MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Iṣẹ́ Ìwàásù àti Kíkọ́ni Ṣe Pàtàkì Láti Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n lọ, kí wọ́n sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mt 28:19) Èyí gba pé ká wàásù ká sì kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Ó yẹ ká máa bi ara wa ní gbogbo ìgbà pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè sunwọ̀n sí i nínú àwọn apá pàtàkì lára iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn yìí?’
ÌWÀÁSÙ
Dípò tí a ó fí máa retí pé káwọn èèyàn wá bá wa, àfi ká dìídì wá àwọn “ẹni yíyẹ” kàn. (Mt 10:11) Tá a bá wà lóde ẹ̀rí, ṣé a máa ń tètè lo àǹfààní èyíkéyìí tó bá yọ láti bá “àwọn tí ó wà ní àrọ́wọ́tó” sọ̀rọ̀? (Iṣe 17:17) Ohun tó mú kí Lìdíà di ọmọ ẹ̀yìn ni pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sapá gan-an láti wàásù.—Iṣe 16:13-15.
“Ní òwúrọ̀, fún irúgbìn rẹ àti títí di ìrọ̀lẹ́, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ sinmi” (Onw 11:6)
WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁA WÀÁSÙ NÌṢÓ “LÁÌDÁBỌ̀”—LỌ́NÀ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ ÀTI LÁTI ILÉ-DÉ-ILÉ, LẸ́YÌN NÁÀ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo ni ohun tí Samuel ń ṣe lójoojúmọ́ ṣe fi hàn pé ó ń wá àǹfààní láti fúnrúgbìn òtítọ́?
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa kópa nínú gbogbo apá tí iṣẹ́ ìwàásù wa pín sí láìjẹ́ kó sú wa?
Nínú ìgbòkègbodò rẹ ojoojúmọ́, àwọn wo ni wàá fẹ́ bá sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run?
KỌ́NI LẸ́KỌ̀Ọ́
Tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, a ò kàn ní fún wọn ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kó sì tán síbẹ̀. A tún gbọ́dọ̀ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn, ká sì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. (1Kọ 3:6-9) Àmọ́ tí ẹnì kan ò bá tẹ̀ síwájú bó ṣe yẹ pẹ̀lú gbogbo ìsapá wa láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run ńkọ́? (Mt 13:19-22) Àá ṣì máa wá àwọn tí ọkàn wọn dà bí “erùpẹ̀ àtàtà.”—Mt 13:23; Iṣe 13:48.
“Èmi gbìn, Àpólò bomi rin, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ń mú kí ó máa dàgbà” (1Kọ 3:6)
WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁA WÀÁSÙ NÌṢÓ “LÁÌDÁBỌ̀”—NÍBI TÉRÒ PỌ̀ SÍ ÀTI MÁA SỌ ÀWỌN ÈÈYÀN DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN, LẸ́YÌN NÁÀ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo ni Solomon àti Mary ṣe bomi rin irúgbìn òtítọ́ tí wọ́n gbìn sọ́kàn Ezekiel àti Abigail?
Kí ló yẹ kó jẹ́ àfojúsùn wa bá a ṣe ń kópa nínú gbogbo apá tí iṣẹ́ ìwàásù wa pín sí, títí kan ìwàásù níbi térò pọ̀ sí?
Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ máa kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́?