Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí àwọn ọmọdé bá wà nínú ilé náà, kẹ́ ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. January: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ fún un ní ìwé èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Ìwé míì tá a tún lè lò gẹ́gẹ́ bí àfidípò ni ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. February: Ẹ lè lo Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé tàbí Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. March: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Kí àwọn akéde ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí onílé bá gba ìtẹ̀jáde yìí tàbí tó bá ti ní in lọ́wọ́.
◼ Ọjọ́ Sunday April 17 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2011, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Ìdí tá a fi tètè ṣe ìfilọ̀ yìí ni pé, a fẹ́ kẹ́ ẹ tètè bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò ibòmíì tẹ́ ẹ máa lò tó bá jẹ́ pé àwọn ìjọ tẹ́ ẹ jọ ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba pọ̀ débi pé kò ní sáyè láti ṣe tiyín ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.
◼ A máa tó fi ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2010 ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ìjọ tó ń ṣe kòkáárí ìwé gbígbà. Ọ̀pọ̀ jù lọ ìjọ ló máa rí i gbà lédè tí wọ́n fi ń ṣe ìpàdé. Tí wọ́n bá ń sọ àwọn èdè míì ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín tẹ́ ẹ sì fẹ́ ká fi ìwé ìkésíni ránṣẹ́ sí yín láwọn èdè yẹn, kẹ́ ẹ tètè béèrè fún un nípa lílo fọ́ọ̀mù tá a fi ń béèrè ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn Literature Request Form (S-14). Ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi wà ní àwọn èdè wọ̀nyí: Ẹ́fíìkì, Faransé, Gẹ̀ẹ́sì, Haúsá, Ìgbò, Ísókó, Tífí àti Yorùbá.