ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 5/1 ojú ìwé 13-19
  • Jíjàǹfààní Láti Inú Bibeli Kíkà Lójoojúmọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jíjàǹfààní Láti Inú Bibeli Kíkà Lójoojúmọ́
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíkà Á Lójoojúmọ́
  • Yíyẹ Tí Ó Yẹ Láti Ka Bibeli Léraléra
  • Nígbà Tí A Lè Ka Bibeli
  • Àwọn Ọ̀nà Yíyàtọ̀síra Láti Gbà Ka Bibeli
  • Lóye Ohun Tí Ìwọ Ń Kà
  • Bíbélì Kíkà—Ó Lérè, Ó Sì Gbádùn Mọ́ni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Fi Ara Rẹ fún Ìwé Kíkà
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ní Inú Dídùn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Bibeli—Ìwé kan tí A Níláti Kà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 5/1 ojú ìwé 13-19

Jíjàǹfààní Láti Inú Bibeli Kíkà Lójoojúmọ́

“Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà . . . [ẹni tí] dídùn-inú rẹ̀ wà ní òfin Oluwa; àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti ní òru.”—ORIN DAFIDI 1:1, 2.

1. (a) Àkọlé tí ó hàn ketekete wo ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ kan orílé-iṣẹ́ àgbáyé ti Watch Tower Society? (b) Báwo ni a óò ṣe jàǹfààní bí a bá fi ìmọ̀ràn náà sọ́kàn ní ẹnìkọ̀ọ̀kan?

“MÁA KA BIBELI MÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌRUN LÓJOOJÚMỌ́.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí hàn ketekete ní ẹ̀gbẹ́ kan ilé-iṣẹ́ ní Brooklyn, New York, níbi tí a ti ń tẹ Bibeli àti àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society. Ìgbaniníyànjú yìí kì í ṣe fún kìkì àwọn ènìyàn ayé tí ń rí àkọlé yìí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọ̀ pé àwọn pẹ̀lú níláti fi í sọ́kàn. Àwọn wọnnì tí wọ́n ń ka Bibeli déédéé tí wọ́n sì ń fi sílò nínú ara wọn ń jàǹfààní láti inú ìkọ́ni, ìbániwí, ìmú-nǹkan-tọ́, àti ìbániwí nínú òdodo tí ó ń pèsè.—2 Timoteu 3:16, 17.

2. Báwo ni Arákùnrin Russell ṣe tẹnumọ́ ìjẹ́pàtàkì Bibeli kíkà?

2 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọrírì àwọn ìrànlọ́wọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọn gidigidi, èyí tí ó ní nínú Ilé-Ìṣọ́nà, wọ́n sì ń lo àwọn wọ̀nyí déédéé. Ṣùgbọ́n wọ́n mọ̀ pé kò sí èyíkéyìí nínú wọn tí ó lè gba ipò Bibeli fúnra rẹ̀. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún ní 1909, Charles Taze Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ ti Watch Tower Bible and Tract Society, kọ̀wé sí àwọn òǹkàwé ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà pé: “Máṣe gbàgbé láé pé Bibeli ni Ọ̀pá Ìdiwọ̀n wa àti pé bí ó ti wù kí ìrànlọ́wọ́ tí Ọlọrun fún wa pọ̀ tó ‘ìrànlọ́wọ́’ ni wọ́n, wọn kò dípò Bibeli.”

3. (a) Ipa wo ni “ọ̀rọ̀ Ọlọrun” ní lórí àwọn tí wọ́n ti fi ara wọn fún-un? (b) Báwo ni àwọn ará Berea ṣe ń ka Ìwé Mímọ́ léraléra tí wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tó?

3 Ìwé Mímọ́ tí a mí sí jinlẹ̀, ó sì ní agbára ìṣiṣẹ́ tí ìwé mìíràn kò ní. “Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wà láàyè ó sì ń sa agbára ó sì mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn ati ẹ̀mí níyà, ati awọn oríkèé oun mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú ati awọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Heberu 4:12) Ọmọ-ẹ̀yìn náà Luku fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà gbóríyìn fún àwọn ará Berea, ní pípè wọ́n ní ‘àwọn ẹni tí ó ní ọkàn-rere jù.’ Kì í ṣe pé wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà gẹ́gẹ́ bí Paulu àti alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ Sila ti wàásù fún wọn pẹ̀lú ìháragàgà nìkan ni ṣùgbọ́n wọ́n tún “fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́” láti pinnu ìpìlẹ̀ Ìwé Mímọ́ fún ohun tí wọ́n kọ́ wọn.—Ìṣe 17:11.

