Fi Ara Rẹ fún Ìwé Kíkà
ÀWỌN ẹranko ò lè ṣe ohun tó ò ń ṣe lọ́wọ́ yìí. Èèyàn kan nínú ẹni mẹ́fà láyé ni kò mọ̀wé kà, ó sì sábà máa ń jẹ́ nítorí àìláǹfààní láti lọ sílé ẹ̀kọ́, kódà lára àwọn tó tiẹ̀ mọ̀wé kà pàápàá, ọ̀pọ̀ ni kì í kà á déédéé. Síbẹ̀, kíkà tó o lè ka ohun tí a bá tẹ̀ ń jẹ́ kí o lè fojú inú rìnrìn àjò lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, kí o bá àwọn èèyàn tí ayé wọn lè mú kí ayé rẹ túbọ̀ dáa sí i pàdé, ó sì ń jẹ́ kí o lè jèrè ìmọ̀ tó ṣeé mú lò, èyí tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú àwọn àníyàn inú ayé.
Ohun tó ò ń kà sétígbọ̀ọ́ àwọn ọmọ rẹ lè kọ́ wọn ní irú ìwà tí wọn yóò máa hù
Bí ọmọ kan bá ṣe mọ ìwé kà sí ni yóò ṣe jàǹfààní tó látinú ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ nílé ẹ̀kọ́. Bó bá sì di pé ó ń wáṣẹ́, bó ṣe mọ ìwé kà sí lè nípa lórí irú iṣẹ́ tó máa rí ṣe àti iye wákàtí tí yóò máa lò láti fi ṣiṣẹ́ láti lè gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Àwọn ìyàwó ilé tó bá mọ ìwé kà dáadáa yóò lè tọ́jú ìdílé wọn dáadáa tó bá di ọ̀ràn fífún wọn lóúnjẹ aṣaralóore, ṣíṣe ìmọ́tótó, àti dídènà àìsàn. Ìyá tó bá sì ń kàwé dáadáa tún lè nípa tó dára lórí bí ọpọlọ ọmọ rẹ̀ ṣe máa jí pépé tó.
Àmọ́ ṣá, àǹfààní gíga jù lọ tí o lè rí gbà látinú ìwé kíkà ni pé, ó lè mú kí o “rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.” (Òwe 2:5) Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọ̀nà tí a gbà ń sin Ọlọ́run ló gba pé kéèyàn mọ ìwé kà. A máa ń ka Ìwé Mímọ́ àti àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì ní àwọn ìpàdé ìjọ. Bí o ṣe mọ ìwé kà sí máa ń nípa gidigidi lórí bí o ṣe máa já fáfá tó lóde ẹ̀rí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, mímúra sílẹ̀ fún ìgbòkègbodò wọ̀nyí gba ìwé kíkà. Nítorí náà, bí o ṣe ń tẹ̀ síwájú sí nípa tẹ̀mí sinmi ní pàtàkì lórí bí o ṣe ń kàwé.
Lo Àǹfààní Tó Ṣí Sílẹ̀ Yìí
Kọ́ bí a ṣe ń kàwé ní gbangba lọ́nà tó dán mọ́rán
Àwọn kan tó ń kọ́ nípa ọ̀nà Ọlọ́run kò kàwé púpọ̀. Èyí ń béèrè pé kí á kọ́ wọn ní ìwé kíkà láti lè mú kí ìtẹ̀síwájú wọn nípa tẹ̀mí gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Ó sì lè jẹ́ pé wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ láti mú kí òye ìwé kíkà wọn já gaara sí i. Tí irú àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ bá wà nínú ìjọ kan, ìjọ máa ń gbìyànjú láti ṣètò fún ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló ti jàǹfààní gidigidi látinú ìṣètò yìí. Nítorí pé mímọ̀wé kà lọ́nà tó já gaara ṣe pàtàkì gan-an, àwọn ìjọ kan dá ilé ẹ̀kọ́ kàwé-já-gaara sílẹ̀, èyí tí wọ́n máa ń ṣe nígbà tí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run bá ń lọ lọ́wọ́. Kódà, níbi tí irú ìṣètò bẹ́ẹ̀ kò bá ti sí, èèyàn ṣì lè tẹ̀ síwájú dáadáa bí ó bá ń wá àkókò díẹ̀ láti kàwé sókè lójoojúmọ́, kí ó tún máa wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run déédéé kí ó sì máa kópa nínú rẹ̀.
Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn ìwé tó ń fi kìkì àwòrán sọ ìtàn àti tẹlifíṣọ̀n wíwò ti fẹ́rẹ̀ẹ́ paná ìfẹ́ ìwé kíkà lọ́kàn àwọn èèyàn. Tẹlifíṣọ̀n wíwò àti àìkì í fi bẹ́ẹ̀ kàwé lè máà jẹ́ kéèyàn tẹ̀ síwájú nínú ìwé kíkà, kéèyàn má sì lè ronú tàbí kó lo làákàyè rẹ̀ lọ́nà tó yè kooro, ó sì lè máà jẹ́ kéèyàn lè ṣàlàyé ara rẹ̀ dáadáa.
“Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” máa ń pèsè àwọn ìtẹ̀jáde tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì. Ìwọ̀nyí máa ń jẹ́ ká ní ọ̀pọ̀ ìsọfúnni nípa àwọn ohun tẹ̀mí tó ṣe pàtàkì. (Mát. 24:45; 1 Kọ́r. 2:12, 13) Wọ́n tún ń jẹ́ ká tètè mọ àwọn ọ̀ràn pàtàkì tó ń lọ láyé àti ìtumọ̀ wọn, wọ́n ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn ìṣẹ̀dá inú ayé, wọ́n sì ń kọ́ wa ní àwọn ọ̀nà tí a lè gbà yanjú àwọn ọ̀ràn tó bá kàn wá. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, wọ́n ń darí àfiyèsí sí bí a ṣe lè sin Ọlọ́run lọ́nà tí ó tẹ́wọ́ gbà kí á sì rí ojú rere rẹ̀. Kíka irú àwọn ìtẹ̀jáde tó gbámúṣé bẹ́ẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.
Òótọ́ ni pé kéèyàn kàn mọ ìwé kà geerege lásán kò lè dá ṣeni láǹfààní. Èèyàn ní láti lo ẹ̀bùn yẹn lọ́nà títọ́. Bí oúnjẹ tí à ń jẹ ni ìwé kíkà ṣe rí, a ní láti ṣàṣàyàn nínú ohun tí à ń kà. Kí nìdí tí wàá fi máa jẹ oúnjẹ tí kò lè ṣe ara rẹ lóore tàbí èyí tó tiẹ̀ lè jẹ́ májèlé fún ọ? Bákan náà, kí nìdí tí wàá fi máa ka ohun tó lè sọ èrò inú àti ọkàn rẹ dìbàjẹ́, ì báà tiẹ̀ jẹ pé o fẹ́ kà á ṣeré lásán? Àwọn ìlànà Bíbélì ló yẹ kó pèsè ìlànà tí a ó fi pinnu irú ìwé tó yẹ kí á kà. Kí o tó pinnu ohun tó o máa kà, kọ́kọ́ fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ́kàn, àwọn bí Oníwàásù 12:12, 13; Éfésù 4:22-24; 5:3, 4; Fílípì 4:8; Kólósè 2:8; 1 Jòhánù 2:15-17; àti 2 Jòhánù 10.
