iṣẹ́-ìsìn Ìjọba náà ti rí ọ̀nà sí ìgbésí-ayé aláyọ̀ àti onítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Àmọ́ ṣáá o, ó ń béèrè ìgbàgbọ́ àti ìgboyà fún ẹnì kan láti lè gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀, àwọn ohun ìdènà sì lè wà lọ́nà. Ṣùgbọ́n Bibeli rán wa létí pé: “Ẹni tí ó ń kíyèsí afẹ́fẹ́ kì yóò fúnrúgbìn; àti ẹni tí ó sì ń wojú àwọ̀sánmà kì yóò ṣe ìkórè.” (Oniwasu 11:4) Ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan kò fi bẹ́ẹ̀ ṣòro níwọ̀n ìgbà tí a bá ti pọkàn wa pọ̀ láti ṣe wọ́n. Ó dàbí pé, apá tí ó le jùlọ níbẹ̀ ni pípọkàn wa pọ̀. Àárẹ̀ lè mú wa nípa jíjìkàkadì pẹ̀lú èrò náà tàbí kíkọ̀ ọ́ sílẹ̀. Bí a bá mọ́kàn wa le tí a sì tẹ́wọ́gba ìpèníjà náà, ó lè yà wá lẹ́nu láti rí irú ìbùkún tí ó yọrí sí. Onipsalmu náà rọ̀ wá pé: “Tọ́ ọ wò, kí o sì rí i pé, rere ni Oluwa.”—Orin Dafidi 34:8; 1 Peteru 1:13.
“Ìtura fún Ọkàn Yín”
19. (a) Kí ni ohun tí a níláti retí bí ipò ayé ti ń bàjẹ́ síi? (b) Nígbà tí a bá wà lábẹ́ àjàgà Jesu, ìdálójú kí ni a fún wa?
19 Aposteli Paulu rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní ọ̀rúndún kìn-ínní létí pé: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú wọ ìjọba Ọlọrun.” (Ìṣe 14:22) Ìyẹn ṣì jẹ́ òtítọ́ lónìí. Bí ipò àwọn nǹkan nínú ayé ti ń bá a lọ láti máa bàjẹ́ síi, ìkìmọ́lẹ̀ tí ń wá sórí àwọn wọnnì tí wọ́n bá pinnu láti gbé ìgbésí-ayé òdodo àti ti ìfọkànsìn Ọlọrun yóò tilẹ̀ túbọ̀ pọ̀ síi. (2 Timoteu 3:12; Ìṣípayá 13:16, 17) Síbẹ̀, a nímọ̀lára ní ọ̀nà kàn náà bíi tí Paulu nígbà tí ó sọ pé: “A há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, ṣugbọn a kò há wa rékọjá yíyíra; ọkàn wa dàrú, ṣugbọn kì í ṣe láìsí ọ̀nà àbájáde rárá; a ṣe inúnibíni sí wa, ṣugbọn a kò fi wá sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́; a gbé wa ṣánlẹ̀, ṣugbọn a kò pa wá run.” Ìdí ni pé a lè gbẹ́kẹ̀lé Jesu Kristi láti fún wa ní okun tí ó rékọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá. (2 Korinti 4:7-9) Nípa títẹ́wọ́gba àjàgà ti ọmọ-ẹ̀yìn tọkàntọkàn, a óò gbádùn ìmúṣẹ ìlérí Jesu pé: “Ẹ̀yin yoo . . . rí ìtura fún ọkàn yín.”—Matteu 11:29.
O Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Kí ni àjàgà onínúrere tí Jesu nawọ́ rẹ̀?
◻ Kí ni a níláti ṣe bí a bá nímọ̀lára pé àjàgà wa ń di ẹrù-ìnira?
◻ Kí ni Jesu ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ pé: “Ẹrù mi . . . fúyẹ́”?
◻ Báwo ni a ṣe lè ríi dájú pé ẹrù wa wà ní fífúyẹ́?