Fi Ara Rẹ fún Ìwé Kíkà
“Láàárín àkókò tí mo ń bọ̀wá, máa bá a lọ ní fífi aápọn lo ara [rẹ] ninu ìwé kíkà ní gbangba, ninu ìgbaniníyànjú, ninu kíkọ́ni.”—1 TIMOTEU 4:13.
1. Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní láti inú kíka Bibeli?
JEHOFA ỌLỌRUN ti fún aráyé ní agbára àgbàyanu ti kíkọ́ láti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Ó tún ti pèsè Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, kí a baà lè fún wa ní ìtọ́ni lọ́nà tí ó gbéṣẹ́. (Isaiah 30:20, 21) Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àwọn ojú ìwé rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti bá àwọn bàbá olórí ìdílé tí wọ́n jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọrun bí Abrahamu, Isaaki, àti Jakobu “rìn.” A lè “rí” irú àwọn obìnrin oníwà-bí-Ọlọ́run bíi Sara, Rebeka, àti Rutu ará Moabu adúróṣinṣin. Bẹ́ẹ̀ ni, a sì lè “gbọ́” bí Jesu Kristi ṣe ń fúnni ní Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè. Gbogbo ìtọ́ni gbígbádùn mọ́ni, tí ó sì kọyọyọ yìí, láti inú Ìwé Mímọ́, lè jẹ́ tiwa bí a bá jẹ́ òǹkàwé tí ó já fáfá.
2. Kí ni ó fi hàn pé Jesu àti àwọn aposteli rẹ̀ lè kàwé lọ́nà tí ó já gaara?
2 Kò sí iyè méjì pé, ọkùnrin pípé náà, Jesu Kristi, ní agbára ìkàwé tí ó ga lọ́lá, ó sì dájú pé, ó mọ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu dunjú. Nítorí náà, nígbà tí Èṣù dán an wò, léraléra ni Jesu tọ́ka sí wọn, tí ó sì wí pé, “A kọ̀wé rẹ̀ pé.” (Matteu 4:4, 7, 10) Ní àkókò kan nínú sínágọ́gù ní Nasareti, ó kàwé ní gbangba, ó sì fi aápọn lo apá kan nínú àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah fún ara rẹ̀. (Luku 4:16-21) Àwọn aposteli Jesu ńkọ́? Nínú àkọsílẹ̀ wọn, wọ́n sábà máa ń ṣàyọlò Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olùṣàkóso Júù ka Peteru àti Johannu sí òpè àti púrúǹtù nítorí pé wọn kò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga ti àwọn Heberu, àwọn lẹ́tà wọn tí a mí sí látọ̀runwá fi hàn kedere pé, wọ́n mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà dáradára. (Ìṣe 4:13) Ṣùgbọ́n agbára ìkàwé ha ṣe pàtàkì ní tòótọ́ bí?
“Aláyọ̀ Ni Ẹni Naa Tí Ń Ka Awọn Ọ̀rọ̀ . . . Sókè”
3. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti máa ka Ìwé Mímọ́ àti àwọn ìtẹ̀jáde Kristian?
3 Gbígba ìmọ̀ pípéye ti Ìwé Mímọ́ sínú àti fífi í sílò lè yọrí sí ìyè ayérayé. (Johannu 17:3) Nítorí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa rí i pé ó ṣe pàtàkì gidigidi láti máa ka Ìwé Mímọ́ àti àwọn ìtẹ̀jáde Kristian tí Ọlọrun ń pèsè nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọgbọ́n inú ti àwọn Kristian ẹni àmì òróró, kí a sì máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú wọn. (Matteu 24:45-47) Ní tòótọ́, nípa lílo àwọn àkànṣe ìtẹ̀jáde Watch Tower, a ti kọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún láti lè kàwé, wọ́n sì ti tipa bẹ́ẹ̀ gba ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ń fúnni ní ìyè.
4. (a) Èé ṣe tí kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, àti fífi í sílò ṣe lè yọrí sí ayọ̀? (b) Nípa ìwé kíkà, kí ni Paulu sọ fún Timoteu?
