Ìdí Tá A Fi Ń Padà Lọ Léraléra
1. Ìbéèrè wo ló jẹ yọ nípa iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe?
1 Lọ́pọ̀ ibi, a sábà máa ń kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù wa látìgbàdégbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tá à ń wàásù fún lè ti sọ fún wa pé àwọn ò fẹ́ gbọ́rọ̀ wa, a ṣì máa ń padà lọ sọ́dọ̀ wọn. Kí nìdí tá a fi máa ń padà lọ sọ́dọ̀ wọn?
2. Kí ni olórí ohun tó ń jẹ́ ká máa tẹpá mọ́ iṣẹ́ ìwàásù?
2 Ìfẹ́ fún Jèhófà Àtàwọn Èèyàn: Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ni olórí ohun tó ń jẹ́ ká máa tẹpá mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ó máa ń wù wá látọkànwá pé ká máa bá a nìṣó láti sọ fáwọn ẹlòmíràn nípa Ọlọ́run wa ọlọ́láńlá. (Lúùkù 6:45) Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà máa ń mú ká lè ṣègbọràn sí òfin rẹ̀ ká sì tún ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti lè máa ṣègbọràn sí i. (Òwe 27:11; 1 Jòh. 5:3) Yálà àwọn èèyàn tẹ́tí gbọ́ wa tàbí wọn kọtí ikún, ìyẹn ò ní ká má máa bá a nìṣó láti fi ìṣòtítọ́ fara da ìṣòro tá à ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ náà. Ó ṣe tán, nígbà táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kojú inúnibíni pàápàá, wọ́n ṣì ń bá a nìṣó láti máa wàásù “láìdabọ̀.” (Ìṣe 5:42) Dípò tá ó fi rẹ̀wẹ̀sì báwọn èèyàn bá kọ̀ láti fetí sí wa, ṣe ni kẹ́ ẹ jẹ́ ká di ìdúró wa mú, ká túbọ̀ máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an àti pé à ń sìn ín tọkàntọkàn.
3. Ọ̀nà wo ni ìfẹ́ tá a ní fáwọn èèyàn máa gbà ràn wá lọ́wọ́ láti máa wàásù nìṣó?
3 A tún máa ń forí ti ìṣòro nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa. (Lúùkù 10:27) Jèhófà ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run. (2 Pét. 3:9) Kódà láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tá à ń ṣe lóòrèkóòrè, a ṣì máa ń rí àwọn tó fẹ́ sin Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ní Guadeloupe, bá a bá kó èèyàn mẹ́rìndínlọ́gọ́ta jọ, a máa rí nǹkan bí ẹnì kan láàárín wọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, igba ó lé mẹ́rìnlá [214] ló sì ṣèrìbọmi lọ́dún tó kọjá. Lọ́dún yẹn náà, nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan [20,000] èèyàn ló wà níbi Ìrántí Ikú Kristi, èyí tó jẹ́ nǹkan bí ẹnì kan láàárín èèyàn méjìlélógún!
4. Àwọn ọ̀nà wo ni àyípadà máa ń gbà bá ìpínlẹ̀ ìwàásù?
4 Àyípadà ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù: Lóòrèkóòrè ni àyípadà ń bá àwọn èèyàn tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Nígbà míì tá a bá wàásù nílé tí wọn kì í ti í fetí sí wa tẹ́lẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan nínú ìdílé yẹn tí ò tíì gbọ́ nípa iṣẹ́ wa tẹ́lẹ̀ ní ká wọlé kó sì gbọ́rọ̀ wa. Tàbí kẹ̀, a lè ráwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kó débẹ̀ tí wọ́n máa fìfẹ́ hàn. Àwọn ọmọ táwọn òbí wọn kì í fẹ́ fetí sílẹ̀ lè ti dàgbà kí wọ́n sì ti kúrò nílè, kó jẹ́ pé ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ni wọ́n rílé sí. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè fẹ́ ká wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn.
5. Kí ló lè mú káwọn èèyàn túbọ̀ fẹ́ máa fetí sílẹ̀?
5 Àwọn èèyàn fúnra wọn máa ń yí padà. Ìgbà kan wà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ “asọ̀rọ̀ òdì àti onínúnibíni àti aláfojúdi.” (1 Tím. 1:13) Bákan náà, ìgbà kan wà tí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sin Jèhófà lónìí ò fẹ́ràn òtítọ́. Àwọn kan tiẹ̀ ti lè ta ko ìhìn rere fáwọn àkókò kan. Bí ìran ayé yìí ṣe ń yí padà, àwọn alátakò kan tàbí àwọn tí ò nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ tẹ́lẹ̀ lè ti wá rí ìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ fetí sílẹ̀. Ó sì lè jẹ́ pé ìgbà táwọn míì bá tó dojú kọ àjálù kan, bí ikú èèyàn wọn kan, bíi kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn, kí ọ̀dá owó dá wọn, tàbí kí wọ́n ní àìlera, ni wọ́n máa tó fetí sílẹ̀.
6. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa bá a lọ ní fífi ọ̀yàyà wàásù?
6 Ètò àwọn nǹkan yìí ti ń kógbá sílé, ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ ìkọ́ni tá à ń ṣe ń bá a lọ ní pẹrẹu. (Aísá. 60:22) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá a lọ láti máa fọ̀yàyà wàásù ká sì máa sapá kó má bàa sú wa. Ẹlòmíì tá a máa bá sọ̀rọ̀ lè fẹ́ gbọ́. A ò gbọ́dọ̀ dákẹ́! ‘Nípa ṣíṣe èyí, a ó gba ara wa àtàwọn tó ń fetí sí wa là.’—1 Tím. 4:16.