Kíkà Á Lójoojúmọ́

4. Kí ni Ìwé Mímọ́ fi hàn nípa bí ó ṣe yẹ kí a máa ka Bibeli léraléra tó?

4 Bibeli kò sọ ní pàtó bí a ṣe níláti máa kà á lemọ́lemọ́ tó. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣàkọsílẹ̀ ìmọ̀ràn Jehofa fún Joṣua láti ‘máa ṣe àṣàrò nínú ìwé òfin ní ọ̀sán àti ní òru’ kí ó ba à lè hùwà lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu kí ó sì lè ṣe àṣeyọrí nínú ṣíṣe iṣẹ́-àyànfúnni tí Ọlọrun fún un. (Joṣua 1:8) Ó sọ fún wa pé ẹni yòówù kí ó jọba lórí Israeli ìgbàanì níláti ka Ìwé Mímọ́ “ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo.” (Deuteronomi 17:19) Ó sọ síwájú síi pé: “Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú . . . Ṣùgbọ́n dídùn-inú rẹ̀ wà ní òfin Oluwa; àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti ní òru.” (Orin Dafidi 1:1, 2) Bákan náà, Ìròyìnrere tí a kọ sílẹ̀ nínú Matteu sọ fún wa pé nígbà tí Jesu Kristi ṣá gbogbo àwọn ìsapá Satani láti tàn Án jẹ tì, Ó fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu tí a mí sí, ní sísọ pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn gbọ́dọ̀ wà láàyè, kì í ṣe nípasẹ̀ búrẹ́dì nìkanṣoṣo, bíkòṣe nípasẹ̀ gbogbo gbólóhùn àsọjáde tí ń jáde wá lati ẹnu Jehofa.’” (Matteu 4:4) Báwo ni a ṣe nílò oúnjẹ nípa tí ara léraléra tó? Lójoojúmọ́! Jíjẹ oúnjẹ nípa tẹ̀mí tilẹ̀ tún ṣe pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ nítorí pé ó kan ìfojúsọ́nà wa fún ìyè ayérayé.—Deuteronomi 8:3; Johannu 17:3.

5. Báwo ni kíka Bibeli lójoojúmọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti “rìn lọ́nà tí ó yẹ Jehofa” nígbà tí ìdánwò ìgbàgbọ́ bá dojúkọ wá?

5 Gbogbo wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan níláti fún ara wa lókun lójoojúmọ́ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Lójoojúmọ́—ní ilé, ní ibi iṣẹ́, ní ilé-ẹ̀kọ́, ní òpópónà, nígbà tí a bá ń rajà, nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa—àwọn ìpènijà ìgbàgbọ́ wa ń dojúkọ wá. Báwo ni a óò ṣe kojú àwọn wọ̀nyí? Àwọn àṣẹ àti ìlànà Bibeli yóò ha wá sí ọkàn wa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ bí? Dípò fífún ìmọ̀lára ìfọkàn tán ara-ẹni ní ìṣírí, Bibeli kìlọ̀ pé: “Kí ẹni tí ó bá rò pé oun dúró kíyèsára kí ó má baà ṣubú.” (1 Korinti 10:12) Kíka Bibeli lójoojúmọ́ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti “rìn lọ́nà tí ó yẹ Jehofa fún ète wíwù ú ní kíkún” dípò yíyọ̀ọ̀da kí ayé sọ wa di dàbí-mo-ti-dà.—Kolosse 1:9, 10; Romu 12:2.

Yíyẹ Tí Ó Yẹ Láti Ka Bibeli Léraléra

6. Èéṣe tí ó fi ṣàǹfààní láti ka Bibeli lákàtúnkà?

6 Kíka Bibeli yàtọ̀ gédégbé sí kíka ìwé ìtàn-àròsọ. Ọ̀pọ̀ jùlọ ìtàn-àròsọ tí ó gbajúmọ̀ ni a ṣe fún kìkì kíkà lẹ́ẹ̀kan; níwọ̀n bí ẹnì kan bá ti mọ ìtàn inú rẹ̀ àti bí ó ṣe parí, kò sí ète kankan fún kíkà á mọ́. Ní ìyàtọ̀ sí èyí, láìka iye ìgbà tí a ti ka Bibeli sí, a ń jàǹfààní púpọ̀ nínú títún un kà. (Owe 9:9) Sí ẹnì kan tí ó jẹ́ olùfòyemọ̀, Ìwé Mímọ́ máa ń ní ìtumọ̀ ọ̀tun nígbà gbogbo. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ó níí ṣe pẹ̀lú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yóò wá di èyí tí a tẹ̀ mọ́ ọn lọ́kàn ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó rí, tí ó gbọ́, tí ó sì ní ìrírí rẹ̀ fúnra rẹ̀ ní àwọn oṣù lọ́ọ́lọ́ọ́. (Danieli 12:4) Bí ó ti ń mú ìrírí ara rẹ̀ nínú ìgbésí-ayé gbòòrò síi tí ó sì ń kojú àwọn ìṣòro, olùfòyemọ̀ náà tí ń ka Bibeli mọrírì àwọn ìmọ̀ràn tí ó ti ṣeé ṣe kí ó ti kà lọ́nà ṣákálá tẹ́lẹ̀ lẹ́kùn-uńrẹ́rẹ́ síi. (Owe 4:18) Bí ó bá ti ṣàìsàn lílekoko, àwọn ìlérí Bibeli nípa mímú ìrora kúrò àti ìmúpadàbọ̀sípò ìlera yóò túbọ̀ ní ìtumọ̀ tí ó jinlẹ̀ síi ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ àti àwọn mẹ́ḿbà ìdílé bá kú, ìlérí àjíǹde yóò túbọ̀ ṣe iyebíye síi.

7. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí a bá tẹ́wọ́gba ẹrù-iṣẹ́ titun nínú ìgbésí-ayé, èésìtiṣe?

7 Ó ti lè ka Bibeli fúnra rẹ kí o sì ti fi àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò láàárín àwọn ọdún bíi mélòókan. Ṣùgbọ́n bóyá o ń tẹ́wọ́gba àwọn ẹrù-iṣẹ́ titun nínú ìgbésí-ayé nísinsìnyí. O ha ń wéèwé láti ṣe ìgbéyàwó bí? Ìwọ yóò ha di òbí bí? A ha ti fún ọ ní ẹrù-iṣẹ́ nínú ìjọ gẹ́gẹ́ bí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ bí? O ha ti di ajíhìnrere alákòókò kíkún, pẹ̀lú àǹfààní tí ó pọ̀ síi fún wíwàásù àti kíkọ́ni? Ẹ wo bí yóò ti ṣàǹfààní tó láti ka gbogbo Bibeli lẹ́ẹ̀kan síi pẹ̀lú àwọn ẹrù-iṣẹ́ titun lọ́kàn!—Efesu 5:24, 25; 6:4; 2 Timoteu 4:1, 2.

8. Báwo ni àyíká ipò tí ó yàtọ̀ ṣe lè fi ìdí náà láti túbọ̀ kọ́ nípa àwọn nǹkan tí a lérò pé a ti mọ̀ hàn?

8 Ní àtẹ̀yìnwá o lè ti ṣe dáradára ní fífi àwọn èso tẹ̀mí hàn kedere. (Galatia 5:22, 23) Síbẹ̀ àyíká ipò tí ó yí padà lè mú kí o nílò kíkọ́ púpọ̀ síi nípa àwọn ànímọ́ Ọlọrun. (Fiwé Heberu 5:8.) Alábòójútó arìnrìn-àjò tẹ́lẹ̀rí kan tí ó ríi pé ó pọndandan láti fi iṣẹ́-ìsìn àkànṣe rẹ̀ sílẹ̀ láti lè bójútó àwọn òbí rẹ̀ tí ó ti darúgbó sọ pé: “Tẹ́lẹ̀ mo lérò pé mo ń hùwà lọ́nà tí ó lọ́gbọ́n nínú gan-an ní fífi àwọn èso tẹ̀mí hàn. Ní báyìí mo nímọ̀lára bí ẹni pé mo tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ̀rẹ̀ ni.” Bákan náà, àwọn ọkọ àti aya tí ẹnìkejì wọn nínú ìgbéyàwó ti jìyà àìlera nípa ti ara tàbí ti èrò ìmọ̀lára lílekoko lè ríi pé nínú pípèsè ìtọ́jú tí ara-ẹni, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan másùnmáwo máa ń yọrí sí ìhùwàpadà tí ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn. Kíka Bibeli déédéé jẹ́ orísun ìtùnú ńlá àti ìrànlọ́wọ́.

Nígbà Tí A Lè Ka Bibeli

9. (a) Kí ni ó lè ṣèrànwọ́ fún ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ dí púpọ̀ láti rí àyè fún Bibeli kíkà ojoojúmọ́? (b) Èéṣe tí kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fi ṣe pàtàkì pàápàá fún àwọn alàgbà?