4 Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, kíkẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀, àti fífi í sílò máa ń yọrí sí ayọ̀. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé, a ń tipa bẹ́ẹ̀ mú inú Ọlọrun dùn, a ń bọlá fún un, a ń rí ìbùkún rẹ̀ gbà, a sì ń láyọ̀. Jehofa fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláyọ̀. Nítorí náà, ó pàṣẹ fún àwọn àlùfáà láti ka Òfin rẹ̀ sí etígbọ̀ọ́ Israeli ìgbàanì. (Deuteronomi 31:9-12) Nígbà tí Esra adàwékọ àti àwọn mìíràn ka Òfin náà sí etígbọ̀ọ́ àwọn ènìyàn tí ó pé jọ ní Jerusalemu, wọ́n mú ìtumọ̀ rẹ̀ ṣe kedere, ó sì yọrí sí “ayọ̀ ńlá.” (Nehemiah 8:6-8, 12) Lẹ́yìn náà, Kristian aposteli Paulu sọ fún alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ Timoteu pé: “Láàárín àkókò tí mo ń bọ̀wá, máa bá a lọ ní fífi aápọn lo ara rẹ̀ ninu ìwé kíkà ní gbangba, ninu ìgbaniníyànjú, ninu kíkọ́ni.” (1 Timoteu 4:13) Ìtumọ̀ míràn kà pé: “Fi ara rẹ fún kíka Ìwé Mímọ́ ní gbangba.”—New International Version.
5. Báwo ni Ìṣípayá 1:3 ṣe so ayọ̀ pọ̀ mọ́ ìwé kíkà?
5 Ìṣípayá 1:3 mú un ṣe kedere pé, ayọ̀ wa sinmi lórí kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti fífi í sílò. A sọ fún wa níbẹ̀ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni naa tí ń ka awọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yii sókè ati awọn wọnnì tí ń gbọ́, tí wọ́n sì ń pa awọn ohun tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́; nitori àkókò tí a yànkalẹ̀ ti súnmọ́lé.” Bẹ́ẹ̀ ni, a ní láti kàwé sókè, kí a sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Ọlọrun tí ó wà nínú Ìṣípayá àti jálẹ̀ inú Ìwé Mímọ́. Ẹni náà tí ó jẹ́ aláyọ̀ ní tòótọ́ ni ẹni tí “dídùn inú rẹ̀ wà ní òfin Oluwa; àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń [kà kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, NW] ní ọ̀sán àti ní òru.” Kí ni ìyọrísí rẹ̀? “Ohunkóhun tí ó ṣe ni yóò máa ṣe déédéé.” (Orin Dafidi 1:1-3) Nítorí náà, fún ìdí rere, ètò àjọ Jehofa ń rọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láti máa dá ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí a sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́, gẹ́gẹ́ bí ìdílé, àti pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́.
Ronú jinlẹ̀, Kí O Sì Ṣàṣàrò
6. Kí ni a fún Joṣua ní ìtọ́ni láti kà, báwo sì ni èyí ṣe ṣàǹfààní?
6 Báwo ni o ṣe lè jàǹfààní jù lọ láti inú bí o ṣe ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti àwọn ìtẹ̀jáde Kristian? Ó ṣeé ṣe kí o rí i pé ó ṣàǹfààní láti ṣe ohun tí Joṣua, aṣáájú Israeli ìgbàanì tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọrun ṣe. A pàṣẹ fún un pé: “Ìwé òfin yìí kò gbọdọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ óò máa [kà á kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, NW] ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè kíyè sí àtiṣe gẹ́gẹ́ bíi gbogbo èyí tí a kọ sínú rẹ̀: nítorí nígbà náà ni ìwọ óò ṣe ọ̀nà rẹ̀ ní rere, nígbà náà ni yóò sì dára fún ọ.” (Joṣua 1:8) ‘Kíkàwé kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́’ túmọ̀ sí dídá sọ àwọn ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ohùn rírẹlẹ̀. Àrànṣe kan láti lè rántí ní èyí jẹ́, nítorí pé ó ń tẹ àkópọ̀ ọ̀rọ̀ náà mọ́ni lọ́kàn. A sọ fún Joṣua pé kí ó máa kà nínú Òfin Ọlọrun “ní ọ̀sán àti ní òru,” tàbí kí ó máa kà á déédéé. Ọ̀nà tí a lè gbá ṣàṣeyọrí, tí a sì lè gbà hùwà lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu nínú bíbójú tó ẹrù iṣẹ́ tí Ọlọrun fún wa nìyẹn. Irú kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun déédéé bẹ́ẹ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ lọ́nà kan náà.
