Ta Ní Tóótun Láti Wàásù?
1 Nígbà tí ó bá kan ọ̀ràn iṣẹ́ òjíṣẹ́, o ha fìgbà kan rí nímọ̀lára bíi ti Mósè bí? Ó sọ pé: “Olúwa, èmi kì í ṣe ẹni ọ̀rọ̀ sísọ nígbà àtijọ́ wá, tàbí láti ìgbà tí o ti ń bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀.” (Ẹks. 4:10) Bí o bá nímọ̀lára lọ́nà yẹn, o lè nítẹ̀sí láti tàdí mẹ́yìn. Síbẹ̀, Jésù “pa àṣẹ ìtọ́ni fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná.” (Ìṣe 10:42) Nítorí náà, báwo ní a ṣe ń di oníwàásù ìhìn rere tí ó tóótun?
2 Kì í ṣe bí a ṣe kàwé tó nínú ayé ní ń sọ wá di ẹni tí ó tóótun fún iṣẹ́ òjíṣẹ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé, “kì í ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n ní ọ̀nà ti ẹran ara ni a pè,” àti pé, “ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ ìwà òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” (1 Kọr. 1:26; 3:19) Jésù yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lára àwọn òṣìṣẹ́—ó kéré tán, àwọn mẹ́rin jẹ́ apẹja. Àwọn agbéraga olórí ìsìn fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kà wọ́n sí “àwọn ènìyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù.” Tí a bá gbé e ka ọ̀pá ìdíwọ̀n ti ayé, àwọn àpọ́sítélì kò tóótun láti wàásù. Síbẹ̀, àwíyé alágbára tí Pétérù sọ ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, sún àwọn 3,000 láti ṣe batisí!—Ìṣe 2:14, 37-41; 4:13.
3 Jèhófà Ní Ń Mú Wa Tóótun Láti Wàásù: Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Títóótun wa tẹ́rùntẹ́rùn ń jáde wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (2 Kọr. 3:5) Jèhófà, Orísun ọgbọ́n, ti kọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn láti wàásù òtítọ́ Ìjọba fún àwọn ẹlòmíràn. (Aisa. 54:13) A lè rí ìgbéṣẹ́ àti ìmésojáde iṣẹ́ yìí nínú 338,491 tí a batisí ní ọdún tí ó kọjá, gẹ́gẹ́ bí “lẹ́tà ìdámọ̀ràn fún ìtẹ́wọ́gbà.” (2 Kọr. 3:1-3) A ní ìdí tí ó pọ̀ rẹpẹtẹ láti fi àìṣojo àti ìdálójú ìgbàgbọ́ wàásù nípa àwọn ohun tí a ti kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.
4 Ètò àjọ Ọlọ́run ti dá ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kárí ayé sílẹ̀ fún àwọn òjíṣẹ́. Nípasẹ̀ Ìwé Mímọ́ àti onírúurú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a ti fún wa nítọ̀ọ́ni, a sì ti dá wa lẹ́kọ̀ọ́ láti di ẹni tí ó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbara dì pátápátá” láti wàásù. (2 Tim. 3:16, 17) Ọ̀pọ̀ ni a ti mú orí wọn wú nítorí ìmọ̀ títayọ lọ́lá tí ń bẹ nínú àwọn ìtẹ̀jáde Society. Fún àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà kan ní ilẹ̀ Sweden sọ pé: “Ìmọ̀ Bíbélì gbígbòòrò kárí ayé àti ìmọ̀ gíga lọ́lá ní ti ẹ̀kọ́ ìwé ni ó jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún ìgbàgbọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù rẹ̀.”
5 Pẹ̀lú ìtọ́ni tí a ń rí gbà nínú àwọn ìpàdé márùn-ún ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tí a ń ṣe, nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a ní fún Bíbélì kíkà àti fún ìkẹ́kọ̀ọ́, ìmọ̀ràn inú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, ìrànwọ́ tí àwọn òjíṣẹ́ onírìírí ń fún wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìtìlẹ́yìn ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, a lè ní ìdánilójú pé Jèhófà kà wá sí ẹni tí ó tóótun ní kíkún láti wàásù. “Bẹ́ẹ̀ ni, gẹ́gẹ́ bí a ti rán wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ní iwájú Ọlọ́run, ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, ni àwá ń sọ̀rọ̀.”—2 Kọr. 2:17.
6 Bí a bá lo gbogbo àǹfààní ìdálẹ́kọ̀ọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, tí Ọlọ́run ń pèsè, nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀, kò ní sí ìdí fún wa láti tàdí mẹ́yìn tàbí láti jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mú wa láyà pami. A lè fi tayọ̀tayọ̀ wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, pẹ̀lú ìdánilójú pé Jèhófà yóò bù kún ìsapá wa.—1 Kọr. 3:6.