Ète Tí Ó Tọ́ Ni Kí Ó Sún Ọ Kàwé
Bí a bá ṣàyẹ̀wò ìtàn àwọn ìwé Ìhìn Rere, a ó rí bí ó ti ṣe pàtàkì tó pé kó jẹ́ ète tí ó tọ́ ló ń súnni kàwé. Bí àpẹẹrẹ, nínú Ìhìn Rere Mátíù, a rí i pé Jésù bi àwọn aṣáájú ìsìn tó ti ka Ìwé Mímọ́ lákàtúnkà ní àwọn ìbéèrè bí, “Ẹ kò ha kà pé?” àti “Ṣé ẹ kò tíì ka èyí rí pé?” kí ó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá fi Ìwé Mímọ́ dáhùn àwọn ìbéèrè ẹ̀kẹ́ẹ̀dẹ tí wọ́n ń bí i. (Mát. 12:3, 5; 19:4; 21:16, 42; 22:31) Ẹ̀kọ́ kan tí a rí kọ́ látinú èyí ni pé, bí kò bá jẹ́ ète tí ó tọ́ ló ń sún wa kàwé, a lè ṣi ohun tá a ń kà lóye tàbí kó má tilẹ̀ yé wa rárá. Ńṣe ni àwọn Farisí ń ka Ìwé Mímọ́ nítorí wọ́n rò pé kíkà tí àwọ́n ń kà á làwọn á fi rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà. Àmọ́, bí Jésù ṣe sọ, àwọn tí kò bá fẹ́ràn Ọlọ́run tí wọn ò sì tẹ́wọ́ gba ọ̀nà tí Ọlọ́run fi ń pèsè ìgbàlà, kò lè rí èrè ìyè gbà rárá. (Jòh. 5:39-43) Ète onímọtara ẹni nìkan ní ń bẹ lọ́kàn àwọn Farisí; nípa bẹ́ẹ̀ ọ̀pọ̀ ibi tí wọ́n parí èrò wọn sí ló lòdì.
Ìfẹ́ tí a ní sí Jèhófà ni ète mímọ́ jù lọ tó yẹ kó sún wa máa ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ ló máa ń mú kí á kọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́, nítorí ìfẹ́ “a máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́.” (1 Kọ́r. 13:6) Àní bí a kò bá tilẹ̀ fẹ́ràn ìwé kíkà tẹ́lẹ̀, fífi tí a fi “gbogbo èrò inú” wa fẹ́ Jèhófà yóò sún wa láti làkàkà gidigidi láti gba ìmọ̀ Ọlọ́run sọ́kàn. (Mát. 22:37) Ìfẹ́ máa ń mú kí nǹkan wuni, tí nǹkan bá sì ti wuni a óò fẹ́ láti kọ́ nípa rẹ̀.
Ronú Lórí Bí O Ṣe Ń Yára Kàwé Sí
Ńṣe ni ìwé kíkà àti dídá ọ̀rọ̀ mọ̀ jọ máa ń lọ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́. Kódà bó o ṣe ń kàwé yìí, ò ń dá àwọn ọ̀rọ̀ mọ̀, o sì ń rántí ohun tí wọ́n túmọ̀ sí. O lè mú kí ìwé kíkà rẹ yá kankan sí i bí o bá mú kí ìwọ̀n ọ̀rọ̀ tí ò ń dá mọ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo túbọ̀ pọ̀ sí i. Dípò kí o máa dúró wo ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan, gbìyànjú láti rí ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan lẹ́ẹ̀kan náà. Bí o bá ń ṣe èyí, ìwọ yóò rí i pé ohun tó ò ń kà yóò túbọ̀ yé ọ sí i.
Kíkàwé pa pọ̀ máa ń mú kí àwọn tó wà nínú ìdílé fà mọ́ra tímọ́tímọ́
Àmọ́, nígbà tó o bá ń ka ohun tó túbọ̀ jinlẹ̀ sí i, o lè jèrè púpọ̀ sí i látinú ìsapá rẹ bó o bá lo ọgbọ́n mìíràn. Nígbà tí Jèhófà ń fún Jóṣúà nímọ̀ràn lórí kíka Ìwé Mímọ́, ó ní: “Ìwé òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ, kí o sì máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà láti inú rẹ̀.” (Jóṣ. 1:8) Èèyàn sábà máa ń lo ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ nígbà tó bá ń ro àròjinlẹ̀. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Hébérù tí a túmọ̀ sí “fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà” ni a tún túmọ̀ sí “ṣe àṣàrò.” (Sm. 63:6; 77:12; 143:5) Nígbà tí èèyàn bá ń ṣe àṣàrò, ṣe ló máa ń ronú jinlẹ̀; kì í kánjú ṣe é. Béèyàn bá ń kàwé ní àkàronújinlẹ̀, ìyẹn máa ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túbọ̀ nípa lórí èrò inú àti ọkàn ẹni. Bíbélì ní àsọtẹ́lẹ̀ nínú, ìmọ̀ràn, àwọn òwe, ewì, àwọn ìpolongo ìdájọ́ Ọlọ́run, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ète Jèhófà, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpẹẹrẹ àwòkọ́ṣe téèyàn lè tẹ̀ lé ní ìgbésí ayé, tó sì jẹ́ pé gbogbo rẹ̀ ló wúlò fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ rìn ní àwọn ọ̀nà Jèhófà. Ó mà ṣàǹfààní gan-an o pé kí o ka Bíbélì lọ́nà tí yóò fi lè wọni lọ́kàn kó sì wọni lára!