7. Èé ṣe tí kò fi yẹ kí á jẹ́ kí èrò jẹ́-n-tètè-kà-á-tán jọba lọ́kàn wa nígbà tí a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun?
7 Má ṣe jẹ́ kí èrò jẹ́-n-tètè-kà-á-tán jọba lọ́kàn rẹ̀ nígbà tí o bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Bí o bá ti wéwèé láti lo àkókò kan láti ka Bibeli tàbí àwọn ìtẹ̀jáde Kristian kan, fara balẹ̀ kà á. Èyí ṣe pàtàkì ní ti gidi nígbà tí o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú góńgó láti rántí àwọn kókó pàtàkì. Nígbà tí o bá sì ń kàwé, máa ronú jinlẹ̀. Ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ àwọn gbólóhùn òǹkọ̀wé Bibeli náà. Bí ara rẹ pé, ‘Kí ni lájorí ọ̀rọ̀ rẹ̀? Kí ni ó yẹ kí n ṣe pẹ̀lú ìsọfúnni yìí?’
8. Èé ṣe tí ó fi ṣàǹfààní láti ṣàṣàrò nígbà tí a bá ń ka Ìwé Mímọ́?
8 Lo àkókò láti ṣàṣàrò nígbà tí o bá ń ka Ìwé Mímọ́. Èyí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rántí àwọn àkọsílẹ̀ Bibeli àti láti fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò. Ṣíṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti títipa bẹ́ẹ̀ rántí àwọn kókó pàtàkì yóò tún ràn ọ́ lọ́wọ́ láti le sọ̀rọ̀ láti inú ọkàn-àyà rẹ wá, ní fífún olùfitọkàntọkàn ṣèwádìí ní àwọn ìdáhùn tí ó mọ́yán lórí dípò sísọ àwọn ohun kan tí ìwọ yóò kábàámọ̀ lé lórí nígbẹ̀yìn. Òwe onímìísí àtọ̀runwá kan sọ pé: “Àyà olódodo ṣàṣàrò láti dáhùn.”—Owe 15:28.
So Àwọn Kókó Tuntun Pọ̀ Mọ́ Ti Àtẹ̀yìnwá
9, 10. Báwo ni o ṣe lè mú kí Bibeli kíkà rẹ sunwọ̀n sí i nípa síso àwọn kókó tuntun láti inú Ìwé Mímọ́ pọ̀ mọ́ àwọn tí o ti mọ̀ tẹ́lẹ̀?
9 Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Kristian gbọ́dọ̀ gbà pé nígbà kan ohun tí wọ́n mọ̀ nípa Ọlọrun, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti àwọn ète rẹ̀ kò tó nǹkan. Ṣùgbọ́n, lónìí, àwọn Kristian òjíṣẹ́ yìí lè ṣàlàyé ète ẹbọ Kristi, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ìṣẹ̀dá àti ìṣubú ènìyàn sínú ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n lè sọ nípa ìparun ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú yìí, wọ́n sì lè fi hàn bí a óò ṣe fi ìyè ayérayé lórí paradise ilẹ̀ ayé kan bù kún aráyé onígbọràn. Èyí ṣeé ṣe ní pàtàkì nítorí pé, àwọn ìránṣẹ́ Jehofa wọ̀nyí ti gba “ìmọ̀ Ọlọrun” sínú nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àti àwọn ìtẹ̀jáde Kristian. (Owe 2:1-5) Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n so àwọn kókó tuntun tí wọ́n kọ́ pọ̀ mọ́ èyí tí wọ́n ti lóye látẹ̀yìnwá.
