Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Ó wúni lórí láti rí i pé àwọn akéde tí iye wọ́n jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìn-dín-láàádọ́jọ ó lé ọgbọ̀n-dín-nírínwó ó lé mẹ́ta [292,373] ló ròyìn lóṣù July ọdún 2009. Èyí fi ìpín mẹ́ta àti ẹ̀sún méje nínú ọgọ́rùn-ún ju ìpíndọ́gba àwọn akéde tó ròyìn lóṣù July ọdún tó kọjá lọ. A gbóríyìn fún yín torí iṣẹ́ rere tí ẹ̀ ń ṣe, a sì fẹ́ kó dá yín lójú pé “ẹ̀san wà fún ìgbòkègbodò yín.”−2 Kíró. 15:7.