9 Ní tòótọ́, fún àwọn tí ọwọ́ wọn dí púpọ̀, wíwá àyè láti ṣe ohun kan ní àfikún lọ́nà tí ó ṣe déédéé jẹ́ ìpèníjà kan. Bí ó ti wù kí ó rí, a lè jàǹfààní láti ara àpẹẹrẹ Jehofa. Bibeli ṣí i payá pé ó ń ṣe nǹkan ní ‘àkókò tí a yàn kalẹ̀’ (Genesisi 21:2; Eksodu 9:5; Luku 21:24; Galatia 4:4) Ìmọrírì fún ìjẹ́pàtàkì kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun déédéé lè ràn wá lọ́wọ́ láti yan àkókò kan fún-un nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ wa ojoojúmọ́. (Efesu 5:15-17) Àwọn alàgbà ní pàtàkì níláti yan àkókò fún kíka Bibeli déédéé kí ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fúnni lè jẹ́ èyí tí a gbékarí àwọn ìlànà Bibeli láìsí iyèméjì, kí ẹ̀mí tí wọn yóò fi hàn sì lè fi “ọgbọ́n tí ó wá lati òkè” hàn.—Jakọbu 3:17; Titu 1:9.

10. Nígbà wo ni àwọn tí wọ́n ń ka Bibeli lójoojúmọ́ ń rí àyè láti kà á?

10 Ọ̀pọ̀ tí ó ṣàṣeyọrí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ kíka Bibeli ara-ẹni ń ka tiwọn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò ọjọ́ náà. Àwọn mìíràn ríi pé ó ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe é dáradára láìtàsé ní àkókò mìíràn. Bibeli tí a ti kà sínú kásẹ́ẹ̀tì (níbi tí ó bá ti wà) ń ran àwọn awakọ̀ lọ́wọ́ láti lo àkókò ìrìn-àjò wọn dáradára, àwọn Ẹlẹ́rìí kan sì máa ń tẹ́tísílẹ̀ sí wọn nígbà tí wọ́n bá ń bójútó àwọn iṣẹ́ àtìgbàdégbà nínú ilé. Àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ó ti ṣiṣẹ́ fún oríṣiríṣi àwọn Ẹlẹ́rìí ní Europe, Africa, North America, South America, àti ní Ìlà-Oòrùn ni a fi hàn ní ojú-ìwé 20 àti 21, nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kà Á àti Bí Wọ́n Ṣe Ń Jàǹfààní.”

11. Báwo ni a ṣe lè ṣàṣeyọrí nínú kíka Bibeli lójoojúmọ́ bí àkókò tí ó wà kò bá tilẹ̀ pọ̀ rárá?

11 Ohun tí ó ṣe pàtàkì kì í ṣe iye àkókò tí o yàsọ́tọ̀ fún kíka Bibeli lẹ́ẹ̀kan ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe déédéé tó. O lè ríi pé ó ṣàǹfààní láti kà á fún wákàtí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan, kí o máa ṣe àfikún ìwádìí kí o sì di ẹni tí ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà gbà lọ́kàn gan-an. Ṣùgbọ́n ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ ha fàyègba èyí ní gbogbo ìgbà bí? Dípò jíjẹ́ kí ọ̀pọ̀ ọjọ́ lọ láì ka Bibeli rárá, kò ha ní dára láti kà á fún ìṣẹ́jú 15 tàbí ìṣẹ́jú 5 lójoojúmọ́ pàápàá bí? Fi í ṣe ìpinnu rẹ láti ka Bibeli lójoojúmọ́. Lẹ́yìn náà ṣe ìwádìí tí ó jinlẹ̀ ní àfikún nígbà tí ó bá ṣeé ṣe.

Àwọn Ọ̀nà Yíyàtọ̀síra Láti Gbà Ka Bibeli

12. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bibeli kíkà wo ni àwọn mẹ́ḿbà ìdílé Beteli titun àti àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ Gileadi ní?

12 Oríṣiríṣi ọ̀nà ni ó wà tí a fi lè ka Bibeli. Ó ṣàǹfààní láti kà á láti Genesisi sí Ìṣípayá. Gbogbo mẹ́ḿbà ìdílé Beteli kárí ilẹ̀ ayé tí ń ṣiṣẹ́sìn ní orílé-iṣẹ́ àgbáyé tàbí ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka Society ni a retí kí wọ́n ka gbogbo odindi Bibeli láàárín ọdún àkọ́kọ́ iṣẹ́-ìsìn wọn ní Beteli. (Èyí ní ọ̀pọ̀ ìgbà ń ní nínú kíka orí mẹ́ta sí márùn ún, ó sinmi lé bí wọ́n bá ti gùn tó, tàbí ojú-ìwé mẹ́rin sí márùn ún, lójúmọ́.) Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Watchtower Bible School of Gilead pẹ̀lú gbọ́dọ̀ ka Bibeli láti páálí dé páálí kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́yege. A retí pé èyí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jẹ́ kí wọ́n sọ Bibeli kíkà lójoojúmọ́ di apákan ìgbésí-ayé wọn.

