Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún August
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 5
Orin 56
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a ṣà yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
20 min: “Àìdábọ̀ Nínú Pípolongo Ìhìn Rere.” Ọ̀rọ̀ àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Fi àyọkà láti inú Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ 2, ojú ìwé 673, ìpínrọ̀ 1 kún un.
15 min: “Fi Àwọn Ìwé Pẹlẹbẹ Pòkìkí Ìhìn Rere Ìjọba Náà.” (Ìpínrọ̀ 1 sí 5) Lo ìpínrọ̀ kíní nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ. Sọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró nípa àǹfààní tí ó wà nínú lílo àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà, Gbádùn Iwalaaye àti “Sawo O!” nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ṣètò fún àṣefihàn mẹ́rin tí a ti múra sílẹ̀ dáradára, tí ń fi bí a ṣe ń ṣe ìkésíni àkọ́kọ́ àti ìpadàbẹ̀wò nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ wọ̀nyí hàn. Jẹ́ kí ọmọdé akéde kan, tí òbí rẹ̀ tẹ̀ lé, ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ ìwé pẹlẹbẹ náà, Gbádùn Iwalaaye. Àwọn akéde lè fẹ́ láti gbé ìgbékalẹ̀ wọn dìde fún fífi àwọn ìwé pẹlẹbẹ mìíràn síta nípa títẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tí a dábàá síhìn-ín.
Orin 136 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 12
Orin 192
15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàyẹ̀wò Àpótí Ìbéèrè.
15 min: “Fi Àwọn Ìwé Pẹlẹbẹ Pòkìkí Ìhìn Rere Ìjọba Náà.” (Ìpínrọ̀ 6 sí 8) Ṣàlàyé ṣókí lórí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Akoso. Ṣàṣefihàn àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dámọ̀ràn fún ìkésíni àkọ́kọ́ àti ìpadàbẹ̀wò. Rọ gbogbo àwùjọ láti ṣiṣẹ́ lórí ìwé tí wọ́n fi síta.
15 min: “Ọrẹ fún Iṣẹ́ Society Kárí Ayé Ń Ṣètìlẹyìn fún Ìmúgbòòrò.” Ọ̀rọ̀ onítara láti ẹnu alàgbà. Fi àwọn nọ́ḿbà tí ń fi ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ Ìjọba náà hàn ní díẹ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tí a dárúkọ, gẹ́gẹ́ bí a ṣe ròyìn nínú Yearbook, kún un.
Orin 9 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 19
Orin 174
12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó. Fi àlàyé tí ń gbéni ró lórí “Àwọn Ọ̀nà Láti Ṣàjọpín,” tí ó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà, December 1, 1993, ojú ìwé 29 sí 31, kún un.
15 min: “Ta Ní Tóótun Láti Wàásù?” Alàgbà jíròrò ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ pẹ̀lú akéde méjì tàbí mẹ́ta. Tẹnu mọ́ ọn pé, a ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó dára jù lọ, tí ó wà, tí ń mú wa gbara dì ní kíkún gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run. Kò sí ìdí fún wa láti ronú pé a kò tóótun láti wàásù.
18 min: “Bí A Óò Ṣe Fi Ìwé Ìmọ̀ Sọ Àwọn Ènìyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn.” Ìjíròrò ìpínrọ̀ 17 sí 26 nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, ti June 1996, pẹ̀lú àwùjọ. Ṣètò ṣáájú àkókò láti fi ìrírí àwọn ará tí ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Ìmọ̀ kún un. Wọ́n lè sọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró nípa bí wọ́n ṣe lo àwọn àbá tí ó wà nínú àkìbọnú náà, bí ó sì ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tí ń tẹ̀ síwájú. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti tọ́jú àkìbọnú náà, kí wọ́n sì máa yẹ̀ ẹ́ wò ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ tuntun.
Orin 189 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní August 26
Orin 104
5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣe ìfilọ̀ ètò tí a ṣe fún iṣẹ́ ìsìn pápá fún òpin ọ̀sẹ̀.
