ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/96 ojú ìwé 1
  • Àìdábọ̀ Nínú Pípolongo Ìhìn Rere

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àìdábọ̀ Nínú Pípolongo Ìhìn Rere
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Wọn Yóò Ṣe Gbọ́?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Máa Wàásù Láìdábọ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Iṣẹ́ Ìwàásù àti Kíkọ́ni Ṣe Pàtàkì Láti Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Àwọn Tó “Ní Ìtẹ̀sí-ọkàn Títọ́” Ń kọbi Ara Sí Ìwàásù Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 8/96 ojú ìwé 1

Àìdábọ̀ Nínú Pípolongo Ìhìn Rere

1 Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi ọwọ́ tí ó nípọn mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Lúùkù ròyìn pé: “Ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ḿpìlì àti láti ilé dé ilé ni wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.” (Ìṣe 5:42) Kò sí ohunkóhun tí ó lè dá wọn lọ́wọ́ kọ́, kódà inúnibíni pàápàá kò tó bẹ́ẹ̀! (Ìṣe 8:4) Wọ́n ń sọ nípa òtítọ́ náà fún àwọn ẹlòmíràn lójoojúmọ́.

2 Àwa náà ńkọ́? Bí ara rẹ léèrè pé: ‘Mo ha ní ìmọ̀lára ìjẹ́kánjúkánjú àkókò wa bí? Mo ha ní ìtẹ̀sí láti máa bá pípolongo ìhìn rere náà nìṣó láìdábọ̀ bí?’

3 Àpẹẹrẹ Wíwàásù Láìdábọ̀ Lóde Òní: Arábìnrin kan, tí ó ní àrun rọpárọsẹ̀, ń gbé nínú ahóló ẹ̀rọ àfimí. Kò ṣeé ṣe fún un láti lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí láti lọ sí àpéjọ. Ṣùgbọ́n, ọwọ́ rẹ̀ dí gan-an fún pípolongo ìhìn rere. Láàárín ọdún 37 tí ó fi wà ní àhámọ́, ó ṣeé ṣe fún un láti ran àwọn ènìyàn 17 lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́! Báwo ni ó ti ṣe é? Bí kò tilẹ̀ ṣeé ṣe fún un láti lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, ó wá ọ̀nà lójoojúmọ́ láti jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà, fún àwọn tí ó bá kàn sí i.

4 Àwọn ará wa ní Bosnia ti ní láti kojú ogun àti òfò. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ń bá a lọ déédéé láti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn. Ní Sarajevo, àwọn akéde lóṣooṣù ń ní tó 20 wákàtí ní ìpíndọ́gba, ní bíbá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọ́n sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méjì, ní ìpíndọ́gba. Láìka ipò ìnira wọn sí, wọ́n ń wàásù, wọ́n sì ń kọ́ni láìdábọ̀.

5 Àwọn ọ̀dọ́ pẹ̀lú ń fi ìtara hàn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. A fi ìdílé Ẹlẹ́rìí kan ní Rwanda sínú yàrá kan níbi tí àwọn sọ́jà ti ṣe tán láti pa wọ́n. Ìdílé náà bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n yọ̀ǹda fún àwọn láti gbàdúrà ná. A gbà pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, Deborah, ọmọdébìnrin wọn, gbàdúrà sókè pé: “Jèhófà, èmi àti Bàbá fi ìwé ìròyìn márùn-ún sóde lọ́sẹ̀ yìí. Báwo ni a óò ṣe padà tọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ láti kọ́ wọn ní òtítọ́, kí a sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ìyè?” Nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lílágbára, àti ìfẹ́ rẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, a dá ẹ̀mí gbogbo ìdílé náà sí.

6 Lónìí, ó ṣe pàtàkì pé kí a wà lójúfò sí àwọn àǹfààní láti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, kí a sì wá àwọn tí ó “ní ìtẹ̀sí ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” kàn. (Ìṣe 13:48) Ní ìbámu pẹ̀lú ipò àdúgbò, àwọn alàgbà ìjọ máa ń ṣètò ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀ sí àkókò tí ó bá wọ̀, yálà ní òwúrọ̀, lọ́sàn-án, tàbí nírọ̀lẹ́. Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa àti àwọn apá inú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, àpéjọ àyíká, àti àpéjọpọ̀ àgbègbè, ń pèsè àwọn àbá àti ìṣírí tí ó bá àkókò mu, láti ṣàjọpín nínú onírúurú ọ̀nà ìjẹ́rìí Ìjọba. Ní àfikún sí èyí, àwọn alábòójútó àyíká àti àgbègbè ń dá àwọn akéde lẹ́kọ̀ọ́ lórí ìjẹ́rìí òpópónà, wọ́n ń fi bí a ti ń ṣiṣẹ́ nínú àwọn ìpínlẹ̀ okòwò hàn wọ́n, wọ́n sì ń tọ́ka sí àwọn ọ̀nà míràn tí a lè gbà jẹ́rìí, níbikíbi tí a bá ti lè rí ènìyàn. Gbogbo ìwọ̀nyí ń tẹnu mọ́ àìdábọ̀ nínú pípolongo ìhìn rere!

7 Àwọn àpọ́sítélì Jésù fi tìgboyàtìgboyà kéde pé: “Àwa kò lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.” Báwo ni wọ́n ṣe lo ìforítì láìka gbogbo ìṣòro sí? Wọ́n bẹ Jèhófà pé kí ó ràn wọ́n lọ́wọ́, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, “gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan sì kún fún ẹ̀mí mímọ́ wọ́n sì ń fi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Ìṣe 4:20, 29, 31) Ó lè máà jẹ́ gbogbo wa ni a ní ìrírí tí ó tayọ lọ́lá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ṣùgbọ́n bí a bá fi tòótọ́tòótọ́ fẹ́ láti polongo ìhìn rere náà láìdábọ̀, tí a bá sì sapá gidigidi láti ṣe bẹ́ẹ̀, àní lójoojúmọ́ pàápàá, Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́