ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 8/15 ojú ìwé 23-27
  • Àwọn Agbo-ilé Olùṣòtítọ́ Ń mú Ìbísí Yá Kánkán Ní Sri Lanka

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Agbo-ilé Olùṣòtítọ́ Ń mú Ìbísí Yá Kánkán Ní Sri Lanka
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Kíkojú Ìpèníjà Náà
  • Ìdílé Tí A Ṣètò Ń Mú Ìyìn Wá
  • Àtakò So Ìdílé Pọ̀ Nínú Ìjọsìn Tòótọ́
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 8/15 ojú ìwé 23-27

Àwọn Agbo-ilé Olùṣòtítọ́ Ń mú Ìbísí Yá Kánkán Ní Sri Lanka

SRI LANKA jẹ́ erékùṣù rírẹwà tí a gbin ọ̀pẹ sí àwọn etíkun rẹ̀, ọ̀wọ́ àwọn òkè-ńlá gìn-ìn-rìn-gìn, tí ó sì ní aṣálẹ̀ kékeré, a mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bí Ceylon títí di 1972. Ní orí ilẹ̀, Òkè-Ṣóńṣó Adam, tí ó ga ní mítà 2,243, jẹ́ ọ̀gangan-ojú-àyè mímọ́-ọlọ́wọ̀ fún ìsìn mẹ́rin pàtàkì.a Lẹ́bàá rẹ̀ ni Ìpẹ̀kun Ayé wà, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ kan níbi tí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àpáta ti jìn sísàlẹ̀ jìngòdò ní èyí tí ó lé ní mítà 1,500. Ọ̀gangan-ojú-àyè náà jẹ́ ibi oníran àpéwò jùlọ ní Sri Lanka.

Àwọn million 18 olùgbé Sri Lanka ṣàjọpín ipò àtilẹ̀wá kan tí ó fanimọ́ra. Láti ọ̀rúndún karùn-ún B.C.E., àwọn Indo-European tí orírun wọn jẹ́ láti àríwá India ti kún erékùṣù náà. Àwọn ni àwọn Sinhalese, tí wọ́n ti tó ìlàta nínú àwọn olùgbé náà nísinsìnyí. Lẹ́yìn náà, jálẹ̀ nǹkan bí ọ̀rúndún kejìlá, ìrọ́gììrì àwọn Tamil wáyé láti gúúsù India; àwọn wọ̀nyí ń gbé ní pàtàkì ní àríwá àti ìlà-oòrùn erékùṣù náà. Àwọn Portugal, Netherlands, àti Britain pẹ̀lú ti ṣe àwọn ìyípadà wọ́n sì ti ní ipa ìdarí tí ó wà pẹ́ títí láti ìgbà ìjọba agbókèèrè ṣàkóso. Ní àfikún síi, àwọn oníṣòwò ojú-òkun láti àwọn ilẹ̀ tí omi fẹ́rẹ̀ẹ́ yíká tán ti Arabia àti Malay ti tẹ̀dó sí àárín àwọn ènìyàn àdúgbò náà. Àwọn àdádó àwọn ará Europe, Parsi, China, àti àwọn mìíràn tún wà níbẹ̀.

Yàtọ̀ sí ẹ̀yà-ìran tí ó dàpọ̀mọ́ra, èdè àti ìsìn ní Sri Lanka fi ìyàtọ̀ ipò àtilẹ̀wá hàn. Sinhalese, Tamil, àti Gẹ̀ẹ́sì ni àwọn olórí èdè ní erékùṣù náà. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Sri Lanka ń sọ ó kéré tan èdè méjì nínú mẹ́ta náà. Ipò àtilẹ̀wá ti ẹ̀yà-èdè tún kó ipa ńláǹlà nínú ìsìn àwọn ènìyàn náà. Ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn Sinhalese jẹ́ onísìn Buddha, nígbà tí ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn Tamil jẹ́ onísìn Hindu. Àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìdè pẹ̀lú ilẹ̀ Arabia tàbí Malay máa ń fara mọ́ ìsìn Islam lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn wọnnì tí wọ́n sì ní ipò àtilẹ̀wá ti ilẹ̀ Europe ní gbogbogbòò máa ń jẹ́ mẹ́ḿbà àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm, Katoliki àti Protẹstanti.

