ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/02 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 13
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 20
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 27
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 3
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 5/02 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 13

Orin 37

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ May 15 àti Jí! June 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, fi hàn bí a ṣe lè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ tó lè bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, irú bí “Ọwọ́ mi dí.”—Wo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ewé 11.

15 min: “Kí La Lè Rí Kọ́ Nínú Wọn?”a Jẹ́ kí gbogbo àwọn ará mọ ìjẹ́pàtàkì gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà ní àwọn àkókò ìṣòro.

15 min: “Àpéjọ Àgbègbè ‘Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run’ tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Yóó Ṣe ní Ọdún 2002.”b Kí akọ̀wé jíròrò ìpínrọ̀ 1 sí ìpínrọ̀ 9. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, sọ ìlú tí a yan ìjọ yín sí láti lọ ṣe àpéjọ náà àti déètì tí yóò jẹ́.

Orin 219 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 20

Orin 13

9 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.

18 min: “Àpéjọ Àgbègbè ‘Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run’ tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Yóó Ṣe ní Ọdún 2002.”c Kí alàgbà kan jíròrò ìpínrọ̀ 10 sí ìpínrọ̀ 19. Ran gbogbo ará lọ́wọ́ láti mọrírì ìdí tó fi yẹ ká kíyè sára nípa bí a ṣe máa hùwà láwùjọ.

18 min: “Ṣé O Ti Di ‘Géńdé’ Kristẹni?” Alàgbà ni kó sọ ọ̀rọ̀ yìí, tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ August 15, 2000, ojú ìwé 26 sí 29.

Orin 169 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 27

Orin 208

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù May sílẹ̀. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, jẹ́ kí akéde kan tó jẹ́ àgbàlagbà ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ June 1 lọni, kí ọ̀dọ́ akéde kan sì fi hàn bí a ṣe lè fi Jí! June 8 lọni. Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, ṣàlàyé bí a ṣe lè fìrọ̀rùn lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan nínú ìgbékalẹ̀ náà.

15 min: “Ṣé Ìjọ Yín Ní Ìpínlẹ̀ Tó Tóbi Gan-an?” Àsọyé àti ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwùjọ. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kí ó bójú tó o. (Àwọn ìjọ tí ìpínlẹ̀ wọn kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ lè jíròrò àpilẹ̀kọ náà, “Lo Àkókò Rẹ Lọ́nà Gbígbéṣẹ́,” èyí tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1999.) Jẹ́ kí àwọn ará mọ bí ìpínlẹ̀ ìjọ yín ṣe gbòòrò tó, àti bí apá tí ẹ ṣe nínú rẹ̀ lọ́dún tó kọjá ṣe pọ̀ tó. Ṣàlàyé bí wọ́n ṣe lè lo àwọn àbá tá a pèsè. Sọ àwọn ètò tí ìjọ ń ṣe láti lọ ṣiṣẹ́ láìpẹ́ láwọn ìpínlẹ̀ tí ẹ kì í ṣe déédéé.

18 min: “Ṣé Ò Ń Lo Ìwé Pẹlẹbẹ Béèrè Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” (Kí gbogbo àwọn ará mú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù January 2002 lọ́wọ́ nígbà ìjíròrò yìí.) Bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò yìí nípa jíjẹ́ kí akéde kan tó ti múra sílẹ̀ dáadáa ṣàṣefihàn bí a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan nípa lílo àpẹẹrẹ tó wà ní ìpínrọ̀ kẹta. Lẹ́yìn náà, sọ àwọn kókó inú ìwé pẹlẹbẹ náà, kó o sì ṣàlàyé bí a ṣe ṣètò rẹ̀ lọ́nà tó dára gan-an fún bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Sọ bó ṣe ṣàǹfààní tó láti máa ṣàyẹ̀wò àwọn ìgbékalẹ̀ tá a dámọ̀ràn nínú àkìbọnú January 2002. Ní kí àwùjọ sọ èwo nínú àwọn àbá náà ni wọ́n ti lò tó sì gbéṣẹ́ fún wọn. Kádìí rẹ̀ nípa títún àṣefihàn ìṣáájú ṣe.

Orin 93 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 3

Orin 178

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ṣètò pé kí àwọn akéde kan sọ àwọn ìbùkún tí wọ́n rí gbà nínú ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú ọ̀nà déédéé ní oṣù March, April tàbí May. Jíròrò Àpótí Ìbéèrè.

15 min: Bí Àwọn Ìtẹ̀jáde Society Ṣe Lo Àwọn Ìtumọ̀ Bíbélì Mìíràn. Àsọyé ṣókí, lẹ́yìn náà ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Bíbélì ni ọlá àṣẹ wa. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló jẹ́ a sì gbọ́dọ̀ máa lò ó gan-an nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ó lé ní ọgọ́ta ọdún tá a fi lo ẹ̀dà ìtumọ̀ Bíbélì King James Version, ìtumọ̀ Bíbélì Douay Version ti àwọn Roman Kátólíìkì, tàbí àwọn ìtumọ̀ èyíkéyìí tọ́wọ́ wa bá sáà ti tẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà àtàwọn ète rẹ̀. Láfikún sí i, àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ yìí la tún ń lò nígbà yẹn láti fi polongo òtítọ́ nípa ipò táwọn òkú wà, bí Ọlọ́run àti Jésù ṣe jẹ́ síra wọn, àti ìdí tó fi jẹ́ pé kìkì agbo kékeré ló ń lọ sí ọ̀run. Àwọn olóye èèyàn tún mọ̀ pé a ṣì máa ń lo ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn nínú iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere tá à ń ṣe karí ayé. Ìdí rèé tí wàá fi rí àwọn ìkékúrú orúkọ àwọn ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn, irú bí AS, AT, By, ED, Int, KJ, Kx, JB, JP, NE, Ro, TEV, Yg, tí a tọ́ka sí nínú àwọn ìwé wa. Àmọ́ o, láti ọdún 1961 wá, a tún ti ń gbádùn lílo Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, èyí tó ní àwọn ọ̀rọ̀ tó bá àkókò mu, tí ìtumọ̀ rẹ̀ péye tó sì rọrùn láti kà. Sọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún, èyí tá a mẹ́nu kàn nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ October 1, 1997 ojú ìwé 16, ìpínrọ̀ 2, àti ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 15. Nípa lílo àwọn ìtọ́ka tí a ṣe sí àwọn ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn nínú ìwé “Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye” ní ojú ìwé 39 sí 43, ní kí àwùjọ sọ bí fífi oríṣiríṣi ìtumọ̀ wéra ṣe lè ṣèrànwọ́ láti túdìí àṣírí bí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ṣe jẹ́ ẹ̀kọ́ èké àti láti fi òtítọ́ nípa orúkọ Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn.

15 min: “Ìgbàgbọ́ Wa Ń Sún Wa Ṣe Àwọn Iṣẹ́ Rere.”d Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 2, fọ̀rọ̀ wá Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ onítara lẹ́nu wò ní ṣókí. Ní kí akéde náà sọ bí wíwàásù fún àwọn ẹlòmíràn ṣe ń fi ìgbàgbọ́ tí ó ní hàn tó sì ń mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára sí i.

Orin 56 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́