13. Góńgó wo ni a dámọ̀ràn fún àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìrìbọmi?

13 Ó ṣàǹfààní fún àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi láti fi góńgó kíka gbogbo odindi Bibeli sí iwájú wọn. Ní 1975, nígbà tí ó ń múrasílẹ̀ fún ìrìbọmi, alàgbà kan béèrè lọ́wọ́ ọ̀dọ́mọkùnrin kan ní France bóyá ó ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ pàtó kan fún Bibeli kíkà. Láti ìgbà náà wá ó ti ń ka gbogbo odindi Bibeli lọ́dọọdún, ó sábà máa ń kà á ní òwúrọ̀ ṣáájú kí ó tó lọ sí ibi iṣẹ́. Nípa ohun tí ó yọrí sí, ó sọ pé: “Mo ti túbọ̀ di ojúlùmọ̀ Jehofa síi. Mo ń rí bí gbogbo ohun tí ó ń ṣe ṣe níí ṣe pẹ̀lú ète rẹ̀ àti bí ó ṣe ń dáhùnpadà nígbà tí ohun ìdènà bá dìde. Bákan náà, mo ríi pé, Jehofa jẹ́, olódodo ó sì dára nínú gbogbo ìṣe rẹ̀.”

14. (a) Kí ó ba lè ṣeé ṣe láti bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bibeli kíkà ara-ẹni tí yóò máa bá a lọ, kí ni ó di dandan? (b) Kí ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti rántí àwọn kókó pàtàkì tí ìwé Bibeli kọ̀ọ̀kan ní nínú bí a ti ń kà á?

14 O ha ti ka gbogbo odindi Bibeli bí? Bí bẹ́ẹ̀kọ́, ìsinsìnyí ni àkókò tí ó dára jù láti bẹ̀rẹ̀. Gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ó ṣe gúnmọ́ kalẹ̀, kí o sì tẹ̀lé e. Pinnu iye ojú-ìwé tàbí iye orí tí ìwọ yóò máa kà lójoojúmọ́, tàbí kí o wulẹ̀ pinnu iye àkókò àti ìgbà tí ìwọ yóò máa lò. Kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni yóò parí Bibeli kíkà ní ọdún kan, ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣe pàtàkì ni láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun déédéé, kí o máa ṣe bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́ bí ó bá ṣeé ṣe. Bí o ti ń ka Bibeli lọ, ìwọ yóò ri ìwúlò lílo àwọn ìwé atọ́ka kan ní títẹ àwọn kókó pàtàkì àkójọpọ̀-ọ̀rọ̀ náà mọ́ ọ lọ́kàn. Bí ìwé Insight on the Scriptures bá wà ní èdè rẹ, nígbà náà ṣáájú kí o tó bẹ̀rẹ̀ sí ka ìwé Bibeli kan pàtó, ṣàyẹ̀wò kókó pàtàkì tí a tẹnumọ́ ní ṣókí bí a ṣe pèsè rẹ̀ nínú Insight.* Ṣàkíyèsí ní pàtàkì àkòrí tí a kọ gàdàgbà gàdàgbà nínú ìlapa-èrò náà. Tàbí kí o lo àkójọpọ̀ tí a ṣe lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ tí a pèsè sínú ìwé náà “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial.”a

15. (a) Ìdámọ̀ràn wo tí ó wà ní ojú ìwé 16 àti 17 ni ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú Bibeli kíkà rẹ dára síi? (b) Dípò sísọ kíka iye ojú ìwé pàtó di elétò-àṣà, ohun tí ó ṣe pàtàkì wo ní a gbọ́dọ̀ fún ní àfiyèsí tí ó ga?

15 Kíka Bibeli lẹ́sẹẹsẹ ṣàǹfààní, ṣùgbọ́n máṣe wulẹ̀ di òǹkàwé elétò-àṣà. Máṣe ka ojú-ìwé kan pàtó lójoojúmọ́ kìkì láti lè sọ pé ìwọ́ ń ka Bibeli tán lọ́dọọdún. Gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn nínú àpótí “Àwọn Àbá Láti Mú Bibeli Kíkà Rẹ Dára Síi” (ojú-ìwé 16 àti 17), oríṣiríṣi ọ̀nà ni ó wà tí ìwọ fi lè ka Bibeli kí o sì gbádùn rẹ̀. Láìka ọ̀nà tí ìwọ́ gbà sí, ríi dájú pé o ń bọ́ èrò-inú àti ọkàn-àyà rẹ.

Lóye Ohun Tí Ìwọ Ń Kà

16. Èéṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti fi àyè sílẹ̀ láti ṣàṣàrò lórí ohun tí a kà?