Kíkojú Ìpèníjà Náà

Gbogbo èyí gbé ìpèníjà tí ó gadabú ka iwájú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Sri Lanka. Àwọn wọ̀nyí ń ṣiṣẹ́ kára láti ṣe iṣẹ́ tí Jesu fifún wọn: “A óò sì wàásù ìhìnrere ìjọba yii ní gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé lati ṣe ẹ̀rí fún gbogbo awọn orílẹ̀-èdè.” (Matteu 24:14) Yàtọ̀ sí dídojú kọ èdè mélòókan, àwọn akéde ìhìnrere náà lè bá àwọn onísìn Buddha, Hindu, àwọn mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm sọ̀rọ̀, àti àwọn aláìgba Ọlọrun gbọ́ pẹ̀lú—gbogbo rẹ̀ ní wákàtí díẹ̀ ti wíwàásù.

Láti lè gbéṣẹ́ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn, àwọn akéde gbọ́dọ̀ mú àwọn ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli mìíràn ní èdè Tamil, Sinhalese, àti Gẹ̀ẹ́sì lọ́wọ́. Àwọn tí wọ́n lè gbé ẹrù wíwúwo tilẹ̀ máa ń gbé àwọn Bibeli ti àwọn èdè wọnnì. Ìdùnnú ṣubú láyọ̀ fún àwọn akéde náà láìpẹ́ yìí nígbà tí a ṣèmújáde ìwé pẹlẹbẹ náà Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? àti Our Problems—Who Will Help Us Solve Them? àti ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ayé Yii Yoo Ha Làájá Bi? ní èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lẹ́ẹ̀kan náà. Èyí túmọ̀ sí irin-iṣẹ́ púpọ̀ síi fún iṣẹ́ náà.

Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ti ń ṣiṣẹ́ kára láti 1912, nígbà tí Charles Taze Russell, ààrẹ Ẹgbẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli Káàkiri Orílẹ̀-Èdè nígbà náà, ṣe ìbẹ̀wò ráńpẹ́ sí Ceylon. Bí ó ti wù kí ó rí, ìdàgbàsókè tí ó ṣe pàtàkì ti níláti dúró de dídé àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege Watchtower Bible School of Gilead ní 1947. Láti ìgbà náà wá, àwọn akéde ní Sri Lanka ti gbádùn àwọn ìyọrísí àtàtà láti inú iṣẹ́ ìwàásù wọn. Ní 1994 àwọn akéde Ìjọba 1,866 darí 2,551 ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lóṣooṣù, ní ìpíndọ́gba. Iye àwọn 6,930 tí wọ́n pésẹ̀ sí Ìṣe-Ìrántí sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po mẹ́rin àwọn akéde nínú gbogbo àwọn ìjọ. Ẹ wo irú ìbùkún àgbàyanu tí èyí jẹ́!

Ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ mìíràn kan, ìtẹ̀síwájú ní Sri Lanka lè dàbí èyí tí ó falẹ̀. Ó dàbí ẹni pé kòkó-abájọ kan ni ìdè ìdílé tí ó lágbára. Bí ó ti wù kí ó rí, nǹkan tún lè yí padà pẹ̀lú. Nígbà tí Korneliu ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Romu mú ìdúró rẹ̀ fún òtítọ́, agbo-ilé rẹ̀ mú ìdúró wọn pẹ̀lú. (Ìṣe 10:1, 2, 24, 44) Ìwé Ìṣe tún mẹ́nu kan àwọn agbo-ilé lílágbára mìíràn tí ó jẹ́ ti Kristian, títí kan àwọn ti Lidia, Krispu, àti ẹni tí ó fi Paulu àti Sila sẹ́wọ̀n.—Ìṣe 16:14, 15, 32-34; 18:8.

Ní tòótọ́, ìdè lílágbára ti ìdílé lè mú àǹfààní wá níbi tí ìṣètò rere àti ìtẹpẹlẹmọ́ pẹ̀lú ìṣòtítọ́ bá wà. Pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah 60:22 lọ́kàn, míṣọ́nnárì ọlọ́jọ́ pípẹ́ Ray Matthews sọ pé: “Ó dàbí ẹni pé Jehofa ń mú kí àwọn nǹkan yá kánkán nísinsìnyí ní àkókò yíyẹ, kì í wulẹ̀ ṣe nípasẹ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan ṣùgbọ́n nípasẹ̀ àwọn agbo-ilé pẹ̀lú.”