Kọ́ Bí A Ṣe Ń Pọkàn Pọ̀
Bí o ṣe ń kàwé sí lè nípa lórí bí o ṣe ń tẹ̀ síwájú sí nípa tẹ̀mí
Bó o ṣe ń kàwé, jẹ́ kí ó dà bíi pé o wà níbi tí ohun tí ìwé náà ń ṣàpèjúwe ti ṣẹlẹ̀. Gbìyànjú láti fojú inú wo àwọn ẹni tí ìtàn náà ń sọ̀rọ̀ wọn, kí o sì fi ara rẹ sípò wọn láti mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Èyí dà bíi pé ó máa ń rọrùn láti ṣe bó o bá ń ka irú ìtàn bíi ti Dáfídì àti Gòláyátì, èyí tó wà nínú Sámúẹ́lì kìíní orí kẹtàdínlógún. Kódà àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe kọ́ àgọ́ ìjọsìn àti ìfilọ́lẹ̀ ipò àlùfáà, èyí tó wà nínú ìwé Ẹ́kísódù àti Léfítíkù pàápàá, yóò dà bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lójú rẹ bí o bá ń fojú inú wo ìbú àti òró àwọn nǹkan tí Ìwé Mímọ́ mẹ́nu kàn àti bí nǹkan wọ̀nyẹn ṣe rí lójú, tàbí bí o bá ń ṣe bí ẹní gbọ́ òórùn tùràrí, òórùn àwọn ọkà sísun àti àwọn ẹran tí wọ́n fi ń rú ọrẹ ẹbọ sísun. Fojú inú wo bí yóò ṣe jẹ́ ohun ẹ̀rù tó láti máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà! (Lúùkù 1:8-10) Bí o bá ń fi iyè inú àti ìmọ̀lára rẹ bá ohun tó ò ń kà lọ lọ́nà yìí, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ìtumọ̀ ohun tó ò ń kà, ìyẹn á sì lè jẹ́ kí o rántí wọn.
Ṣùgbọ́n bí o kò bá ṣọ́ra, bí o bá ń gbìyànjú láti kàwé, ọkàn rẹ lè máa rìn gbéregbère kiri. O lè ranjú mọ́ ìwé náà, síbẹ̀ kó jẹ́ pé ibòmíràn ni ọkàn rẹ wà. Ṣé orin ò máa lọ lábẹ́lẹ̀? Ṣé o ò tan tẹlifíṣọ̀n sílẹ̀? Ṣé àwọn ará ilé ò máa pariwo? Tó bá ṣeé ṣe, ibi tó pa rọ́rọ́ ló dára jù lọ fúnni láti kàwé. Àmọ́, ìpínyà ọkàn lè tinú ẹni lọ́hùn-ún wá o. Bóyá o fi àárọ̀ ṣúlẹ̀ ṣiṣẹ́ kárakára. Wẹ́rẹ́ báyìí ni ìrònú nípa ìgbòkègbodò ọjọ́ yẹn lè padà wá sí ọ lọ́kàn! Lóòótọ́, ó dára pé kéèyàn padà ronú lórí ìgbòkègbodò ẹni lójúmọ́, àmọ́ kò yẹ kó jẹ́ ìgbà tó o bá ń kàwé. Bóyá o tilẹ̀ pọkàn pọ̀ nígbà tó o bẹ̀rẹ̀, o tiẹ̀ lè ti gbàdúrà kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí kàwé. Ṣùgbọ́n kó di pé bó o ṣe ń kàwé lọ, ọkàn rẹ bẹ̀rẹ̀ sí kúrò níbẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Tún gbìyànjú láti pọkàn pọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Fi kọ́ra láti máa pọkàn pọ̀ sórí ohun tí o bá ń kà. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wàá rí i pé o túbọ̀ ń ṣe dáadáa sí i.
