ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/10 ojú ìwé 1
  • Ǹjẹ́ Mo Tóótun Láti Wàásù?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Mo Tóótun Láti Wàásù?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta Ní Tóótun Láti Wàásù?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • A Ti Mú Wa Gbára Dì Fún Iṣẹ́ Olùkọ́ni Ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Báwo La Ṣe Ń Wàásù Ìhìn Rere?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dá Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
km 1/10 ojú ìwé 1

Ǹjẹ́ Mo Tóótun Láti Wàásù?

1. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká rò pé a ò tóótun láti wàásù?

1 Bó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò tóótun láti wàásù, má mikàn! Kì í ṣe ìwé téèyàn kà tàbí ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ téèyàn ní ló ń sọni di òjíṣẹ́ tó tóótun. Wọ́n pe àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní àwọn èèyàn tí “kò mọ̀wé àti gbáàtúù.” Síbẹ̀, wọ́n wàásù ìhìn rere lọ́nà tó gbéṣẹ́ torí wọ́n pinnu láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀.—Ìṣe 4:13; 1 Pét. 2:21.

2. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà kọ́ni?

2 Ọ̀nà Tí Jésù Gbà Kọ́ni: Jésù kọ́ni lọ́nà tó rọrùn, tó ṣeé fi sílò, tó sì máa ń tètè yéni. Ó lo àwọn ìbéèrè, àkàwé àti ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí kò lọ́jú pọ̀, èyí sì mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lọ́kàn. (Mát. 6:26) Ó fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ òun lọ́kàn. (Mát. 14:14) Síwájú sí i, Jésù fi hàn pé ohun tóun ń sọ dá òun lójú àti pé òun ní ọlá àṣẹ, ó mọ̀ pé Jèhófà ló gbéṣẹ́ lé òun lọ́wọ́ tó sì ń fún òun lágbára láti ṣe iṣẹ́ ọ̀hún.—Lúùkù 4:18.

3. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

3 Jèhófà Ń Ràn Wá Lọ́wọ́: Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá ń lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀ láti kọ́ wa ká lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Aísá. 54:13) Bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ni wà lákọọ́lẹ̀ fún wa ló jẹ́ ká lè gbé àpẹẹrẹ rẹ̀ yẹ̀ wò ká sì lè fara wé e. Jèhófà ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ó sì máa ń tipasẹ̀ àwọn ìpàdé ìjọ kọ́ wa. (Jòh. 14:26) Láfikún sí èyí, Jèhófà tún pèsè àwọn akéde tó nírìírí tí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ kí iṣẹ́ ìwàásù wa lè túbọ̀ gbéṣẹ́.

4. Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkàn wa balẹ̀ pé a tóótun láti sọ ìhìn rere fáwọn ẹlòmíì?

4 Kò sídìí tó fi yẹ ká máa ronú pé a ò tóótun láti wàásù, torí “títóótun wa tẹ́rùntẹ́rùn ń jáde wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (2 Kọ́r. 3:5) Bá a bá ń gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tọkàntọkàn tá a sì ń lo àwọn ìpèsè onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lọ́nà rere, a máa jẹ́ ẹni tó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Tím. 3:17.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́