Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun
A gbé ẹṣin ọ̀rọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe fún ọdún iṣẹ́ ìsìn wa tuntun karí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó lágbára. Ẹṣin ọ̀rọ̀ náà ni: “Ẹ Fi Ara Yín Sábẹ́ Ọlọ́run—Ẹ Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù.” (Ják. 4:7) Ìtọ́sọ́nà tó yè kooro mà lèyí jẹ́ láwọn àkókò oníwàhálà tá a wà yìí o! Pípa tí à ń pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ ń mú kí Sátánì dojú ìjà kọ wá. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí yóò kọ́ wa ní bá a ṣe lè dúró gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù èyí tó lè ri ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣúra tẹ̀mí tá a máa rí gbà ní àpéjọ yìí?
Alábòójútó àyíká yóò jẹ́ ká mọ bí “Fífi Ìtẹríba Lọ́nà ti Ọlọ́run Hàn Gẹ́gẹ́ Bí Mẹ́ńbà Ìdílé” ṣe lè fún ìdílé lókun láti kojú àwọn pákáǹleke inú ayé. Àsọyé tí olùbánisọ̀rọ̀ tí a rán wá máa kọ́kọ́ sọ lọ́jọ́ náà, “Ohun Tí Kíkọ Ojú Ìjà sí Èṣù Túmọ̀ Sí,” yóò ṣàlàyé ìdí tá a fi ní láti fi ìgboyà gbégbèésẹ̀ láti dènà èrò tí Sátánì ń pa láti ba ipò tẹ̀mí wa jẹ́, àti bí a ṣe lè ṣe é. Apá méjì la dìídì ṣètò fún àwọn èwe, nítorí àwọn pẹ̀lú gbọ́dọ̀ wà lójúfò sí àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Èṣù. Ọ̀pọ̀ Kristẹni tó ti dàgbà báyìí ni kò tẹ̀ lé àwọn ohun ti ayé nígbà tí wọ́n wà ní kékeré. A óò gbádùn gbígbọ́ díẹ̀ lára àwọn ìrírí tí wọ́n ní.
Ó pọn dandan pé kí gbogbo ẹni tó wà nínú àwùjọ ẹ̀dá èèyàn tẹrí ba fún ọlá àṣẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, àsọyé tí olùbánisọ̀rọ̀ tá a rán wá yóò sọ kẹ́yìn máa ṣàlàyé ọ̀nà mẹ́rin tí ìtẹríba wa fún Ọlọ́run ti gbọ́dọ̀ fara hàn: (1) fún ìjọba, (2) nínú ìjọ, (3) níbi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, àti (4) nínú agbo ìdílé. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí mà kúkú gbéṣẹ́ o!
Kí àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi ní àpéjọ àkànṣe yìí tètè sọ fún alábòójútó olùṣalága bó bá ti lè ṣeé ṣe kó yá tó. Ó yẹ kí gbogbo wa sàmì sí déètì yìí lórí kàlẹ́ńdà wa, ká sì wéwèé láti wà níbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Àwọn ìbùkún ayérayé la ó máa gbà bá a bá ń bá a nìṣó láti máa fi ara wa sábẹ́ Jèhófà títí láé.