10 Síso àwọn kókó tuntun nínú Ìwé Mímọ́ pọ̀ mọ́ àwọn tí o ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ ń ṣàǹfààní, ó sì ń mú èrè wá. (Isaiah 48:17) Nígbà tí a bá gbé àwọn òfin Bibeli, ìlànà, tàbí èrò kan tí ó yàtọ̀ pátápátá jáde, so ìwọ̀nyí pọ̀ mọ́ ohun tí o ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. So ìsọfúnni náà pọ̀ mọ́ ohun tí o ti kọ́ tẹ́lẹ̀ nípa “àpẹẹrẹ àwòṣe awọn ọ̀rọ̀ afúnninílera.” (2 Timoteu 1:13) Wá àwọn ìsọfúnni tí ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fún ipò ìbátan rẹ pẹ̀lú Ọlọrun lókun, láti mú àkópọ̀ ìwà Kristian rẹ sunwọ̀n sí i, tàbí láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàjọpín àwọn òtítọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.
11. Kí ni o lè ṣe nígbà tí o bá ka ohun kan tí Bibeli sọ nípa ìwà? Fúnni ní àpẹẹrẹ.
11 Nígbà tí o bá ń ka ohun kan tí Bibeli sọ nípa ìwà, gbìyànjú láti fòye mọ ìlànà tí ó wé mọ́ ọn. Ṣàṣàrò lórí rẹ̀, kí o sì pinnu ohun tí ìwọ yóò ṣe lábẹ́ irú ipò kan náà. Josefu, ọmọkùnrin Jakobu, kọ̀ jálẹ̀ láti hu ìwà pálapàla pẹ̀lú aya Potifari, ní bíbéèrè pé: “Ǹjẹ́ èmi óò ha ti ṣe hu ìwà búburú ńlá yìí, kí èmí sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọrun?” (Genesisi 39:7-9) Nínú àkọsílẹ̀ arùmọ̀lára sókè yìí, o lè rí ìlànà ìpìlẹ̀ kan—ìwà pálapàla jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ sí Ọlọrun. O lè fi ọgbọ́n ìrònú so ìlànà yìí pọ̀ mọ́ àwọn gbólóhùn míràn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, o sì lè jèrè láti inú rírántí rẹ̀, bí a bá dán ọ wò láti lọ́wọ́ nínú irú ìwà àìtọ́ bẹ́ẹ̀.—1 Korinti 6:9-11.
Fojú Inú Wo Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Inú Ìwé Mímọ́
12. Èé ṣe tí ó fi yẹ láti fojú inú wo àwọn àkọsílẹ̀ Bibeli bí o ṣe ń kà wọ́n?
12 Láti tẹ àwọn kókó mọ́ ọ lọ́kàn bí o ṣe ń kàwé, fojú inú wo ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Finú wòye agbègbè náà, àwọn ilé, àwọn ènìyàn. Gbọ́ ohùn wọn. Gbóòórùn búrẹ́dì tí a ń ṣe nínú ààrò. Fọkàn yàwòrán ìran náà. Nígbà náà, ìwé kíkà rẹ yóò jẹ́ ìrírí arùmọ̀lárasókè, nítorí ìwọ lè rí ìlú ńlá ìgbàanì kan, o lè gun òkè gíga fíofío kan, àwọn àgbàyanu ìṣẹ̀dá lè mú ọ kọ háà, tàbí kí o dara pọ̀ mọ́ àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí ìgbàgbọ́ wọn ga.
13. Báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣàpèjúwe ohun tí a ṣàkọsílẹ̀ nínú Onidajọ 7:19-22?
13 Ká ní o ń ka Onidajọ 7:19-22. Fojú inú wo ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Onídàájọ́ Gideoni àti ọ̀ọ́dúnrún akíkanjú ọkùnrin Israeli ti wà ní àyè wọn ní etí ibùdó àwọn ará Midiani. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó aago mẹ́wàá alẹ́, ìbẹ̀rẹ̀ “ìṣọ́ àárín.” A ṣẹ̀ṣẹ̀ yan àwọn ẹ̀ṣọ́ àwọn ará Midiani sí ipò wọn ni, òkùnkùn sì bo ibùdó àwọn ọ̀tá àwọn ọmọ Israeli tí ń sùn lọ́wọ́. Kíyè sí i! Gideoni àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ mú ipè lọ́wọ́. Wọ́n ní ìṣà omi ńlá tí ó bo àwọn òtùfù tí ó wà ní ọwọ́ òsì wọn. Lójijì, agbo ẹgbẹ́ mẹ́ta tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ọgọ́rùn-ún ọkùnrin nínú fọn ipè wọn, wọ́n fọ́ ìṣà wọn, wọ́n na òtùfù wọn sókè, wọ́n sì kígbe pé: “Idà OLUWA, àti ti Gideoni.” Wo ibùdó wọn ná. Họ́wù, àwọn ará Midiani fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ, wọ́n sì figbe ta! Bí ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin náà ṣe ń bá fífọn ipè wọn lọ, Ọlọrun mú kí àwọn ará Midiani kọjú ìjà sí ara wọn. A ti mú kí Midiani bá ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀, Jehofa sì ti fún Israeli ní ìṣẹ́gun.