15 min: Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà tí ó jẹ́ olùbánisọ̀rọ̀ tí ó dáńgájíá, lórí àkójọ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, ti August 1994. Kárí ìpínrọ̀ 18 sí 22, láti ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀ náà, “Lílo Awọn Ẹ̀tọ́ Rẹ.” Ṣàlàyé pé, àwọn ilé ìwòsàn kan ti ń fa ẹ̀jẹ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí pàápàá lára, nítorí wọ́n bu ọwọ́ lu fọ́ọ̀mù ìjọ́hẹn ilé ìwòsàn náà, kí wọ́n tó fara balẹ̀ kà á. Fọ́ọ̀mù ìtúsílẹ̀ ilé ìwòsàn lè sọ pé, o ‘yọ̀ǹda fún wọn láti lo ìtọ́jú èyíkéyìí tí ó lè gba ẹ̀mí là,’ èyí tí wọ́n gbà gẹ́gẹ́ bí ọlá àṣẹ láti ọ̀dọ̀ aláìsàn láti lo ẹ̀jẹ̀. O gbọ́dọ̀ wọ́gi lé irú gbólóhùn bẹ́ẹ̀, kí o sì kọ gbólóhùn yìí sí i: ‘N kò ní fàyè gba ìfàjẹ̀sínilára lábẹ́ ipò èyíkéyìí.’ Tẹnu mọ́ ìtọ́ni tí ó wà ní ìpínrọ̀ 18. Rọ gbogbo ìdílé láti jẹ́ kí àkìbọnú náà máa wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní gbogbo ìgbà. Àwọn tí ó ti sọ ẹ̀dà tiwọn nù lè béèrè fún òmíràn lọ́dọ̀ akọ̀wé ìjọ. Bí ìjọ bá ń fẹ́ sí i, wọ́n lè kọ̀wé béèrè lọ́dọ̀ Society. Tún tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì mímú káàdì Advance Medical Directive/Release lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà, àti ìjẹ́pàtàkì jíjíròrò ìdúró wa lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú dókítà wa, nígbà ìbẹ̀wò àkọ́kọ́, kí a má dúró de ìgbà tí yánpọnyánrin bá ṣẹlẹ̀. Jọ̀wọ́, kíyè sí i pé káàdì Advance Medical Directive/Release kì í ṣe káàdì tí a ń lẹ̀ máyà gẹ́gẹ́ bí irú àwọn káàdì ìlẹ̀máyà tí a ń lò ní àwọn àpéjọpọ̀. Ó gbọ́dọ̀ wà pẹ̀lú wa ní gbogbo ìgbà, yálà nínú àpò aṣọ, nínú pọ́ọ̀sì, tàbí nínú àpamọ́wọ́, ṣùgbọ́n, a kò gbọdọ̀ fi sí ibi tí yóò ti hàn síta.
15 min: “Iwọ Ha Ń Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Lati Yan Jehofa Bí?” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà, tí a mú jáde láti inú Ilé-Ìṣọ́nà, October 1, 1994, ojú ìwé 26 sí 30. Tẹnu mọ́ ìdí tí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní kùtùkùtù ìgbésí ayé fi pọ̀n dandan àti bí àwọn òbí ṣe lè ya àkókò wọn sọ́tọ̀ fún èyí. Tẹnu mọ́ àǹfààní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ rere àti fífi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀. Mú ọ̀rọ̀ rẹ wá sí òpin pẹ̀lú ìdùnnú tí ń wá láti inú ríri í kí àwọn ọmọ wa yan Jèhófà.
10 min: Ṣàyẹ̀wò Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Tí A Fi Ń Lọni Ní September. A óò lo ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I, àti Igbesi Aye Yii Ha Ni Gbogbo Ohun Ti O Wà Bi?, nínú ìgbétásì àkànṣe. Ìwé Walaaye Titilae rọrùn láti lóye, ó sì ń fúnni nírètí. A ṣí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì payá nínú àwọn 30 orí tí ìwé náà ní. Àwòrán inú rẹ̀ lé ní 100. A gbé àwọn àkòrí orí 11 kalẹ̀ lọ́nà ìbéèrè, láti lè ru ọkàn-ìfẹ́ sókè. Orí 1 gbé àwọn ìdí tí ó bọ́gbọ́n mú, tí ó sì bá Ìwé Mímọ́ mu kalẹ̀ lórí ìdí tí wíwàláàyè títí láé nínú párádísè kan lórí ilẹ̀ ayé kì í fi í ṣe àlá kan lásán. Orí 7, “Idi Ti A Fi Wà Nihin,” yóò ru ọkàn-ìfẹ́ àwọn tí ó ti ṣe kàyéfì nípa ìtumọ̀ ìgbésí ayé sókè. Lójú ìwòye wàhálà àti ìwà ibi tí ó kún inú ayé lónìí, dájúdájú, orí 11, “Eeṣe Ti Ọlọrun Fi Àyè Gba Ìwa-ibi,?” yóò ru ọkàn-ìfẹ́ ọ̀pọ̀ onílé sókè. Orí 29, “Ṣiṣe Aṣeyọri Ìgbesi Aye Idile,” yóò fa ọkọ àti aya mọ́ra. Ó rọrùn láti lo àwọn àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 156 sí 158, nípa àwọn nǹkan tí a óò gbádùn nínú ayé tuntun Ọlọ́run, láti bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀. Jẹ́ kí akéde tí ó dágáńjíá lo ọ̀kan lára àwọn ìyọsíni wọ̀nyí láti ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ kúkúrú lórí ìwé Walaaye Titilae. Bí o bá wéwèé láti lo Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I, tàbí Igbesi Aye Yii Ha Ni Gbogbo Ohun Ti O Wà Bi?, o lè ṣe ìmúra sílẹ̀ ìgbékalẹ̀ rẹ, tí o gbé karí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí ó bá a mú nínú èyíkéyìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde mẹ́ta náà.
Orin 113 àti àdúrà ìparí.