ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/02 ojú ìwé 3-6
  • “Wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ní Kíkún”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ní Kíkún”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Jẹ́rìí Kúnnákúnná sí Ìhìn Rere”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ṣé A Óò Ṣe É Lẹ́ẹ̀kan Sí I?—Ìpè Mìíràn fún Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Máa Bá A Nìṣó Láti Sọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Jèhófà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • A Ń Fẹ́—30,000 Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 2/02 ojú ìwé 3-6

“Wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ní Kíkún”

1 Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lo mọrírì ohun dídára kan tí ẹnì kan fún ọ, ìṣesí rẹ kò ha ní fi èyí hàn bí? Dájúdájú ìṣarasíhùwà rẹ ló máa fi hàn pé o moore! Kíyè sí bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìmọrírì rẹ̀ hàn fún oore àti inú rere onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà nawọ́ rẹ̀ sí aráyé. Ó fi tìtaratìtara sọ pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run fún ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ aláìṣeé-ṣàpèjúwe”! Kí ni “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́” náà ní nínú? Ìyẹn ni gbogbo “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run títayọ ré kọjá” tí ó ti fi hàn sí wa. Èyí tó tóbi jù lọ nínú gbogbo wọn ni ẹ̀bùn Ọmọ òun fúnra rẹ̀ tó fi ṣe ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ wa.—2 Kọ́r. 9:14, 15; Jòh. 3:16.

2 Ǹjẹ́ Pọ́ọ̀lù kàn ń fẹnu lásán dúpẹ́ ni? Rárá o! Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ló gbà fi ìmọrírì rẹ̀ àtọkànwá hàn. Ire tẹ̀mí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jẹ ẹ́ lọ́kàn, ó sì fẹ́ ṣe ohun tó bá lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní inú rere onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Pọ́ọ̀lù sọ nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé: “Ní níní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún yín, ó dùn mọ́ wa nínú jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ọkàn àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ di olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún wa.” (1 Tẹs. 2:8) Yàtọ̀ sí pé Pọ́ọ̀lù ran àwọn tí wọ́n ti jẹ́ apá kan ìjọ náà lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà ìgbàlà, ó tún wàásù ìhìn rere náà láìṣàárẹ̀, ó rìnrìn àjò ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà lórí ilẹ̀ àti lórí omi láti lè wá “àwọn tí wọ́n . . . ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” rí. (Ìṣe 13:48) Ìmọrírì jíjinlẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù ní fún gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún un sún un “láti wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní kíkún.”—Kól. 1:25.

3 Ṣé kò yẹ kí ìmọrírì wa fún gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa sún wa láti pèsè ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí fún àwọn tí wọ́n nílò rẹ̀ nínú ìjọ wa? (Gál. 6:10) Ǹjẹ́ kò yẹ kí èyí sún wa láti nípìn-ín ní kíkún bó bá ti lè ṣeé ṣe tó nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba náà jákèjádò ìpínlẹ̀ wa?—Mát. 24:14.

4 Àǹfààní Kan Tá A Ní Láti Fi Ìmọrírì Wa Hàn: Lọ́dọọdún, Ìṣe Ìrántí ikú Kristi máa ń fún wa ní àǹfààní àkànṣe láti fi ìmọrírì wa hàn fún ohun tí Jèhófà àti Jésù ti ṣe fún wa. Èyí kì í kàn ṣe ìpàdé mìíràn kan ṣáá tàbí ayẹyẹ ìrántí ṣákálá kan. Jésù sọ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Ìgbà Ìṣe Ìrántí ikú Kristi jẹ́ àkókò kan tó yẹ ká fi ronú jinlẹ̀ lórí irú ẹni tí Jésù jẹ́. Ó jẹ́ àkókò kan fún wa láti mọ̀ pé ó wà láàyè àti pé ó ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ lónìí, pẹ̀lú ògo àti ipò ọba tí a fi fún un nítorí ìgbésí ayé ìṣòtítọ́ rẹ̀ àti ìrúbọ rẹ̀. Ìgbà ayẹyẹ yìí tún jẹ́ àǹfààní kan láti fi ìtẹríba wa hàn fún ipò orí Kristi bí ó ti ń darí àwọn ìgbòkègbodò ìjọ Kristẹni. (Kól. 1:17-20) Gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run ló yẹ kó fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi. Lọ́dún yìí, a óò ṣe é lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ ní Thursday, March 28, 2002.