Kíkọ́ Àwọn Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n
14. Báwo ni a ṣe lè lo Onidajọ orí 9 láti kọ́ ọmọ kan ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀?
14 Nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, a lè kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́. Fún àpẹẹrẹ, bóyá o fẹ́ tẹ ìdí tí ó fi yẹ kí a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ mọ́ ọmọ rẹ lọ́kàn. Tóò, ó lè rọrùn láti fojú inú wo kókó ohun tí a sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jotamu, ọmọkùnrin Gideoni, kí a sì lóye rẹ̀. Bẹ̀rẹ̀ sí í kà á láti Onidajọ 9:8. Jotamu wí pé: “Àwọn igi lọ ní àkókò kan kí wọn kí ó lè fi ọba jẹ lórí wọn.” Igi ólífì, igi ọ̀pọ̀tọ́, àti igi àjàrà kọ̀ láti jọba. Ṣùgbọ́n inú igi ẹ̀gún rírẹlẹ̀ dùn láti di ọba. Lẹ́yìn tí o ti ka àkọsílẹ̀ náà sókè fún àwọn ọmọ rẹ, o lè ṣàlàyé pé igi tí ó níye lórí náà dúró fún àwọn ẹni yíyẹ tí wọn kò wá ipò ọba lórí àwọn ọmọ Israeli ẹlẹgbẹ́ wọn. Igi ẹ̀gún, tí ó wúlò fún kìkì iná dídá, dúró fún ipò ọba Abimeleki agbéraga, apànìyàn tí ó fẹ́ jẹ gàba lé àwọn ẹlòmíràn lórí, ṣùgbọ́n tí ó ko àgbákò ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jotamu. (Onidajọ, orí 9) Ọmọ wo ni yóò fẹ́ dàgbà di igi ẹ̀gún?
15. Báwo ni a ṣe fi ìjẹ́pàtàkì ìdúróṣinṣin hàn nínú ìwé Rutu?
15 Ìjẹ́pàtàkì ìdúróṣinṣin ni a mú ṣe kedere nínú ìwé Rutu nínú Bibeli. Ká ní àwọn mẹ́ḿbà ìdílé rẹ ń ka àkọsílẹ̀ náà sókè lọ́kọ̀ọ̀kan, tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti lóye ohun tí ó ń sọ. O rí Rutu ará Moabu tí ń rin ìrìn àjò lọ sí Betlehemu pẹ̀lú ìyakọ rẹ̀, Naomi, tí ó jẹ́ opó, o sì gbọ́ tí Rutu ń sọ pé: “Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò máa ṣe ènìyàn mí, Ọlọrun rẹ ni yóò sì máa ṣe Ọlọrun mi.” (Rutu 1:16) O rí Rutu òṣìṣẹ́ aláápọn tí ń pèéṣẹ́ lẹ́yìn àwọn olùkórè nínú oko Boasi. O gbọ tí Boasi ń gbóṣùbà fún un, ní sísọ pé: “Gbogbo àgbájọ àwọn ènìyàn mi ni ó mọ̀ pé obìnrin rere ni ìwọ́ í ṣe.” (Rutu 3:11) Kò pẹ́ kò jìnnà, Boasi fẹ́ Rutu. Ní ìbámu pẹ̀lú ìṣètò opó ṣíṣú, nípasẹ̀ Boasi, ó bí ọmọkùnrin kan “fún Naomi.” Rutu di ìyá ńlá Dafidi, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó di ìyá ńlá Jesu Kristi. Ó tipa bẹ́ẹ̀ gba “ẹ̀san iṣẹ́ rẹ̀.” Ní àfikún sí i, àwọn tí ń ka àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ náà kọ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n: Jẹ́ adúróṣinṣin sí Jehofa, a óò sì bù kún ọ jìngbìnnì.—Rutu 2:12; 4:17-22; Owe 10:22; Matteu 1:1, 5, 6.
