Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 4
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 4, 2010
Orin 69
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóṣúà 16-20
No. 1: Jóṣúà 17:1-10
No. 2: Ìbatisí Jẹ́ Ohun Tí À Ń Béèrè Lọ́wọ́ Kristẹni (td 17A)
No. 3: Ìdí Tí “Ẹni Tó Ń Tiro Lórí Èrò Méjì Tí Ó Yàtọ̀ Síra” Kò Fi Lè Wu Ọlọ́run (1 Ọba 18:21)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 32
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Lo Ìbéèrè Láti Mú Kí Ẹ̀kọ́ Rẹ Wọ Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́kàn. Àsọyé tá a gbé ka ìsọ̀rí tó gbẹ̀yìn lójú ìwé 238 àti ìsọ̀rí tó wà lójú ìwé 239 nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Máa Lo Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Lóde Ẹ̀rí. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. A gbé e ka ìpínrọ̀ mẹ́ta tó wà lójú ìwé 100 àti 101 nínú ìwé A Ṣètò Wa, lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Bó O Ṣe Lè Máa Lo Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́.” Ní kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn tàbí alàgbà míì fún àwọn ará láwọn àbá lórí bá a ṣe lè lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa dáadáa tá ò sì ní máa fi wọ́n ṣòfò.
Orin 162