Máa Wàásù Láìdábọ̀
1 Nígbà míì, ó lè máa ṣe wá bíi pé a ti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, àmọ́ ìwọ̀nba làwọn tó dáhùn padà. Síbẹ̀, àwọn ìdí pàtàkì wà tó fi yẹ ká máa wàásù láìdábọ̀.—Mát. 28:19, 20.
2 Láti Ṣe Ẹ̀rí: Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run máa jẹ́ apá pàtàkì lára àwọn àmì “ìparí ètò àwọn nǹkan,” ó sì sọ pé a máa ṣe é “láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mát. 24:3, 14) Ẹ̀rí tó lágbára là ń jẹ́ fáwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bá rí wa tá à ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Kódà bí wọn ò tiẹ̀ fetí sí wa, ó ṣeé ṣe káwọn kan fi ọ̀pọ̀ wákàtí tàbí ọ̀pọ̀ ọjọ́ sọ̀rọ̀ nípa wíwá tá a wá sádùúgbò wọn lẹ́yìn tá a kúrò níbẹ̀. Tá a bá mọ ìdí tá a fi ń wàásù, a ò ní dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà kódà bí ìṣòro bá dé. Ńṣe là ń múnú Jèhófà dùn bá a ti ń lọ́wọ́ nínú mímú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ nípa wíwàásù àti kíkéde ìdájọ́ rẹ̀ tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí àwọn èèyàn.—2 Tẹs. 1:6-9.
3 Ìforítì Ṣe Pàtàkì: Nítorí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń pín ọkàn àwọn èèyàn níyà, tí wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ ráyè, ó yẹ ká níforítì tá a bá fẹ́ kí wọ́n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa. Odindi ọdún kan gbáko làwọn ará wa fi máa ń lọ sọ́dọ̀ obìnrin kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kó tó gbà pé kí wọ́n bá òun sọ̀rọ̀ látinú Bíbélì. Ohun tó gbọ́ múnú rẹ̀ dùn gan-an débi tó fi gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn ìpàdé kò sì pẹ́ tó fi sọ pé òun á fẹ́ láti ṣèrìbọmi.
4 Bí ipò ayé ṣe ń yára yí padà, bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn ń yí padà. Ọ̀pọ̀ àwọn tó kọ̀ láti gbọ́ ìwàásù wa nígbà kan rí lè wá fẹ́ gbọ́ nípa ìrètí tó ń tuni lára tá à ń wàásù rẹ̀. Ká tiẹ̀ wá ní ẹnì kan péré ló dáhùn padà lọ́nà rere sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá à ń wàásù, ìforítì wa tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.
5 Jákèjádò ayé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló túbọ̀ ‘ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tó ń ṣẹlẹ̀.’ (Ìsík. 9:4) Àbájáde iṣẹ́ ìwàásù wa ti fi hàn pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo ń dáhùn padà lọ́nà tó dáa sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá à ń wàásù rẹ̀. (Aísá. 2:2, 3) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà lọ láìdábọ̀, ká sì máa fi tìfẹ́tìfẹ́ forí tì í lẹ́nu iṣẹ́ ‘mímú ìhìn rere ohun tí ó dára jù’ lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn.—Aísá. 52:7; Ìṣe 5:42.