16. Ìdánwò wo ni àwọn Heberu mẹ́ta nírìírí rẹ̀, báwo sì ni àkọsílẹ̀ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
16 Àkọsílẹ̀ nípa àwọn Heberu tí ń jẹ́ Ṣadraki, Meṣaki, àti Abednego lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Ọlọrun nínú ipò tí ń dánniwò. Fojú inú wo ìṣẹ̀lẹ̀ náà bí a ṣe ń ka Danieli orí 3 sókè. Ère gàgàrà tí a fi wúrà mọ rí gogoro lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dura, níbi tí àwọn lọ́gàá-lọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba Babiloni pé jọ sí. Nígbà tí ìró ohun èèlò orin dún, wọ́n wólẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn ère tí Ọba Nebukadnessari yá. Ìyẹn ni pé, gbogbo wọn ṣe bẹ́ẹ̀ àyàfi Ṣadraki, Meṣaki, àti Abednego. Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdúróṣinṣin, wọ́n sọ fún ọba náà pé, àwọn kì yóò sin àwọn ọlọrun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn kì yóò jọ́sìn ère oníwúrà náà. A ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Heberu wọ̀nyí sínú iná ìléru tí ń jó fòfò. Ṣùgbọ́n kí ni ó ṣẹlẹ̀? Nígbà tí ó wo inú rẹ̀, ọbá rí ọkùnrin abarapá mẹ́rin, ọ̀kan nínú wọn “dà bí . . . Ọmọ Ọlọrun.” (Danieli 3:25) A mú àwọn Heberu mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jáde kúrò nínú iná ìléru, Nebukadnessari sì fi ìyìn fún Ọlọrun wọn. Fífojú inú wo àkọsílẹ̀ yìí ti mú èrè wá. Ẹ sì wo irú ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n tí ó fúnni nípa ìṣòtítọ́ sí Jehofa lábẹ́ ìdánwò!
Àǹfààní Láti Inú Kíka Bibeli Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé
17. Ní ṣókí, sọ àwọn ohun ṣíṣàǹfààní tí ìdílé rẹ lè kọ́ nípasẹ̀ kíka Bibeli pa pọ̀?
17 Ìdílé rẹ lè gbádùn ọ̀pọ̀ àǹfààní bí ẹ bá ń lo àkókò láti ka Bibeli pa pọ̀ déédéé. Bí ẹ bá bẹ̀rẹ̀ ní Genesisi, ẹ lè fojú inú wo ìṣẹ̀dá, kí ẹ sì rí Paradise ilé ènìyàn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ẹ lè ṣàjọpín ìrírí àwọn bàbá ńlá olùṣòtítọ́ àti àwọn ìdílé wọn, kí ẹ sì tẹ̀ lé àwọn ọmọ Israeli bí wọ́n ṣe ń la orí ìyàngbẹ ilẹ̀ Òkun Pupa kọjá. Ẹ lè rí ọ̀dọ́ olùṣọ́ àgùtàn náà, Dafidi, bí ó ṣe ṣẹ́gun òmìrán ará Filistini náà, Goliati. Ìdílé rẹ lè ṣàkíyèsí kíkọ́ tẹ́ḿpìlì Jehofa ní Jerusalemu, ẹ lè rí ìsọdahoro rẹ̀ láti ọwọ́ agbo àwọn ará Babiloni, ẹ sì lè rí ṣíṣe àtúnkọ́ rẹ̀ lábẹ́ Gómìnà Serubbabeli. Pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀ olùṣọ́ àgùntàn nítòsí Betlehemu, ẹ lè gbọ́ ìkéde tí áńgẹ́lì náà ṣe nígbà ìbí Jesu. Ẹ lè rí kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa batisí rẹ̀ àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ẹ sì lè rí i tí ó fi ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn lélẹ̀ bí ìràpadà, ẹ sì lè ṣàjọpín ìdùnnú àjíǹde rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, ẹ lè rin ìrìn àjò pẹ̀lú aposteli Paulu, kí ẹ sì ṣàkíyèsí ìdásílẹ̀ àwọn ìjọ bí ìsìn Kristian ṣe ń tàn kálẹ̀. Lẹ́yìn náà, nínú ìwé Ìṣípayá, ìdílé rẹ lè gbádùn ìran kíkọyọyọ tí aposteli Johannu rí nípa ọjọ́ ọ̀la, títí kan Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi.
