ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/01 ojú ìwé 7
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àkànṣe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àkànṣe
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mú Agbára Ìmòye Rẹ Dàgbà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe ti Ọdún 2010
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àkànṣe
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 2/01 ojú ìwé 7

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àkànṣe

“Ẹ Dàgbà Di Géńdé Nínú Agbára Òye” ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní oṣù kẹ́ta ọdún 2001. (1 Kọ́r. 14:20) Kí ló dé tó fi ṣe pàtàkì pé ká lọ? Inú ayé kan tó kún fún ìwà ibi là ń gbé. Láti yẹra fún èyí, a gbọ́dọ̀ mú agbára òye wa nípa tẹ̀mí dàgbà ká lè fi rere ṣẹ́gun búburú. Ohun tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe yìí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe nìyẹn.

Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ìpàdé náà, alábòójútó àyíká yóò jíròrò àsọyé tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “Àwọn Ìrànwọ́ fún Dídi Géńdé Nínú Òye Bíbélì.” Yóò ṣàlàyé fún wa nípa bí a ṣe lè di ẹni tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ Kristẹni. Olùbánisọ̀rọ̀ tí a rán wá yóò ṣàlàyé bí fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ní ti gidi ti ṣe kókó fún mímú agbára ìlóye tó mú hánhán dàgbà, bí yóò ṣe máa sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Dáàbò Bo Ipò Tẹ̀mí Rẹ Nípa Kíkọ́ Agbára Ìmòye Rẹ.”

Àwọn ọ̀dọ́ pẹ̀lú gbọ́dọ̀ mú agbára òye wọn dàgbà. A óò jíròrò èyí nínú apá tí a pè ní, “Ìdí Tí A Fi Ní Láti Jẹ́ Ìkókó Ní Ti Ìwà Búburú” àti “Àwọn Èwe Tó Ń Sapá Láti Ní Òye Nísinsìnyí.” Gbọ́ bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń sọ ohun tí wọ́n ń ṣe láti máa fún ara wọn lágbára nípa tẹ̀mí, kí wọ́n má bàa ṣe àtojúbọ̀ èyíkéyìí nípa àwọn ìgbòkègbodò burúkú ayé yìí, tí wọ́n sì ń yẹra fún wàhálà.

Báwo la ṣe lè rí ayọ̀ gíga jù lọ ní ìgbésí ayé? Olùbánisọ̀rọ̀ tí a rán wá yóò ṣàlàyé èyí nínú àsọyé tí yóò kẹ́yìn tó ní àkọlé náà, “Jàǹfààní Nínú Fífi Àwọn Ìlànà Bíbélì Sílò Tòyetòye.” Yóò sọ àwọn àpẹẹrẹ tó ń fi hàn bí fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro, láti ṣe àwọn ìpinnu, àti láti jàǹfààní ní tòótọ́ látinú ohun tí Jèhófà ń kọ́ wa.

Kí àwọn tó fẹ́ fàmì ìyàsímímọ́ wọn fún Ọlọ́run hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi ní àpéjọ yìí tètè sọ fún alábòójútó olùṣalága bó bá ti ṣeé ṣe kó yá tó. Sàmì sí déètì ọjọ́ àpéjọ àkànṣe yín ní gbàrà tí wọ́n bá ti ṣèfilọ̀ rẹ̀, kí o sì ṣe àwọn ìwéwèé tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ láti jàǹfààní nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó níye lórí yìí. Má ṣàìgbọ́ apá èyíkéyìí nínú àpéjọ àkànṣe yìí o! Yóò fún ọ lágbára láti fara da ètò búburú yìí, kí o sì máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́