16 Nígbà tí ó ń kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Jesu tẹnumọ́ ìjẹ́pàtàkì lílóye ohun tí òun sọ. Ohun tí ó ṣe pàtàkì, kì í wulẹ̀ ṣe ìfinúmòye ti èrò-orí, ṣùgbọ́n kí ‘òye rẹ̀ yé wọn ninu ọkàn-àyà wọn’ kí wọ́n baà lè lò ó nínú ìgbésí-ayé wọn. (Matteu 13:14, 15, 19, 23) Ohun tí ó jà lọ́dọ̀ Ọlọrun ni ohun tí ẹnì kan jẹ́ nínú lọ́hùn ún níti tòótọ́, èyí sì ni ohun tí ọkàn-àyà ń ṣojú fún. (1 Samueli 16:7; Owe 4:23) Nípa báyìí, ní àfikún sí rírí i dájú pé a lóye ohun tí àwọn àyọkà-ọ̀rọ̀ Bibeli ń sọ, a níláti ṣàṣàrò lórí wọn, kí a sì ṣàgbéyẹ̀wò ipa tí wọ́n ní lórí ìgbésí-ayé tiwa.—Orin Dafidi 48:9; 1 Timoteu 4:15.

17. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ojú ìwòye tí ó ṣe pàtó tí a lè gbé àṣàrò lórí ohun tí a ń kà nínú Ìwé Mímọ́ kà?

17 Sakun láti dá àwọn ìlànà ìpìlẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ Bibeli mọ̀ yàtọ̀ kí o baà lè lò wọ́n nínú ipò-ọ̀ràn tí ó bá dojúkọ ọ́. (Fiwé Matteu 9:13; 19:3-6.) Bí o ti ń kà nípa àwọn àgbàyanu ànímọ́ Jehofa tí o sì ń ṣàṣàrò nípa wọn, lo àǹfààní yẹn láti fún ipò-ìbátan ara-ẹni rẹ pẹ̀lú rẹ̀ lókun síi, kí o mú òye lílágbára ti ìfọkànsìn Ọlọrun dàgbà nínú ara rẹ. Nígbà tí o bá ka àwọn àkọsílẹ̀ nípa ète Jehofa, ṣàkíyèsí ohun tí ìwọ́ lè ṣe láti ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìwọ̀nyí. Nígbà tí o bá ka ìmọ̀ràn ní tààràtà, dípò wíwulẹ̀ sọ fún ara rẹ pé, ‘Mo mọ ìyẹn,’ béèrè pé, ‘Mo ha ń ṣe ohun tí ó sọ bí?’ Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, bi ara rẹ léèrè pé, ‘Ní àwọn ọ̀nà wo ni mo fi lè ṣe é “lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ síi”?’ (1 Tessalonika 4:1) Bí o ti ń kọ́ nípa àwọn ohun tí Ọlọrun béèrè fún, tún ṣàkíyèsí àwọn àpẹẹrẹ tí ó ṣẹlẹ̀ níti gidi tí ó wà nínú Bibeli nípa àwọn wọnnì tí wọ́n ti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí a béèrè fún yìí àti àwọn wọnnì tí kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ronú nípa ìdí tí wọ́n fi tẹ̀lé ipa-ọ̀nà tí wọ́n tẹ̀lé àti ohun tí àbájáde rẹ̀ jẹ́. (Romu 15:4; 1 Korinti 10:11) Nígbà tí o bá ń kà nípa ìgbésí-ayé Jesu Kristi, rántí pé Jesu ni ẹni náà tí Jehofa ti fi ipò-ọba lórí gbogbo ilẹ̀-ayé lé lọ́wọ́; lo àǹfààní náà láti mú ìfẹ́ fún ayé titun Ọlọrun nínú ara rẹ lágbára síi. Bákan náà, ṣàyẹ̀wò ní kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ọ̀nà tí o fi lè túbọ̀ ṣàfarawé Ọmọkùnrin Ọlọrun lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ síi.—1 Peteru 2:21.

18. Báwo ni a ṣe lè mú kí Bibeli kíkà wa wàdéédéé pẹ̀lú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” náà ń pèsè?

18 Àmọ́ ṣáá o, Bibeli kíkà kò gbọdọ̀ rọ́pò lílo àwọn ohun èlò tí ó gbámúṣé tí a ti pèsè láti ọwọ́ “olùṣòtítọ́ ati ọlọgbọ́n-inú ẹrú.” Ìyẹn pẹ̀lú jẹ́ apákan ìpèsè Jehofa—ọ̀kan tí ó ṣeyebíye gan-an. (Matteu 24:45-47) Ríi dájú pé kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun déédéé ní ipò tí ó ṣe pàtàkì nínú ìgbésí-ayé rẹ. Bí ó bá ṣeé ṣe, “MÁA KA BIBELI MÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌRUN LÓJOOJÚMỌ́.”