18, 19. Àwọn àbá wo ni a fúnni ní ti kíka Bibeli gẹ́gẹ́ bí ìdílé?
18 Bí ẹ bá ń ka Bibeli sókè gẹ́gẹ́ bí ìdílé, ẹ kà á yékéyéké àti tìtaratìtara. Nígbà tí ẹ bá ń ka àwọn apá kan nínú Ìwé Mímọ́, mẹ́ḿbà ìdílé kan—tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ bàbá—lè ka ọ̀rọ̀ àkópọ̀ ìtàn náà. Àwọn mìíràn lè kó ipa àwọn ẹ̀dá ìtàn inú Bibeli, ní kíka àwọn apá tìrẹ pẹ̀lú ìmọ̀lára tí ó bá a mu.
19 Bí ẹ ṣe ń ṣàjọpín nínú Bibeli kíkà gẹ́gẹ́ bí ìdílé, agbára ìkàwé yín lè sunwọ̀n sí i. Ó ṣeé ṣe kí ìmọ̀ yín nípa Ọlọrun pọ̀ sí i, èyí sì ní láti túbọ̀ fà yín sún mọ́ ọn. Asafu kọrin pé: “Ó dára fún mí láti sún mọ́ Ọlọrun: èmi ti gbẹ́kẹ̀ mi lé Oluwa Ọlọrun, kí èmi kí ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ gbogbo.” (Orin Dafidi 73:28) Èyí yóò ran ìdílé rẹ lọ́wọ́ láti dà bíi Mose, ẹni tí “ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni naa tí a kò lè rí,” ìyẹn ni, Jehofa Ọlọrun.—Heberu 11:27.
Ìwé Kíkà àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristian
20, 21. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe ní ìsopọ̀ pẹ̀lú agbára ìkàwé wa?
20 Ìfẹ́ ọkàn wa láti jọ́sìn “Ẹni naa tí a kò lè rí” yẹ kí ó sún wa láti ṣiṣẹ́ lórí jíjẹ́ òǹkàwé tí ó já fáfá. Agbára ìkàwé lọ́nà tí ó já gaara ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́rìí láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Dájúdájú, ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà lọ, èyí tí Jesu pa láṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà tí ó wí pé: “Ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba ati ti Ọmọkùnrin ati ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn lati máa pa gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún yín mọ́.” (Matteu 28:19, 20; Ìṣe 1:8) Ìjẹ́rìí ni olórí iṣẹ́ àwọn ènìyàn Jehofa, agbára ìkàwé sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣeparí rẹ̀.
21 Ó ń béèrè ìsapá láti lè jẹ́ òǹkàwé tí ó já fáfá àti olùkọ́ni tí ó dáńgájíá nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. (Efesu 6:17) Nítorí náà, ‘sa gbogbo ipá rẹ lati fi ara rẹ hàn fún Ọlọrun ní ẹni tí a fi ojú rere tẹ́wọ́ gbà, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.’ (2 Timoteu 2:15) Mú ìmọ̀ rẹ nípa òtítọ́ Ìwé Mímọ́ àti agbára ìkàwé rẹ pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jehofa, nípa fífi ara rẹ fún ìwé kíkà.
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
◻ Báwo ni ayọ̀ ṣe sinmi lórí kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun?
◻ Èé ṣe ti o fi ní láti ṣàṣàrò lórí ohun tí o kà nínú Bibeli?
◻ Èé ṣe tí a fi ní láti lo síso kókó pọ̀ àti fífi ojú inú wo nǹkan nígbà ti a bá ń ka Ìwé Mímọ́?
◻ Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ láti inú kíka Bibeli?
◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a ka Bibeli sókè gẹ́gẹ́ bí ìdílé, ìsopọ̀ wo sì ní ìwé kíkà ní pẹ̀lú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Nígbà tí ẹ bá ń ka Bibeli gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, ẹ fojú inú wo àwọn àkọsílẹ̀ náà, kí ẹ sì ṣàṣàrò lórí ìjẹ́pàtàkì wọn