5 Nítorí pé a sapá taápọntaápọn ṣáájú ká tó ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí lọ́dún tó kọjá, iye àwọn èèyàn tó wá pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, wọ́n jẹ́ 639,237 ní Nàìjíríà. Báwo làwọn tó máa wá lọ́dún yìí ṣe máa pọ̀ tó? Èyí wà lọ́wọ́ bá a bá ṣe ‘ṣiṣẹ́ kára, tí a sì tiraka,’ láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó láti wá.—1 Tím. 4:10.

6 Yàtọ̀ sí pé a máa lọ síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, a tún lè mú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá wa pọ̀ sí i. Láìsí àní-àní, ẹgbẹẹgbàárùn-ún àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa ni yóò ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ọdún kọ̀ọ̀kan láti ọdún márùn-ún sẹ́yìn, ìpíndọ́gba àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tí a ní jẹ́ 13,864 ní sáà Ìṣe Ìrántí, ìyẹn oṣù March sí May. Ṣé o lè ṣètò àwọn ìgbòkègbodò rẹ kó o lè gbádùn àǹfààní ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní ọdún yìí? Èyí á jẹ́ ọ̀nà kan tó dára fún ọ láti fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn fún ìpèsè onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run fún wa, ìyẹn ẹbọ Kristi. Kí ó dá ọ lójú pé ìbùkún Jèhófà á wà lórí rẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìrírí tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí ti fi hàn.

7 Arábìnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó ń gba ọ̀pọ̀ àkókò kọ̀wé nípa ìrírí ara rẹ̀ nígbà tó ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March tó kọjá. Ó sọ pé: “Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 2001 fún olúkúlùkù ẹni tí ipò rẹ̀ bá lè gbé e níṣìírí láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní sáà Ìṣe Ìrántí. Níwọ̀n bí oṣù March ti ní Saturday márùn-ún, èyí bá ìtòlẹ́sẹẹsẹ mi mu gẹ́lẹ́. Ni mo bá pinnu láti fi ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ sílẹ̀.” Nígbà tó máa bẹ̀rẹ̀ lóṣù yẹn, ó gbé ohun tó fẹ́ láti lépa kalẹ̀ fún ara rẹ̀, ìyẹn ni sísapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Ṣé ó ṣàṣeyọrí? Ó kúkú ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ti ń sapá láti bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tó ti wàásù fún wákàtí méjìléláàádọ́ta nínú oṣù yẹn! Kí ló sọ lẹ́yìn gbogbo èyí? Ó sọ pé: “Àwọn ìbùkún àgbàyanu wà tá a máa gbà bá a bá lè ṣe àfikún ìsapá.”

8 Àwọn àǹfààní wo ni ìdílé kan tí gbogbo wọn lápapọ̀ ń ṣe aṣáájú ọ̀nà lè gbádùn? Ìdílé kan tí gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rin tí wọ́n ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù April tó kọjá rí i pé ó jẹ́ oṣù mánigbàgbé. Ìyá wọn sọ pé: “Ayọ̀ tá a máa ń fojú sọ́nà fún láti ní lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan kò ṣeé fẹnu sọ, níwọ̀n bí a ti ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ pa pọ̀! Bá a ṣe ń jíròrò àwọn ìgbòkègbodò wa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan máa ń jẹ́ kí àkókò oúnjẹ alẹ́ wa lárinrin gan-an.” Ọmọ wọn ọkùnrin sọ pé: “Mo gbádùn bí mo ṣe ń bá Dádì ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí láàárín ọ̀sẹ̀, ní àkókò tó jẹ́ pé ibi iṣẹ́ ni wọ́n sábà máa ń wà.” Bàbá wọn fi kún un pé: “Gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé, inú mi dùn gan-an pé gbogbo wa la jọ ṣe iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ ní àkókò tá a wà yìí.” Ṣé ìdílé tìrẹ náà lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà pa pọ̀? Kí ló dé tí gbogbo yín ò kúkú jọ jíròrò rẹ̀ pa pọ̀, kẹ́ ẹ sì wò ó bó bá lè ṣeé ṣe fún gbogbo agboolé yín láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní sáà Ìṣe Ìrántí yìí?

