Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù February: Ìṣípayá-Òtéńté Rẹ̀ Títóbilọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, tàbí ìwé olójú ewé 192 mìíràn tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ ju èyí tá a dárúkọ yìí tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A ó sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Níbi tí wọ́n bá ti fi ìfẹ́ hàn fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni, kí o sì ní in lọ́kàn pé o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.
◼ Nígbà tí àwọn akéde bá ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ tí a kò pín fúnni, wọ́n lè fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀ lọni. Wọ́n lè fi ìtẹ̀jáde èyíkéyìí mìíràn lọni bí onílé bá ti ní àwọn ìtẹ̀jáde méjì wọ̀nyí tẹ́lẹ̀. Kí gbogbo wọn kó onírúurú ìwé àṣàrò kúkúrú dání nítorí àwọn kò-sí-nílé tàbí àwọn mìíràn tí kò gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Kí wọ́n sapá láti padà lọ síbi tí wọ́n bá ti fi ìfẹ́ hàn, pàápàá níbi tí àwọn ìjọ tó wà nítòsí bá ti lè dé àwọn ìpínlẹ̀ tí a kò pín fúnni.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní March 1, tàbí bó bá ti ṣe lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó tó tẹ̀ lé e.
◼ Ní àwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe tí a óò ṣe lọ́dún 2002, a ó ṣètò àyè ìjókòó lọ́tọ̀ fún àwọn adití ní àwọn àyíká tí a to orúkọ wọn sísàlẹ̀ yìí, níbi tí a ó ti túmọ̀ gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ sí èdè àwọn adití ní ìlànà ti Amẹ́ríkà:
Akabo (EE-08) July 6-7 àti March 31
Àkúrẹ́ (WE-12) May 11-12 àti August 25
Badagry (WE-23) October 5-6 àti May 19
Enugu (EE-17) August 31-September 1 àti May 4
Igwuruta Ali (EE-22) February 9-10 àti June 29
Iléṣà (WE-15) March 23-24 àti July 7
Kàdúná (NE-01b) March 30-31 àti July 27
Ọ̀tà (WE-07) April 20-21 àti August 17
Ùbogò (ME-07) June 8-9 àti September 8
◼ Kí akọ̀wé àti alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ṣàyẹ̀wò ìgbòkègbodò gbogbo aṣáájú ọ̀nà déédéé. Bó bá ṣòro fún ẹnikẹ́ni lára wọn láti ní iye wákàtí tí à ń béèrè, kí àwọn alàgbà ṣètò láti ràn án lọ́wọ́. Fún ìdámọ̀ràn, ẹ ṣàtúnyẹ̀wò àwọn lẹ́tà ọdọọdún náà, S-201, tí Society kọ. Ẹ tún wo ìpínrọ̀ 12 sí 20 nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1986.
◼ Ṣọ́ra fún àwọn ètò gbájú-ẹ̀ tó ti ń tàn kálẹ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì àti nípasẹ̀ lẹ́tà kíkọ. Ohun tí àwọn oníjìbìtì wọ̀nyí fi ń bojú ni pé àwọn fẹ́ kówó jọ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí. Nígbàkigbà tí ipò nǹkan bá ń béèrè pé kí a dá ìgbìmọ̀ kan sílẹ̀ láti pèsè ìrànwọ́ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a óò jẹ́ kí àwọn arákùnrin tí wọ́n tóótun gbọ́. Kí a fi irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́ sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State.
◼ Àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn fún sáà Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2002 ni a óò sọ ní ọjọ́ Sunday, April 14. Àkọlé àsọyé náà ni, “Ẹ Máa Fi ‘Ọjọ́ Ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀’ Náà Sọ́kàn Pẹ́kípẹ́kí!” A óò pèsè ìlapa èrò fún àsọyé. Kí àwọn ìjọ tí wọ́n bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọ àkànṣe ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ àkànṣe àsọyé yìí ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Kí ìjọ kankan má sọ àkànṣe àsọyé yìí ṣáájú April 14, 2002 o.
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà:
Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú? (Ìwé àṣàrò kúkúrú No. 25) —Àbúà, Ègùn, Ẹ̀dó, Ẹ́fíìkì, Faransé, Gẹ̀ẹ́sì, Haúsá, Ìgalà, Ìgbò, Ísókó, Kánà, Tífí, Ùròbò, àti Yorùbá
Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì —Ègùn, Ẹ́fíìkì, Faransé, Gẹ̀ẹ́sì, Ìgbò, àti Yorùbá