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Èéṣe tí ó fi ṣàǹfààní láti ka Bibeli lójoojúmọ́?

◻ Èéṣe tí a fi níláti ka Bibeli lákàtúnkà?

◻ Nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tìrẹ, ìgbà wo ni ó dára láti ka Bibeli lójoojúmọ́?

◻ Bí o ti ń ka Bibeli lákàtúnkà, kí ni ó lè fi ọ̀kankòjọ̀kan kún ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ?

◻ Èéṣe tí ó fi ṣe pàtàkì púpọ̀ láti ṣàṣàrò lórí ohun tí a kà?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Àwọn àbá láti mú Bibeli kíkà rẹ dára síi

(1) Púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ń ka àwọn ìwé Bibeli ní ìtòtẹ̀léra bí a ṣe kọ wọ́n, láti Genesisi sí Ìṣípayá. Ìwọ náà lè kà wọ́n ní ìtòtẹ̀léra bí a ṣe kọ wọ́n ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Rántí pé Bibeli jẹ́ àkójọpọ̀ ìwé 66 tí a mí sí, àkójọpọ̀ ìwé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Fún ọ̀kankòjọ̀kan, o lè fẹ́ láti ka àwọn ìwé tí ó sọ̀rọ̀ nípa ìtàn, lẹ́yìn náà àwọn tí ọ̀rọ̀ wọn jẹ́ kìkì àsọtẹ́lẹ̀, kí o sì ka àwọn tí wọ́n jẹ́ lẹ́tà ìmọ̀ràn tẹ̀lé e, dípò wíwulẹ̀ tẹ̀lé ètò ojú-ìwé. Fi ohun tí o kà sọ́kàn, kí o sì rí i dájú pé o ka gbogbo odindi Bibeli.

(2) Lẹ́yìn kíka apákan nínú Ìwé Mímọ́, bi ara rẹ léèrè ohun tí ó fi hàn nípa Jehofa, ète rẹ̀, ọ̀nà ìgbà-ṣe-nǹkan rẹ̀; bí ó ṣe níláti nípa lórí ìgbésí-ayé rẹ; bí o ṣe lè lò ó láti ran ẹlòmíràn lọ́wọ́.

(3) Ní lílo àwòrán ìsọfúnni náà “Main Events of Jesus’ Earthly Life” (Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Aye Jesu) tí a tẹ̀ jáde lábẹ́ orí-ọ̀rọ̀ náà “Jesus Christ” (Jesu Kristi) nínú Insight on the Scriptures (bákan náà nínú “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial”) gẹ́gẹ́ bí ìtọ́sọ́nà, ka àwọn àkọsílẹ̀ tí ó ṣe déédéé pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn nínú àwọn ìwé Ìròyìnrere, níkọ̀ọ̀kan. Ṣe àfikún èyí nípa ṣíṣe ìwádìí láti inú ẹ̀ka-ìpín tí ó ṣe wẹ́kú nínú ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí.

(4) Nígbà tí o bá ka àkọsílẹ̀ nípa ìgbésí-ayé àti iṣẹ́-òjíṣẹ́ Paulu nínú Ìṣe Awọn Aposteli, tún ka àwọn lẹ́tà tí ó farajọ ọ́ tí a mí sí. Nípa báyìí, nígbà tí a bá mẹ́nukan oríṣiríṣi àwọn ìlú-ńlá àti àdúgbò tí Paulu ti wàásù, séraró kí o sì ka àwọn lẹ́tà tí ó kọ lẹ́yìn náà sí àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní àwọn ibi wọ̀nyẹn. Ó tún máa ń ṣèrànwọ́ láti tẹ̀lé àwọn ìrìn-àjò rẹ̀ ní orí àwòrán-ilẹ̀, irú èyí tí ó wà ní ẹ̀yìn Bibeli Ìtumọ̀ Ayé Titun.

(5) Ní àfikún sí kíka ìwé Eksodu sí Deuteronomi, ka lẹ́tà sí àwọn Heberu láti lè rí àlàyé púpọ̀ nínú àwọn ìlàlẹ́sẹẹsẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà. Lábẹ́ “Law” (Òfin) nínú ìwé Insight on the Scriptures, wo àwòrán ìsọfúnni náà “Some Features of the Law Covenant” (Apá Pàtàkì Díẹ̀ Nínú Májẹ̀mú Òfin).