9 Ǹjẹ́ A Lè Mú Kí Oṣù March Jẹ́ Oṣù Tí A Tíì Ṣe Dáadáa Jù Lọ? Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2000, Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa béèrè ìbéèrè yìí: “Ǹjẹ́ A Lè Mú Kí April 2000 Jẹ́ Oṣù Tí A Tíì Ṣe Dáadáa Jù Lọ?” Báwo la ṣe dáhùn padà? A ṣe dáadáa gan-an ju bí a ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ lọ nínú ọ̀pọ̀ apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ní oṣù kan ṣoṣo, iye àwọn tí wọ́n ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, wọ́n jẹ́ 22,714. Láfikún sí i, iye wákàtí tá a fi wàásù, iye ìwé ìròyìn tá a fi síta àti iye àwọn ìpadàbẹ̀wò tá a ṣe pọ̀ sí i. Ṣé o rántí bí ọ̀kan-kò-jọ̀kan ìgbòkègbodò tẹ̀mí nínú ìjọ yín lóṣù àkànṣe yẹn ṣe mú kí ìtara yín pọ̀ sí i? Ǹjẹ́ a lè ṣe irú àṣeyọrí kan náà lọ́dún yìí àbí ká tiẹ̀ tún ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ? Bí gbogbo wa lápapọ̀ bá sa gbogbo ipá wa, oṣù March 2002 lè jẹ́ “Oṣù Tí A Tíì Ṣe Dáadáa Jù Lọ.” Èé ṣe tó fi jẹ́ oṣù March?

10 Ìdí méjì loṣù March ṣe máa jẹ́ oṣù àkànṣe fún ìgbòkègbodò. Lákọ̀ọ́kọ́, apá ìparí oṣù March la máa ṣe Ìṣe Ìrántí, èyí á sì fún wa ní ọ̀pọ̀ àǹfààní ní apá ìbẹ̀rẹ̀ oṣù náà láti ké sí ọ̀pọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó láti pésẹ̀. Ìdí kejì, òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún ṣáńgílítí ni oṣù March ọdún yìí ní, èyí á sì mú kó rọrùn fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti àwọn tó ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Èé ṣe tó ò fi jókòó nísinsìnyí kó o sì ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tó máa múná dóko nípa lílo kàlẹ́ńdà tó wà nínú àkìbọnú yìí? Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ kò nira tó bá a ṣe ń wò ó. Fún àpẹẹrẹ, bó o bá pinnu láti máa lo wákàtí mẹ́jọ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá lópin ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan nínú òpin ọ̀sẹ̀ márààrún, kìkì àfikún wákàtí mẹ́wàá péré lo kàn máa ṣètò láti lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ láàárín ìwọ̀nba ọjọ́ tó kù nínú oṣù, kó o bàa lè dójú ìlà àádọ́ta wákàtí tí à ń béèrè.

11 Kí làwọn alàgbà lè ṣe láti ran gbogbo ìjọ lọ́wọ́ láti “wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní kíkún”? Ẹ ta àwọn ará jí nípasẹ̀ àwọn apá ìpàdé tẹ́ ẹ bá bójú tó àti nípa ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwọn ará lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àti àwọn olùrànlọ́wọ́ wọn lè lo ìdánúṣe láti bá ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà nínú àwùjọ wọn sọ̀rọ̀ kí wọ́n sì ṣèrànwọ́ fún wọn. Ó lè jẹ́ pé kìkì ohun tí wọ́n nílò ni pé kẹ́ ẹ sọ ọ̀rọ̀ ìṣírí fún wọn tàbí kẹ́ ẹ fún wọn láwọn ìmọ̀ràn kan tó gbéṣẹ́. (Òwe 25:11) Ọ̀pọ̀ á rí i pé pẹ̀lú àtúnṣe díẹ̀ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ wọn, wọ́n lè gbádùn àǹfààní sísìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ní ọ̀pọ̀ ìjọ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn aya wọn ló fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nípa ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní sáà Ìṣe Ìrántí. Èyí ti fún ọ̀pọ̀ àwọn akéde níṣìírí láti dara pọ̀ mọ́ wọn. Ó lè má rọrùn fún àwọn akéde kan láti ṣe aṣáájú ọ̀nà nítorí àìlera tàbí àwọn ipò mìíràn, àmọ́ a lè fún wọn níṣìírí láti fi ìmọrírì wọn hàn nípa ṣíṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pẹ̀lú gbogbo ìjọ.

