Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 11
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 11
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv orí 15 ìpínrọ̀ 10 sí 17 àti àpótí tó wà lójú ìwé 177
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóṣúà 21-24
No. 1: Jóṣúà 24:1-13
No. 2: Ṣé Aláìláàánú àti Ẹni Tí Kò Bìkítà Ni Ọlọ́run?
No. 3: Ìbatisí Kò Wẹ Ẹ̀ṣẹ̀ Nù (td 17B)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
15 min: Kọ́ Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Láti Máa Dá Kẹ́kọ̀ọ́. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. A gbé e ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 28 sí 31 lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Bí A Ṣe Ń Kẹ́kọ̀ọ́.” Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àṣefihàn kan tó fi hàn bí akéde kan tó nírìírí ṣe ń lo ohun tó wà lójú ìwé 7 nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni láti kọ́ ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bó ṣe lè máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sílẹ̀.
15 min: “Ǹjẹ́ Mo Tóótun Láti Wàásù?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 4, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan, nípa lílo àwọn ìbéèrè bíi: Àwọn ìṣòro wo lo ti borí kó o lè máa wàásù lọ́nà tó gbéṣẹ́? Àwọn ìrànlọ́wọ́ wo lo ti rí gbà tó mú kó o lè máa fìtara wàásù kó o sì lè máa ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?