Èé Ṣe Tí A Óò Fi Máa Wàásù Nìṣó?
1 Ṣé ó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń bá iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà lọ ní àdúgbò rẹ? (Mát. 24:14) Bó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè rò pé ẹ ti kárí gbogbo ìpínlẹ̀ ìjọ yín kúnnákúnná. Nísinsìnyí tó o bá ń wàásù, ó lè dà bíi pé ọ̀pọ̀ èèyàn tó ò ń bá pàdé ni kò ka ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà sí. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kíyè sí ohun tí a sọ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ nínú ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ní ojú ewé 140 sí 141. Àlàyé náà sọ pé: “Ní àwọn ibì kan, àṣeyọrí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lè dà bí èyí tí kò já mọ́ nǹkan kan rárá ní ìfiwéra pẹ̀lú iṣẹ́ àti ìsapá tí wọ́n ṣe. Síbẹ̀, wọ́n ń forí tì í nìṣó.” Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí a óò fi máa wàásù nìṣó?
2 Rántí Jeremáyà: Fífi tí à ń fi ìṣòtítọ́ fara dà á nínú iṣẹ́ ìwàásù kò yẹ kó sinmi lórí bóyá àwọn èèyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ wa tàbí wọn ò gbọ́. Jeremáyà wàásù fún ogójì ọdún ní ìpínlẹ̀ kan náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló fetí sílẹ̀ sí i tí ọ̀pọ̀ jù lọ sì ta ko iṣẹ́ tó ń jẹ́. Èé ṣe tí Jeremáyà fi tẹra mọ́ ọn? Ìdí ni pé ó ń ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run pàṣẹ fún un láti ṣe, àti pé mímọ̀ tó mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ló jẹ́ kó máa fìgboyà sọ̀rọ̀.—Jer. 1:17; 20:9.
3 Ipò wa lónìí bá tirẹ̀ dọ́gba. Jésù ti “pa àṣẹ ìtọ́ni fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná pé Ẹni tí Ọlọ́run ti fàṣẹ gbé kalẹ̀ nìyí pé kí ó jẹ́ onídàájọ́ alààyè àti òkú.” (Ìṣe 10:42) Ìhìn iṣẹ́ tá à ń jẹ́ jẹ́ ọ̀ràn ìyè àti ikú fún àwọn tó ń gbọ́ ọ. A ó ṣèdájọ́ àwọn èèyàn ní ìbámu pẹ̀lú bí wọ́n bá ṣe dáhùn sí ìhìn rere náà. Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, ojúṣe wa ni láti ṣe bí wọ́n ṣe pàṣẹ fún wa gan-an. Kódà bí àwọn èèyàn ò bá fetí sílẹ̀, èyí ń fún wa láǹfààní láti fi bí ìfẹ́ wa sí wọn àti ìfọkànsìn wa sí Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó hàn nípa títẹra mọ́ ohun tó yẹ ká ṣe. Àmọ́ kò tán síbẹ̀ o.
4 À Ń Jàǹfààní: Ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, láìka bí àwọn èèyàn ṣe lè dáhùn ní ìpínlẹ̀ wa sí, máa ń fún wa ní ìbàlẹ̀ ọkàn, ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀, èyí tá ò lè rí lọ́nà mìíràn. (Sm. 40:8) Ìgbésí ayé wa yóò ní ìtumọ̀ àti ète gidi. Bá a bá ṣe túbọ̀ ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó, bẹ́ẹ̀ ni a óò ṣe túbọ̀ máa pa ọkàn wa àti èrò inú wa pọ̀ sórí ìrètí àti ayọ̀ gbígbé nínú ayé tuntun Ọlọ́run tó. Ríronú lórí àwọn ìlérí Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí máa ń jẹ́ kí ipò tẹ̀mí wa túbọ̀ sunwọ̀n sí i, ó sì máa ń jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i.
5 Kódà bí a kò bá rí àbájáde ojú ẹsẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù wa, a lè ti gbin irúgbìn òtítọ́, tí yóò hù bí àkókò bá tó lójú Jèhófà, sí ọkàn ẹnì kan. (Jòh. 6:44; 1 Kọ́r. 3:6) Kò sí èyíkéyìí nínú wa tó mọ bí àwọn tó ṣì máa wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba náà ṣe máa pọ̀ tó nípasẹ̀ ìsapá àwa èèyàn Jèhófà, yálà ní ìpínlẹ̀ wa ni o tàbí jákèjádò ayé.
6 Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, a ní láti kọbi ara sí ìtọ́ni Jésù pé: “Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́. Ṣùgbọ́n ohun tí mo sọ fún yín ni mo sọ fún gbogbo ènìyàn, Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” (Máàkù 13:33, 37) Ǹjẹ́, nígbà náà, kí gbogbo wa máa bá a nìṣó ní pípolongo ìhìn rere Ìjọba náà, kí a sì máa mú ọkàn Jèhófà yọ̀ bá a ti ń kópa nínú sísọ orúkọ ńlá rẹ̀ di mímọ́.