Orin 92
“Wàásù Ọ̀rọ̀ Náà”
1. Ọlọ́run pàṣẹ kan lónìí;
Ó fún wa láṣẹ kan láti pa mọ́.
Nígbà gbogbo, ṣe tán láti sọ
Ìdí ìrètí tó wà lọ́kàn rẹ.
(ÈGBÈ)
Ṣáà máa wàásù,
Gbogbo èèyàn gbọ́dọ̀ gbọ́!
Máa wàásù,
Òpin ayé ti dé tán.
Máa wàásù,
Kọ́lọ́kàn tútù lóye.
Máa wàásù,
Kárí ayé!
2. Àsìkò ìdààmú yóò wà;
Inúnibíni lè dójú tini.
Iṣẹ́ ìwàásù lè má rọgbọ,
Olódùmarè làwa gbẹ́kẹ̀ lé.
(ÈGBÈ)
Ṣáà máa wàásù,
Gbogbo èèyàn gbọ́dọ̀ gbọ́!
Máa wàásù,
Òpin ayé ti dé tán.
Máa wàásù,
Kọ́lọ́kàn tútù lóye.
Máa wàásù,
Kárí ayé!
3. Àsìkò tó rọgbọ yóò wà,
Aó sì rídìí tó fi yẹ ká kọ́ni.
A ńpòkìkí ọ̀nà ìgbàlà
Kí orúkọ Jèhófà bàa lè mọ́.
(ÈGBÈ)
Ṣáà máa wàásù,
Gbogbo èèyàn gbọ́dọ̀ gbọ́!
Máa wàásù,
Òpin ayé ti dé tán.
Máa wàásù,
Kọ́lọ́kàn tútù lóye.
Máa wàásù,
Kárí ayé!
(Tún wo Mát. 10:7; 24:14; Ìṣe 10:42; 1 Pét. 3:15.)