Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe ti Ọdún 2010
1. (a) Kí ni díẹ̀ lára ẹṣin ọ̀rọ̀ àwọn àpéjọ àkànṣe tá a gbé karí Ìwé Mímọ́ tá a ti ṣe sẹ́yìn? (b) Ǹjẹ́ àwọn ohun pàtó kan wà nínú àpéjọ àkànṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn tó ti ràn ẹ́ lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?
1 Díẹ̀ lára àkọlé àwọn àpéjọ àkànṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn ni: “Rí Àrídájú Awọn Ohun Tí Wọn Ṣe Pataki Jù,” “Dídúró Gírígírí Gẹgẹbi Agbo Kan,” “Máa Báa Nìṣó Ní Jíjẹ́rìí sí Òtítọ́” àti “Amọ̀ Ni Wá, Jèhófà Ló Ń Mọ Wá.” (Fílí. 1:9, 10; 1:27; Jòh. 18:37; Aísá. 64:8) Ǹjẹ́ ò ń fojú sọ́nà fún àpéjọ àkànṣe ti ọdún 2010? Ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àkànṣe náà ni: “Àkókò Tí Ó Ṣẹ́ Kù Ti Dín Kù.” A gbé e ka ìwé 1 Kọ́ríńtì 7:29.
2. Báwo la ṣe lè máa fojú sọ́nà fún àpéjọ yìí?
2 Gbàrà tí wọ́n bá ti ṣèfilọ̀ ọjọ́ tí ìjọ yín máa ṣe àpéjọ àkànṣe ni kó o ti bẹ̀rẹ̀ sí fìtara múra sílẹ̀ fún un. Káwọn ọmọ wọn lè máa wọ̀nà fún ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe àpéjọ, àwọn òbí kan máa ń sàmì sí ọjọ́ náà lórí kàlẹ́ńdà, wọ́n á sì kọ ohun tí wọ́n máa nílò, wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí í ka iye ọjọ́ tó kù kí ọjọ́ náà pé. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé yín, ẹ lè ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ohun tẹ́ ẹ kọ sílẹ̀ láwọn àpéjọ àkànṣe tẹ́ ẹ ti ṣe kọjá. Ẹ tún lè múra ọkàn yín sílẹ̀ fún àpéjọ yìí, nípa ṣíṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 13 sí 16, kẹ́ ẹ lè túbọ̀ “fiyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.”—Lúùkù 8:18.
3. Báwo la ṣe lè jàǹfààní kíkún látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà?
3 Fi Ohun Tó Ò Ń Kọ́ Sílò: Ohun tí ọ̀pọ̀ sábà máa ń sọ lẹ́yìn àpéjọ ni pé, “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí mà kàmàmà o!” Òótọ́ sì ni, torí pé àwọn àpéjọ wa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpèsè yanturu tá à ń rí gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Òwe 10:22) Kí ohun tó ò ń gbọ́ tó lè ṣe ẹ́ láǹfààní, o gbọ́dọ̀ máa ṣàṣàrò lórí rẹ̀ kó o sì fi í sọ́kàn. (Lúùkù 8:15) Nígbà tẹ́ ẹ bá ń pa dà sílé láti àpéjọ yìí, ẹ jíròrò ohun tẹ́ ẹ kọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé tàbí pẹ̀lú àwọn tẹ́ ẹ bá jọ wà nínú ọkọ̀. Ẹ sọ̀rọ̀ nípa àfojúsùn tí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ní àti àwọn ohun tó máa ràn yín lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ yín. Bẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, èyí á jẹ́ kẹ́ ẹ lè máa báa nìṣó láti jàǹfààní látinú àpéjọ náà lẹ́yìn tí àpéjọ náà bá ti parí.—Ják. 1:25.
4. Àǹfààní àkànṣe wo la máa jẹ látinú àpéjọ yìí?
4 Inú wa sábà máa ń dùn gan-an nígbà tá a bá gba ẹ̀bùn kan tó bọ́ sákòókò. Ṣé ara wa ti wà lọ́nà láti mọ ohun tí Jèhófà ní nípamọ́ fún wa nígbà àpéjọ àkànṣe wa tó ń bọ̀? Ó dá wa lójú pé ó máa wúlò fún wa ní gbogbo ọ̀nà. A mọ̀ pé ẹ̀bùn tá a nílò gan-an ni Baba wa ọ̀run, Jèhófà máa fún wa, ìyẹn ìṣírí àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ táá mú ká lè ṣe iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́.—2 Tím. 4:2; Ják. 1:17.