Ìdílé Tí A Ṣètò Ń Mú Ìyìn Wá

Ó dájú pé irú àwọn agbo-ilé olùṣòtítọ́ bẹ́ẹ̀ wà ní Sri Lanka lónìí. Fún àpẹẹrẹ, ìdílé Sinnappa tí a ṣètò dáradára wà tí ń gbé ní Kotahena, ìpínlẹ̀-agbègbè Colombo, ìlú-ńlá pàtàkì ti Sri Lanka. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì pẹ́ púpọ̀ tí olórí ìdílé náà, Marian kù, aya rẹ̀, Annamma, àti 12 lára àwọn ọmọ wọn 15, tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún 13 sí 33, ń bá a nìṣó láti ṣiṣẹ́sin Jehofa gẹ́gẹ́ bí agbo-ilé kan. Ní àkókò tí a ń kọ àkọsílẹ̀ yìí, mẹ́jọ lára wọn ti ṣe ìrìbọmi, mẹ́ta lára wọn sì wà nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Àwọn mẹ́ta mìíràn ti forúkọ sílẹ̀ nínú iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láti ìgbà dé ìgbà. Àwọn akéde mẹ́rin tí kò tíì ṣe ìrìbọmi wà lára àwọn tí ó kéré nínú agbo-ilé náà. Ní àfikún síi, àwọn ọmọ-ọmọ mẹ́rin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì kéré lọ́jọ́ orí, ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọ́n sì ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristian ní Ìjọ Colombo North ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.

Ní 1978 ni Annamma kọ́kọ́ gbọ́ ìhìnrere Ìjọba náà nígbà tí ó tẹ́wọ́gba ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà kan. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli bẹ̀rẹ̀, lẹ́yìn tí ó sì parí àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli náà Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye, Annamma ya ìgbésí-ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jehofa Ọlọrun ó sì ṣe ìrìbọmi, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ àkọ́kọ́ lélẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí ó jẹ́ ti agbo-ilé rẹ̀.

Bíi ti jagunjagun náà Korneliu, Annamma ní ìṣètò tí ó dára nínú agbo-ilé rẹ̀. Annamma rántí pé: “A níláti wéwèé fún àwọn ìpàdé Kristian àti àpéjọ—kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan ilé-ẹ̀kọ́. Aṣọ jẹ́ ìpèníjà kan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìbùkún Jehofa ó ṣeé ṣe fún wa láti rán àwọn aṣọ titun díẹ̀ fún àpéjọ kọ̀ọ̀kan. Gbogbo ìdílé lọ pẹ̀lú aṣọ tí ó dára àti oúnjẹ tí ó dára—wọ́n sì bú sẹ́rìn-ín pẹ̀lú.”

Àwọn ọmọ náà máa ń rántí ìṣètò agbo-ilé wọn pẹ̀lú ìfẹ́ni. Láti ran ìdílé náà lódindi lọ́wọ́ láti pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé Kristian, nígbà gbogbo ni a ń fún àwọn tí ó dàgbà jù ní àwọn àkànṣe ẹrù-iṣẹ́. Fún àpẹẹrẹ, Mangala ni ó ń fọ aṣọ, Winnifreda yóò sì lọ̀ ọ́. Winnifreda, tí ó tún máa ń múra fún àwọn tí ó kéré jù, sọ pé: “Olúkúlùkù rí rèterète bí wọ́n ṣe ń fi ilé sílẹ̀.”

Ìpèsè tẹ̀mí ni a tún ṣètò lọ́nà kan náà. Pushpam ọmọbìnrin, tí ó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé nísinsìnyí, rántí pé: “Lójoojúmọ́, ìdílé wa máa ń gbádùn kíka Bibeli àti ṣíṣàyẹ̀wò ẹsẹ̀-ìwé Bibeli ojoojúmọ́ papọ̀.” Annamma fi kún un pé: “Ọmọ kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀dà Bibeli, Ilé-Ìṣọ́nà, àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tirẹ̀. Mo ń fetísílẹ̀ dáradára sí gbogbo ọ̀rọ̀-ìlóhùnsí wọn ní àwọn ìpàdé. Níbi tí ó bá ti pọndandan, mo máa ń ṣiṣẹ́ lé e lórí ní ilé pẹ̀lú ìṣírí àti àtúnṣe. Ní alẹ́ a óò parapọ̀ láti mú ọjọ́ náà wá sí òpin pẹ̀lú àdúrà ìdílé wa.”

Àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà wúlò púpọ̀ ní ríran Annamma lọ́wọ́ láti pèsè ẹ̀kọ́ Kristian tí ó dára púpọ̀ fún gbogbogbòò nínú ìdílé náà. Bí ó ti wù kí ó rí, ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ó há gádígádí náà kò dí ìfẹ́-ọkàn wọn láti ṣàjọpín ìhìnrere náà lẹ́yìn òde ilé wọn lọ́wọ́. Lápapọ̀, onírúurú mẹ́ḿbà ìdílé náà ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli 57 nínú ilé pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń bẹ ní àdúgbò. Rajan tí ó jẹ́ àna sọ pé: “Ìdílé náà ń darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ń tẹ̀síwájú. Pushpam, aya mi, ti ní àǹfààní rírí ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tí ó ya ìgbésí-ayé ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jehofa.”

Ó dá họ́wùhọ́wù ńlá sílẹ̀ ní Kotahena nígbà tí irú ìdílé ńlá bẹ́ẹ̀ fi Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Katoliki sílẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àlùfáà náà fúnra rẹ̀ kò bẹ ìdílé náà wò rí láti wádìí ohun tí ó fa sábàbí, ó ní kí àwọn mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì náà ṣè ìwádìí. Ọ̀pọ̀ ìjíròrò tẹ̀lé e, ní pàtàkì nípa ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan. Annamma máa ń fìgbà gbogbo gbáralé Jehofa àti Bibeli láti gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ẹsẹ̀-ìwé mímọ́ tí ó yàn láàyò nínú àwọn ìjíròrò wọ̀nyí ni Johannu 17:3.

Agbo-ilé Sinnappa fi hàn gbangba pé ìṣètò tí ó dára àti ìsapá léraléra lè mú ìyọrísí tí ó tẹ́ni lọ́rùn wá. Nípa ìsapá onítara wọn, ìran titun àwọn akéde Ìjọba ń dàgbà, gbogbo rẹ̀ sí ìyìn Jehofa.

Àtakò So Ìdílé Pọ̀ Nínú Ìjọsìn Tòótọ́

Agbo-ilé Ratnam wà ní ibùsọ̀ díẹ̀ tí kò jìnnà sí àwọn Sinnappa, ní Narhenpitya, ìpínlẹ̀-agbègbè mìíràn ti Colombo. Àwọn pẹ̀lú jẹ́ onísìn Roman Katoliki tẹ́lẹ̀rí. Ní 1982, àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó lọ́wọ́ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé kàn sí Balendran, ọkọ ọmọbìnrin tí ó dàgbà jùlọ, Fatima. A bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan pẹ̀lú gbogbo ìdílé náà. Láìpẹ́ àwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ń béèrè nípa orúkọ Ọlọrun lọ́wọ́ Ignasiamal Ìyá-Àgbà. Nígbà tí àwọn ọmọ náà pèsè ìdáhùn náà “Jehofa,” wọ́n ru ọkàn-ìfẹ́ Ìyá-Àgbà sókè, a sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, méjì lára àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, Jeevakala àti Stella, darapọ̀ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, nígbà tí yóò sì fi di 1988 gbogbo àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti ṣe ìrìbọmi.

Ní àkókò kan náà, Balendran àti Fatima ṣàjọpín òtítọ́ náà pẹ̀lú àbúrò Fatima mìíràn tí ó jẹ́ obìnrin, Mallika, àti ọkọ rẹ̀, Yoganathan. Nígbà tí yóò fi di 1987 àwọn tọkọtaya yìí ti ṣe ìrìbọmi, wọ́n sì ti gbin ìfẹ́ tí ń dàgbà fún Jehofa sínú ọkàn àwọn ọmọ wọn méjèèjì. Pushpa, òmíràn lára àwọn àbúrò Fatima tí ó jẹ́ obìnrin, ni ó tẹ̀lé e. Ó ṣe ìyàsímímọ́ ara rẹ̀ ó sì ṣe ìrìbọmi ní 1990. Nígbà tí ó wà ní Tokyo, ọkọ rẹ̀, Eka, ṣiṣẹ́sìn pẹ̀lú ìjọ tí ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, Pushpa sì ran ọ̀dọ́mọkùnrin wọn, Alfred, lọ́wọ́ nípa títọ́ ọ dàgbà ní ọ̀nà Jehofa.

Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, mẹ́rin nínú àwọn ọmọ mẹ́wàá ti ìdílé Ratnam ti mú ìdúró wọn fún ìjọsìn tòótọ́. Ó dùnmọ́ni pé, àwọn mẹ́ta mìíràn ń tẹ̀síwájú dáradára nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ti ara-ẹni wọn. Lára àwọn ọmọ-ọmọ 11, ọmọbìnrin kan, Pradeepa, ti ṣe ìrìbọmi. Àwọn méje mìíràn tí wọn ṣì kéré ní a ń fún ní ìtọ́ni déédéé nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìdílé wọn. Ní àfikún síi, àpapọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli 24 nínú ilé ni wọ́n ń darí pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn ní àdúgbò.

