ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/09 ojú ìwé 3
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
km 12/09 ojú ìwé 3

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣàtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní December 28, 2009.

1. Báwo ni àwa Kristẹni lónìí ṣe lè fi ìlànà tó wà nínú Diutarónómì 14:1 sílò? [w05 1/1 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 2; w04 9/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 5]

2. Báwo la ṣe lè fi ìlànà tó wà nínú Diutarónómì 20:5-7 sílò nínú ìjọ Kristẹni lónìí? [w04 9/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 6]

3. Báwo ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣe yàtọ̀ sáwọn orílẹ̀-èdè míì, tó bá dọ̀rọ̀ ogun jíjà? (Diu. 20:10-15, 19, 20; 21:10-13) [cl ojú ìwé 134 sí 135, ìpínrọ̀ 17]

4. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣiṣẹ́ sin Jèhófà pẹ̀lú ìdùnnú ọkàn-àyà? (Diu. 28:47) [w95 1/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 4 sí 5]

5. Báwo làwọn òbí ṣe lè jàǹfààní látinú àfiwé tó ṣàpèjúwe ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún Ísírẹ́lì, èyí tó wà nínú Diutarónómì 32:9, 11, 12? [w01 10/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 7 sí 9]

6. Báwo ló ṣe yẹ ká lóye àwọn ọ̀rọ̀ aṣinilọ́nà tí Ráhábù fi tan àwọn ìránṣẹ́ ọba tó ń lépa àwọn amí náà? (Jóṣ. 2:4, 5) [w93 12/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 1]

7. Kí la rí kọ́ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú Jóṣúà 3:15, 16? [w04 12/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 5]

8. Kí la rí kọ́ nípa ọ̀nà tí Jóṣúà gbà bójú tó ọ̀ràn Ákáánì tó jalè? (Jóṣ. 7:20-25) [w04 12/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 4]

9. Báwo ni ohun tó wà nínú Jóṣúà 9:22, 23 ṣe fi hàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kì í yẹ̀? [w04 12/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 3]

10. Ìṣírí wo ni àpẹẹrẹ Kálébù fún wa? (Jóṣ. 14:8, 10-12) [w04 12/1 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 2; w93 5/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 1]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́