Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 12
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 12
Orin 162
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 6-10
No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 9:1-17
No. 2: Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀ Lòdì sí Ẹ̀mí Mímọ́? (td-YR 15E)
No. 3: Lẹ́tà Kan Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Tó Fẹ́ràn Wa (lr-YR orí 2)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 16
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù January sílẹ̀.
10 min: Àǹfààní Tó Wà Nínú Kéèyàn Ní Èrò Tó Dáa Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Jésù wo àwọn tó ń wàásù fún gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tó nílò ìrànlọ́wọ́, àpẹẹrẹ rere lèyí sì jẹ́ fún wa. (Mát. 9:36-38) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lílọ́ sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù kọ́kọ́ ba Ananíà lẹ́rù, kí ló ràn án lọ́wọ́ láti yí èrò rẹ̀ pa dà? (Ìṣe 9:13-15) Báwo ni ọ̀nà tó gbà bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ ṣe fi hàn pé ó ní èrò tó dáa nípa rẹ̀? (Ìṣe 9:17) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ní èrò tó dáa nípa àwọn èèyàn tá a ń wàásù fún ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa? Báwo ni níní èrò tó dáa ṣe lè mú ká túbọ̀ kẹ́sẹ járí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí níní èrò tó dáa ti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn so èso rere.
10 min: Bá A ṣe Lè Lo Ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó. Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn tàbí alàgbà míì sọ àsọyé yìí tó dá lórí ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 2 àti 7.
10 min: “Báwo Ni Wọn Yóò Ṣe Gbọ́?”a
Orin 38
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.