ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 5/15 ojú ìwé 4-6
  • Bibeli—Ìwé kan tí A Níláti Kà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bibeli—Ìwé kan tí A Níláti Kà
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Abájọ tí Ó Fi Wàpẹ́títí!
  • Àṣà Bibeli Kíkà
  • Máa Kà Á Déédéé
  • Jíjàǹfààní Láti Inú Bibeli Kíkà Lójoojúmọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Bíbélì Kíkà—Ó Lérè, Ó Sì Gbádùn Mọ́ni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ní Inú Dídùn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Fi Ara Rẹ fún Ìwé Kíkà
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 5/15 ojú ìwé 4-6

Bibeli​—⁠Ìwé kan tí A Níláti Kà

ÓRỌRÙN láti wá ọ̀rọ̀ àpọ́nlé gíga jùlọ tì nígbà tí ẹnìkan bá ń sọ̀rọ̀ nípa Bibeli. Ní gbogbo ọ̀nà òun ni ìwé tí ìpínkiri rẹ̀ pọ̀ jùlọ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ ìtàn. Bibeli ni ó lọ́jọ́lórí jùlọ, òun ni a túmọ̀ jùlọ, òun ni a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ jùlọ, òun ni ó ní agbára ìdarí tí ó pọ̀ jùlọ, òun sì ni ìwé tí a bọ̀wọ̀ fún jùlọ. Bóyá òun náà sì tún ni ó jẹ́ okùnfà àríyànjiyàn jùlọ. Ó sì dájú pé òun ni ìwé tí ó ti la ìfòfindè, ìfijóná, àti àtakò gbígbóná janjan jùlọ já. Bí ó ti wù kí ó rí, lọ́nà tí kò múniláyọ̀, ọ̀rọ̀ àpọ́nlé gíga jùlọ kan wà tí a kò lè lò fún Bibeli mọ́. Kò dàbí ẹni pé òun ni ìwé tí a ń kà níbi tí ó pọ̀ jùlọ lágbàáyé mọ́.

Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ènìyàn lè ní Bibeli níbìkan nínú ilé wọn, ọ̀pọ̀ nímọ̀lára pé ọwọ́ wọn ti dí jù láti wá àkókò fún kíkà á níti gidi. Nígbà kan rí ni ìwé kíkà ti jẹ́ eré ọwọ́dilẹ̀ tí ó gbajúmọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, nísinsìnyí, ọ̀pọ̀ yàn láti lo àkókò tí ọwọ́ wọ́n bá dilẹ̀ fún wíwo tẹlifíṣọ̀n tàbí ṣíṣe àwọn nǹkan mìíràn. Àwọn tí wọ́n ṣì ń kàwé díẹ̀ sábà máa ń fẹ́ ohun kan tí kò gba ìsapá púpọ̀ tí ó sì rọrùn. Kíka Bibeli ń béèrè fún ìpọkànpọ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn kò sì pọkànpọ̀ lọ́nà jíjinlẹ̀ sórí ohun tí wọ́n ń kà mọ́.

Síbẹ̀, Bibeli kò làájá kìkì kí a baà lè fi sórí pẹpẹ ìkówèésí wa lásán. Àwọn ìdí rere wà tí a fi níláti kà á. Gbé àwọn òtítọ́ díẹ̀ nípa rẹ̀ yẹ̀wò.

Abájọ tí Ó Fi Wàpẹ́títí!

Èdè náà “Bibeli” wá láti inú ọ̀rọ̀ Griki náà bi·bliʹa, tí ó túmọ̀sí “àwọn ìwé kéékèèké.” Èyí rán wa létí pé iye àwọn ìwé mélòókan ni wọ́n parapọ̀ di Bibeli​—⁠àwọn kan kò fi bẹ́ẹ̀ kéré! A kọ wọ́n ní èyí tí ó ju ọgọ́rùn-⁠ún ọdún mẹ́rìndínlógún lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òǹkọ̀wé rẹ̀ jẹ́ ènìyàn, wọ́n ní ìmísí láti ọ̀dọ̀ Orísun gíga jù kan. Òǹkọ̀wé Bibeli kan sọ pé: “Àsọtẹ́lẹ̀ kan kò ti ipa ìfẹ́ ènìyàn wá rí; ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun bí a ti ń darí wọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá.” (2 Peteru 1:21) Ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ nípa àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ tún jẹ́ òtítọ́ nípa apá yòókù nínú Bibeli. “Àwọn ìwé kéékèèké” tí wọ́n ní ìmísí àtọ̀runwá náà kún fún àwọn èrò gíga fíofío ti Jehofa Ọlọrun. (Isaiah 55:⁠9) Abájọ tí Bibeli fi wàpẹ́títí fún àkókò gígùn tóbẹ́ẹ̀!

Fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun, Bibeli ti fìgbà gbogbo jẹ́ ìwé tí ó gbapò iwájú jùlọ. Wọ́n fohùnṣọ̀kan pẹ̀lú aposteli Paulu, tí òun fúnraarẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òǹkọ̀wé Bibeli. Ó wí pé: “Gbogbo ìwé-mímọ́ [ni] ó ní ìmísí Ọlọrun [tí] ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́.” (2 Timoteu 3:16) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, Bibeli ni ìpìlẹ̀ fún ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lónìí. Ó ń pinnu ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ wọn ó sì ń ṣàkóso ìwà wọn. Wọ́n fi tọkàntara dámọ̀ràn pé kí olúkúlùkù ka àwọn apákan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun lójoojúmọ́ kí wọ́n sì fi pẹ̀lú ìmọrírì ṣe àṣàrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀.​—⁠Orin Dafidi 1:​1-⁠3.

Àṣà Bibeli Kíkà

Àṣà kíka Ìwé Mímọ́ ti ṣàǹfààní ní àwọn àkókò tí ó ti kọjá. Àwọn ọba Israeli ni a pàṣẹ fún láti ṣe ẹ̀dà àfọwọ́kọ tiwọn nínú Òfin​—⁠tí ó jẹ́ apá pàtàkì kan nínú Bibeli nísinsìnyí​—⁠kí wọ́n sì máa kà á lójoojúmọ́ kí ó lè máa rán wọn létí ìfẹ́-inú Ọlọrun fún wọn lemọ́lemọ́. (Deuteronomi 17:​18-⁠20) Ìkùnà láti ṣe èyí ṣokùnfà ìṣubú ọ̀pọ̀ àwọn ọba.

Ìníyelórí kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ ni a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú ọ̀ràn ti wòlíì Danieli tí ó ti darúgbó. Nítorí dídákẹ́kọ̀ọ́ àwọn apá Bibeli tí ó wà ní ọjọ rẹ̀, ó ṣeéṣe fún Danieli, nígbà tí ó ṣì wà ní ìgbèkùn ní Babiloni, láti “fiyèsi láti inú ìwé” pé àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì kan tí Jeremiah kọ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ní ìmúṣẹ.​—⁠Danieli 9:⁠2.

Nígbà ìbí Jesu, Simeoni ọkùnrin “olóòótọ́ àti olùfọkànsìn” náà ń fi pẹ̀lú ìdánilójú retí láti rí ẹni náà tí yóò di Kristi, tàbí Messia. A ti ṣèlérí fún Simeoni pé òun kì yóò kú ṣáájú kí ó tó rí Kristi. Sísọ tí ó sọ̀rọ̀bá àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah nígbà tí ó gbé ọmọ-ọwọ́ náà Jesu lọ́wọ́ fihàn pé Simeoni jẹ́ olùfiyèsílẹ̀ òǹkàwé àwọn ìwé Bibeli tí a ti kọ ní ọjọ́ rẹ̀.​—⁠Luku 2:​25-⁠32; Isaiah 42:⁠6.

Nígbà tí Johannu Arinibọmi ń wàásù, ‘àwọn ènìyàn ti ń retí’ Messia. Kí ni èyí fihàn? Ó dọ́gbọ́n túmọ̀sí pé ọ̀pọ̀ lára àwọn Ju mọ àwọn asọtẹ́lẹ̀ Messia tí a kọsílẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ dunjú. (Luku 3:15) Èyí wuni láti gbọ́, nítorí pé ní àwọn ọjọ́ wọnnì ìwé ṣọ̀wọ́n jọjọ. Ẹ̀dà àwọn ìwé Bibeli ni a níláti fi ọwọ́ dàkọ tìṣọ́ratìṣọ́ra, wọ́n gbówólórí bákan náà ni wọ́n sì ṣòro láti rí. Báwo ni àwọn ènìyàn ṣe mọ àwọn ọ̀rọ̀ inú wọn dunjú?

Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀ràn, ó jẹ́ nípa ìwé kíkà ní gbangba. Fún àpẹẹrẹ, Mose pàṣẹ pé ní àwọn àkókò kan pàtó, gbogbo Òfin tí Ọlọrun fi fúnni ni a níláti kà fún àwọn ọmọ Israeli tí wọ́n péjọpọ̀. (Deuteronomi 31:​10-13) Ní ọ̀rúndún kìn-⁠ín-⁠ní C.E., kíka àwọn ìwé Bibeli ní gbangba tànkálẹ̀. Ọmọlẹ́yìn náà Jakọbu sọ̀rọ̀ àkíyèsí pé: “Mose nígbà àtijọ́ sáà ní àwọn tí ń wàásù rẹ̀ ní ìlú gbogbo, a máa kà á nínú sínágọ́gù ní ọjọọjọ́ ìsinmi.”​—⁠Iṣe 15:⁠21.

Lónìí, ó rọrùn láti ní ẹ̀dà Bibeli ti ara-ẹni. Ó kérétán díẹ̀ nínú “àwọn ìwé kéékèèké” wọ̀nyí wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní èdè ìpín 98 nínú ọgọ́rùn-⁠ún àwọn ènìyàn tí ń gbé nínú ayé. Èyí ni a fi ń sọ pé ọ̀pọ̀ kò lọ́kàn-ìfẹ́ nínú wíwádìí ohun tí Bibeli ní láti sọ fún wọn. Èyí lè jẹ́ sànmánì ìmọ̀-ìjìnlẹ̀, síbẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli, ṣì “ní èrè fún ẹ̀kọ́” lọ́nà títayọlọ́lá. Ó fúnni ní ìmọ̀ràn tí ó gbéṣẹ́ lórí ìwàhíhù, àjọṣepọ̀ ẹ̀dá ènìyàn, àti àwọn kókó ẹ̀kọ́ mìíràn. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Bibeli nìkan ni ó nawọ́ ìrètí dídájú kanṣoṣo fún ọjọ́-ọ̀la alálàáfíà síni.

Máa Kà Á Déédéé

Nítorí náà àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti fi ṣe apá pàtàkì jùlọ nínú iṣẹ́ wọn láti fún kíka Bibeli déédéé ní ìṣírí. Lára ògiri ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ wọn ní orílé-iṣẹ́ ní Brooklyn, New York, ni ọ̀rọ̀ ìyànjú náà ti farahàn pẹ̀lú lẹ́tà gàdàgbàgàdàgbà pé: “KA Ọ̀RỌ̀ ỌLỌRUN BIBELI MÍMỌ́ LÓJOOJÚMỌ́.” Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tí ń kọjá ti rí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, a sì nírètí pé ọ̀pọ̀ ti kọbiara sí wọn.

Nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ó ju 73,000 lọ jákèjádò àgbáyé, ọ̀wọ́ àwọn Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun ni a ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Apákan ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ náà ni kíka apá kan tí a yàn láti inú Bibeli ní gbangba. Gbogbo àwọn tí ó pésẹ̀ tún ní iṣẹ́ àyànfúnni láti ka àwọn orí díẹ̀ nínú Bibeli lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní kọ́lọ́fín inú ilé tiwọn fúnraawọn. Àwọn wọnnì tí wọ́n ń tẹ̀lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí máa ń ka gbogbo Bibeli tán ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀.

Ìṣètò yìí wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ń lò nínú ilé-ẹ̀kọ́ yìí. Iwe-Amọna Ile Ẹkọ Iṣẹ Ojiṣẹ Ijọba Ọlọrun sọ pé: “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ fúnraàrẹ níláti fi àkókò fún kíka Bibeli fúnraarẹ̀ kún un. Àǹfààní ńláǹlà ni ó wà nínú rẹ̀ láti kà á jálẹ̀ láti ojú ìwé kan dé èkejì. . . . Ṣùgbọ́n góńgó rẹ tí o ń lépa nínú ìwé kíkà kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kìkì kíka ìwé jọ bẹẹrẹbẹ, ṣùgbọ́n láti ní ojú ìwòye rẹ̀ láti òkè délẹ̀ pẹ̀lú ète láti rántí. Lo àkókò láti fi ṣàkíyèsí kí o sì ronú lórí ohun tí ó wí.”

Àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe bákan náà tún pèsè ìṣírí fún kíka Bibeli. Fún àpẹẹrẹ, nínú ìwé-ìròyìn tí ó sìkejì àkànṣe ìwé ìròyìn yìí, Jí!, ni ìṣírí tí ó tẹ̀lé e yìí ti farahàn fún àwọn ọ̀dọ́: “Iwọ ha ti ka . . . gbogbo Bibeli jálẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ni, Bibeli jẹ́ ìwé títóbi kan, ṣùgbọ́n èéṣe tí o kò fi pín kíkà rẹ̀ sí apá ìpín kéékèèké? . . . Àwọn ará Beroa tí wọ́n ‘ṣọmọlúwàbí’ ‘ń yẹ àwọn Ìwé Mímọ́ wò lójoojúmọ́.’ (Iṣe 17:11, NW) Bí ìwọ bá tẹ̀lé ìwéwèé ojoojúmọ́ ti kíkàwé ní ìṣẹ́jú 15 péré lóòjọ́ . . . , ìwọ lè parí kíka Bibeli láàárín ọdún kan.” Bẹ́ẹ̀ni, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nímọ̀lára pé àwọn Kristian òde-ìwòyí níláti mọ Ìwé Mímọ́ dunjú, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ti ṣe ní ìgbà àtijọ́.

Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, àwọn Ẹlẹ́rìí ti ṣe ìgbégasíwájú Bibeli kíkà ní gbangba tí ó jẹ́ ti ọ̀rúndún ogún. Ní àwọn èdè mélòókan, wọ́n ti gba ohùn àwọn ìwé kíkà tí ó kárí odidi Bibeli sílẹ̀ sórí kásẹ́ẹ̀tì. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, èyí ti jásí ìrànlọ́wọ́ dídára nínú bíborí àwọn ìdènà fún Bibeli kíkà. Àwọn kan ń fetísílẹ̀ sí ohùn tí a gbàsílẹ̀ yìí nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ láyìíká ilé, ń wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn, tàbí ń ṣe àwọn nǹkan mìíràn. Láti jókòó kí o sì fetísílẹ̀ jẹ́jẹ́ sí kíkà apákan nínú Bibeli nígbà tí o ń fojú báa lọ nínú ẹ̀dà tìrẹ jẹ́ ìrírí tí ń gbádùnmọ́ni.

Bí ìwọ kò bá tíì máa ka Bibeli lójoojúmọ́, èéṣe tí ìwọ kò sọ ọ́ di àṣà rẹ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀? Kò pọndandan kí èyí gba àkókò gígùn ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ṣùgbọ́n àǹfààní náà yóò pọ̀, nítorí pé ìfisílò Ìwé Mímọ́ yóò mú kí ó ṣeéṣe fún ọ láti hùwà ọlọgbọ́n kí o sì gbádùn ìgbésí-ayé tí ń mérè wá nípa tẹ̀mí. Ìwọ yóò sì tún máa hùwà ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ yìí tí a fifún aṣáájú àwọn ọmọ Israeli náà Joṣua ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn pé: “Ìwé òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ ó máa ṣe àṣàrò nínú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè kíyèsí àti ṣe gẹ́gẹ́ bíi gbogbo èyí tí a kọ sínú rẹ̀: nítorí nígbà náà ni ìwọ ó ṣe ọ̀nà rẹ ní rere, nígbà náà ni yóò sì dára fún ọ.”​—⁠Joṣua 1:⁠8.

Àwọn ojú-ìwé Bibeli ṣí ète onífẹ̀ẹ́ ti Jehofa payá fún aráyé onígbọràn. Ìmọ̀ pípéye ti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a mísí ń yọrísí ayọ̀ tòótọ́ àti ìrètí ìyè ayérayé nínú Paradise nínú ayé titun àgbàyanu ti àwọn ìbùkún aláìlópin. (Luku 23:43; 2 Peteru 3:13) Ǹjẹ́ kí ìwọ lo àǹfààní tí ó ṣí sílẹ̀ fún ọ láti kà kí o sì kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kí o sì lépa ìgbésí-ayé àgbàyanu yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́