Gbogbo èyí kò wá lọ́nà tí ó rọrùn. Ní ìbẹ̀rẹ̀, àtakò ìdílé wà. Bàbá náà, Muthupillai, àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin ṣàtakò gidigidi sí èyíkéyìí nínú àwọn ìdílé wọn tí ó bá ń lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí tí ó bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù fún gbogbo ènìyàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lára èyí ní í ṣe pẹ̀lú àníyàn fún ààbò ara-ẹni, Muthupillai fi kún un pé: “Mo fi ara mi jìn pátápátá fún ‘àwọn ẹni mímọ́’ n kò sì gbà pé kí ìdílé mi fi Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki sílẹ̀.” Bí ó ti wù kí ó rí, nísinsìnyí, ó gbàgbọ́ pé wọ́n ń jọ́sìn Ọlọrun òtítọ́ náà nítorí pé ó lè rí àwọn àǹfààní tí ìgbàgbọ́ wọn ti mú wá fún wọn.

Fún àpẹẹrẹ, nígbà kan onílé wọn tí ó jẹ́ onísìn Buddha gbìdánwò láti lé wọn jáde kúrò nínú ilé rẹ̀ nípa fífi oògùn bá wọn jà. Ó wá ní alẹ́ ọjọ́ kan ó sì fi ọsàn wẹ́wẹ́ “tí a ti rẹ lóògùn” sí àyíká ilé náà. Ìbẹ̀rù dàbo àwọn aládùúgbò tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ohun asán gbogbo àwọn tí ń retí pé kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ kan ṣẹlẹ̀ sí agbo-ilé Ratnam. Ṣùgbọ́n, nígbà tí Ignasiamal rí èyí, òun àti àwọn ọmọ wulẹ̀ kó àwọn ọsàn wẹ́wẹ́ náà dànù láìbẹ̀rù rárá tàbí gbọ̀n jìnnìjìnnì—láburú kankan kò sì ṣẹlẹ̀ sí wọn. Ìgbésẹ̀ aláìbẹ̀rù wọn di ìjẹ́rìí gidi ní agbègbè náà, tí ó mú kí àwọn ènìyàn ní ọ̀wọ̀ ńláǹlà fún wọn. Ó ṣeé ṣe fún Stella láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli méjì nínú ilé ní àwọn agboolé tí kò jìnnà sí wọn. Nítorí ìṣírí tí èyí fún un, Nazeera aya ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú tẹ́wọ́gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.

Nígbà tí ó bojú wẹ̀yìn wo ọ̀pọ̀ ìbùkún tí ó ti wá sórí ìdílé rẹ̀, Ignasiamal sọ pé: “Inú mi dùn láti rí ìdàgbàsókè tẹ̀mí láàárín ìdílé. Jehofa ti bùkún wa nítorí pé àtakò ti rọlẹ̀, ìṣọ̀kan ìdílé wa sì ti pọ̀ síi.”

Ẹ wo irú ìbùkún tí agbo-ilé ńlá yìí ti jẹ́. Wọ́n ti pa ohùn wọn pọ̀ mọ́ ti àwọn ìdílé kéékèèké, àwọn ìdílé olóbìí kan, àti àwọn Kristian kò-lọ́kọ kò-láya tí ń sakun kárakára láti mú kí ìpolongo ìhìnrere Ìjọba náà yá kánkán ní “ilẹ̀ ológo ẹwà dídán,” gẹ́gẹ́ bí ohun tí orúkọ náà Sri Lanka túmọ̀ sí. Papọ̀ pẹ̀lú àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wọn kárí-ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí ní Sri Lanka ń fojú sọ́nà fún ìmúpadàbọ̀sípò Paradise, èyí tí a lè rántí nísinsìnyí pàápàá bí a ṣe ń rí àwọn etíkun àti òkè-ńlá Sri Lanka ọlọ́pọ̀ ẹwà.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìjìnwọnú ńlá kan tí ń bẹ níbẹ̀ ni a lérò pé ó jẹ́ ipasẹ̀ Adam, Buddha, Siva, àti Thomas “Mímọ́,” ní ìtòtẹ̀léra, nínú àwọn àròfọ̀ àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn onísìn Musulumi, Buddha, Hindu, àti àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní Sri Lanka ń dáhùnpadà sí ìwàásù àti ẹ̀kọ́ àwọn Kristian

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́