Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Kí àwọn akéde sọ fún àwọn onílé pé wọ́n lè fi ọrẹ àtinúwá ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ wa kárí ayé bí wọ́n bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Níbi tí ẹnì kan bá ti fi ìfẹ́ hàn nígbà ìpadàbẹ̀wò, jẹ́ kí onítọ̀hún wà lára àwọn tí wàá máa mú ìwé ìròyìn lọ fún déédéé. Fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni, kí o sì ní in lọ́kàn pé o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. June: Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Bí onílé bá ti ní àwọn ìwé wọ̀nyí, fi ìwé pẹlẹbẹ kan tó bá àkókò yẹn mu tí ìjọ ní lọ́wọ́ lọ̀ ọ́. July àti August: A lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tó tẹ̀ lé e yìí lọni: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye Lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú?, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” A tún lè fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ wọ̀nyí, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, àti Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, lọni níbi tó bá ti bá àkókò mu.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní June 1 tàbí bí ó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó ti oṣù tó ń bọ̀.
◼ Bí alábòójútó olùṣalága kò bá fi rí ẹ̀dà Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù kan pàtó títí fi di ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù tó ṣáájú oṣù náà, kí ó tètè kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́.