Kí lo máa ń ṣe bí o bá débi ọ̀rọ̀ kan tí kò yé ọ? Àlàyé tàbí ìtumọ̀ àwọn kan lára àwọn ọ̀rọ̀ tí o kò mọ̀ yìí lè wà nínú ìwé náà. O sì lè róye ìtumọ̀ rẹ̀ látinú ọ̀rọ̀ tó yí i ká. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, wá àyè láti wo ọ̀rọ̀ náà nínú ìwé atúmọ̀ èdè kan bí ó bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó, tàbí kí o sàmì sí ọ̀rọ̀ yẹn kí o lè béèrè ìtumọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ ẹnì kan lẹ́yìn náà. Èyí á jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ tó o mọ̀ túbọ̀ pọ̀ sí i, á sì jẹ́ kí ohun tí o bá ń kà túbọ̀ máa yé ọ sí i.
Kíkàwé ní Gbangba
Máa bá a lọ ní fífi ara rẹ fún ìwé kíkà ní gbangba
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé kó máa bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ fún ìwé kíkà, ọ̀rọ̀ nípa kíkàwé sétígbọ̀ọ́ àwọn ẹlòmíràn ló ń sọ ní pàtó. (1 Tím. 4:13) Kì í ṣe kéèyàn kàn máa pe ọ̀rọ̀ inú ìwé sókè lásán là ń pè ní kíkàwé ní gbangba lọ́nà tó jáfáfá. Òǹkàwé ní láti mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn kí ó sì lóye èrò tí wọ́n ń gbé jáde. Ìgbà tí òye yẹn bá yé e nìkan ló tó lè gbé èrò yẹn jáde lọ́nà títọ́ kí ó sì gbé bí nǹkan ṣe rí lára yọ níbẹ̀ lọ́nà tó bá a mu rẹ́gí. Ó dájú pé èyí ń béèrè ìmúrasílẹ̀ àti àṣedánrawò tó múná dóko. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi gbani níyànjú pé: “Máa bá a lọ ní fífi ara rẹ fún ìwé kíkà ní gbangba.” Ìwọ yóò gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó jíire nípa rẹ̀ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.
Máa Wá Àyè Láti Kàwé
“Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.” (Òwe 21:5) Òótọ́ gbáà nìyẹn jẹ́ tó bá di ti ìwé kíkà! Bí a bá fẹ́ jẹ “àǹfààní” yìí, a ní láti wéwèé dáadáa kí àwọn ìgbòkègbodò mìíràn má bàa gbapò ìwé kíkà.
Ìgbà wo lo máa ń kàwé ná? Ṣé ìdájí ló pé ọ láti máa jí kàwé? Tàbí ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ni ara rẹ máa ń yá sí ìwé kíkà jù lọ? Bí o bá lè ya ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ogún ìṣẹ́jú sọ́tọ̀ lóòjọ́ láti fi kàwé, àṣeyọrí tó o máa ṣe yóò yà ọ́ lẹ́nu. Kókó pàtàkì ibẹ̀ ni pé kó o máa kà á déédéé.
Kí nìdí tí Jèhófà fi yàn pé kí àwọn ète rẹ̀ àgbàyanu wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìwé kan? Kí àwọn èèyàn lè máa ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni. Èyí á mú kí wọ́n lè gbé àwọn iṣẹ́ àrà Jèhófà yẹ̀ wò, kí wọ́n sọ wọ́n fún àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n má sì gbàgbé àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run. (Sm. 78:5-7) Ọ̀nà tí a gbà ń ṣakitiyan láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń fúnni ní ìyè yìí ló máa sọ bí a ṣe mọrírì inúure tí Jèhófà fi hàn nípasẹ̀ ohun tó ṣe yìí tó.