Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 28
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 28
Orin 84
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv orí 14 ìpínrọ̀ 15 sí 19, àpótí tó wà lójú ìwé 167
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóṣúà 12-15
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 35
5min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Bó O Ṣe Lè Dáhùn. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ, tó dá lórí ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín láti fi bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀. Ṣe àṣefihàn kan tó dá lórí ọ̀kan lára ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn máa ń sọ láti fi bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀.—Wo ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 8 sí 12.
10 min: Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Sọ ọjọ́ tó kàn tẹ́ ẹ yà sọ́tọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn. Kí làwọn ohun tẹ́ ẹ ti gbé ṣe ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín lọ́jọ́ tẹ́ ẹ yà sọ́tọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ní kí aṣáájú-ọ̀nà tàbí akéde kan sọ ìrírí kan tàbí kó ṣe àṣefihàn ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tẹ́ ẹ rí i pé ó gbéṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín.
10 min: Ìwé Tá A Máa Lò Lóṣù January. Ní ṣókí, sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó inú ìtẹ̀jáde tá a máa lò. Kí ìwọ àti akéde kan jíròrò àwọn ọ̀nà téèyàn lè gbà fi ìtẹ̀jáde náà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà àìjẹ́bí-àṣà. Rọ àwọn ará pé kí wọ́n fi ṣe àfojúsùn wọn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lóṣù yìí.
Orin 193