(6) Nígbà tí o bá ń ka àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀, wá àyè láti ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìtàn ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí ó farajọ ọ́ nínú Bibeli. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí o bá ń ka ìwé Isaiah, ṣàtúnyẹ̀wò ohun tí a sọ níbòmíràn nípa ọba Ussiah, Jotamu, Ahasi, àti Hesekiah, tí a mẹ́nukàn nínú Isaiah 1:1. (2 Ọba, orí 15 sí 20; 2 Kronika, orí 26 sí 32) Tàbí nígbà tí o bá ń ka ìwé Haggai àti Sekariah, farabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tí ó wà nínú ìwé Esra.

(7) Yan ìwé kan nínú Bibeli, ka apákan rẹ̀ (bóyá orí kan), lẹ́yìn náà ṣe ìwádìí, nípa lílo ìwé Watch Tower Publications Index tàbí Watchtower Library tí a ṣe sínú ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà tí ó bá wà ní èdè tìrẹ. Lo àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà nínú ìgbésí-ayé rẹ. Lò ó nínú ọ̀rọ̀-àsọyé àti nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá. Lẹ́yìn náà ka ẹ̀ka-ìpín tí ó tẹ̀lé e.

(8) Bí ìtẹ̀jáde Watch Tower tí ó pèsè àlàyé-ọ̀rọ̀ lórí ìwé Bibeli kan tàbí apákan rẹ̀ bá wà, máa ṣèwádìí nínú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà bí o tí ń ka apá yẹn nínú Bibeli. (Fún àpẹẹrẹ: lórí Orin Solomoni, Ilé-Ìṣọ́nà, December 1958, ojú-ìwé 357 sí 368; lórí ìwé Esekieli, “The Nations Shall Know That I Am Jehovah”—How?; lórí ìwé Danieli, “Ifẹ Tirẹ Ni Ki A Ṣe Li Aiye” tàbí Our Incoming World Government—God’s Kingdom; lórí ìwé Haggai àti Sekariah, Paradise Restored to Mankind—By Theocracy!; lórí ìwé Ìṣípayá, Revelation—Its Grand Climax At Hand!)

(9) Bí o ti ń kà á, wo àwọn ìtọ́kasí tí a ṣe síwájú. Ṣàkíyèsí àwọn àyọkà 320 láti inú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu tí a fàyọ tààràtà nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki àti ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn àyọkà mìíràn tí a tọ́kasí, àti àwọn ìtumọ̀ tí a fifúnni. Àwọn ìtọ́kasí onísokọ́ra fi ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí a kọ sínú Bibeli hàn, àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìtàn ìgbésí-ayé àti àwòrán ojú-ilẹ̀, àti àwọn èrò tí ó jọra tí ó lè fi àwọn ìsọfúnni tí ó ti ṣe é ṣe kí ó ṣòro fún ọ láti lóye hàn ní kedere.

(10) Ní lílo Ẹ̀dà-Ìtẹ̀jáde Tí Ó Ní Atọ́ka ti New World Translation, bí ó bá wà ní èdè rẹ, ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ ẹsẹ̀-ìwé àti àsomọ́ ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí o tan mọ́ ohun tí o ń kà. Àwọn wọ̀nyí fi ìpìlẹ̀ hàn fún lílò tí a lò ó bẹ́ẹ̀ àti àwọn ọ̀nà mìíràn tí a fi lè túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe pàtàkì. O tún lè fẹ́ láti fi bí a ṣe lo àwọn ẹsẹ̀ kan nínú àwọn ìtumọ̀ Bibeli mìíràn wéra.

(11) Lẹ́yìn tí o bá ti ka orí kọ̀ọ̀kan, kọ àkọsílẹ̀ kúkúrú lórí kókó pàtàkì nínú orí náà. Lò ó gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún àtúnyẹ̀wò àti àṣàrò nígbà mìíràn.

(12) Bí o ti ń ka Bibeli, fi àmì sí ẹsẹ̀-ìwé tí o ṣàyàn tí o fẹ́ láti rántí ní pàtàkì, tàbí kí o dà wọ́n kọ sínú káàdì kí o sì fi wọ́n sí ibi tí o ti lè rí wọn ní ojoojúmọ́. Kọ́ wọn sórí; ṣàṣàrò lé wọn lórí; kí o sì lò wọ́n. Máṣe gbìyànjú láti kọ́ èyí tí ó pọ̀ jù sórí lẹ́ẹ̀kan náà, bóyá ọ̀kan tàbí méjì lọ́sẹ̀; lẹ́yìn náà kí o yan púpọ̀ síi nígbà mìíràn tí o bá tún ka Bibeli.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

O ha ń ka Bibeli tàbí tẹ́tísílẹ̀ lójoojúmọ́ sí èyí tí a gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀ bí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́