Báwo Ni Wọn Yóò Ṣe Gbọ́?
1. Kí ló lè mú kí iṣẹ́ ìwàásù má rọrùn, kí sì nìdí tí kò fi ỵẹ ká jáwọ́?
1 Bí ọjọ́ Jèhófà ṣe ń yára sún mọ́lé, ó jẹ́ kánjúkánjú fún wa báyìí láti ran ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé. (Jòh. 17:3; 2 Pét. 3:9, 10) Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀, torí pé ọ̀pọ̀ ló máa ń dágunlá tàbí kí wọ́n máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. (2 Pét. 3:3, 4) Síbẹ̀, ó dájú pé àwọn kan ṣì wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa tí wọ́n máa tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà tí wọ́n bá gbọ́ ọ. Báwo nirú àwọn bẹ́ẹ̀ ṣe máa gbọ́ tí kò bá sẹ́ni tó máa wàásù fún wọn?—Róòmù 10:14, 15.
2. Ìṣírí wo ni àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wa?
2 Kíkojú Àtakò: Torí pé àwọn kan ṣì wà tí wọ́n fẹ́ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, a ò gbọ́dọ̀ rẹ̀wẹ̀sì rárá. Nílẹ̀ Yúróòpù, ìlú Fílípì ni wọ́n ti kọ́kọ́ gbọ́ ìwàásù ìhìn rere látẹnu àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn èké kan òun àti Sílà, wọ́n fi ọ̀pá nà wọ́n, wọ́n sì sọ wọ́n sẹ́wọ̀n. (Ìṣe 16:16-24) Àmọ́, ìyẹn ò mú kí Pọ́ọ̀lù fà sẹ́yìn nítorí ìbẹ̀rù. Nígbà tó wá lọ sílùú Tẹsalóníkà, ìyẹn ìlú tó kàn lẹ́nu ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀, ó “máyàle nípasẹ̀ Ọlọ́run.” (1 Tẹs. 2:2) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù yìí jẹ́ ká mọ̀dí tí kò fi yẹ ká “juwọ́ sílẹ̀!”—Gál. 6:9.
3. Kí ló lè mú káwọn kan tí ò fẹ́ gbọ́ ìhìn rere tẹ́lẹ̀ yí èrò wọn pa dà?
3 Àwọn kan tí ò fẹ́ gbọ́ ìhìn rere nígbà kan rí ti yí èrò wọn pa dà. Ó lè jẹ́ pé ìṣòro ọrọ̀ ajé, àìsàn, ikú ẹnì kan nínú ìdílé tàbí ìròyìn tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ló fa ìyípadà náà. (1 Kọ́r. 7:31) Àwọn ọmọ kan táwọn òbí wọn ò fẹ́ kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nígbà kan rí ti wá dàgbà báyìí, wọ́n sì fẹ́ gbọ́ ìhìn rere. Bá ò bá jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù wa, èyí á jẹ́ kírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láǹfààní láti “ké pe orúkọ Jèhófà” kó tó pẹ́ jù.—Róòmù 10:13.
4. Kí ló ń mú ká máa bá ìṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ “láìdábọ̀”?
4 Ẹ Máa Bá A Lọ “Láìdábọ̀”: Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àti fáwọn aládùúgbò wa á mú ká máa bá iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn lọ “láìdábọ̀” bíi tàwọn àpọ́sítélì ní ọ̀rúndún kìíní. (Ìṣe 5:42) Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló “ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí” tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé. (Ìsík. 9:4) Ẹ ò rí i pé ìrètí àti ìtura ńlá ló máa jẹ́ fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láti gbọ́ ìhìn rere! Kódà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò bá tiẹ̀ gbọ́ ìhìn rere, Ìwé Mímọ́ fi dá wa lójú pé inú Jèhófà ń dùn sí ìsapá wa.—Héb. 13:15, 16.