12 Àṣeyọrí náà wà lọ́wọ́ ìwéwèé tí àwọn alàgbà bá fara balẹ̀ ṣe. Kí ẹ ṣètò àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ní àwọn àkókò tó rọgbọ jálẹ̀ ọ̀sẹ̀. Bó bá ṣeé ṣe, kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn yan àwọn arákùnrin tó tóótun ṣáájú láti darí àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Wọn yóò ní láti múra sílẹ̀ dáadáa láti rí i pé àwọn ìpàdé wọ̀nyí, títí kan ṣíṣètò àwùjọ kọ̀ọ̀kan, yíyan ìpínlẹ̀ fúnni àti gbígba àdúrà kò ju ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ. (Wo Àpótí Ìbéèrè nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 2001.) Kí a ṣàlàyé ìtòlẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún oṣù náà yékéyéké fún ìjọ, kí a sì lẹ̀ ẹ́ mọ́ ojú pátákó ìsọfúnni.

13 Kí a rí i pé ìpínlẹ̀ tí ó tó láti ṣiṣẹ́ wà. Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn pàdé pọ̀ pẹ̀lú arákùnrin tó ń bójú tó àwọn ìpínlẹ̀ láti ṣe àwọn ètò fún ṣíṣiṣẹ́ ní àwọn ìpínlẹ̀ tí a kì í sábà kárí. Kí ó tẹnu mọ́ pípadà wá àwọn kò-sí-nílé lọ, kí ó sì tún tẹnu mọ́ jíjẹ́rìí ní òpópónà àti láti ìsọ̀ dé ìsọ̀, àti ṣíṣe ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́. Níbi tó bá ti bá a mu, kí ó ran àwọn akéde kan lọ́wọ́ láti ṣe ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù.

14 Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Láti Sìn Lẹ́ẹ̀kan Sí i: Ǹjẹ́ àwọn kan wà ní ìpínlẹ̀ ìjọ rẹ tí kì í lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà déédéé? Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣì jẹ́ apá kan ìjọ wọ́n sì nílò ìránlọ́wọ́. (Sm. 119:176) Níwọ̀n bí a ti sún mọ́ òpin ayé ògbólógbòó yìí gan-an tí ayé tuntun sì ti wọlé dé tán, ó dára pé kí a sa gbogbo ipá wa láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́. (Róòmù 13:11, 12) Ní ọdún márùn-ún tó ti kọjá, àwọn èèyàn tí ó ju 2,500 lọ lọ́dọọdún ni wọ́n ti tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá lẹ́ẹ̀kan sí i. Kí la lè ṣe láti ran ọ̀pọ̀ sí i lọ́wọ́ láti mú kí iná ìfẹ́ àti ìgbọ́kànlé tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn máa jó?—Héb. 3:12-14.

15 Ẹgbẹ́ àwọn alàgbà yóò fẹ́ láti jíròrò bí wọ́n ṣe lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn. (Mát. 18:12-14) Kí akọ̀wé ṣàyẹ̀wò àwọn káàdì Congregation’s Publisher Record kí ó sì ṣàkọsílẹ̀ orúkọ gbogbo àwọn tí wọ́n ti di aláìṣiṣẹ́mọ́. A ní láti ṣe ìsapá àkànṣe láti pèsè ìrànwọ́ nípasẹ̀ ètò ìbẹ̀wò olùṣọ́-àgùntàn. Alàgbà kan lè fẹ́ láti ran akéde kan ní pàtó lọ́wọ́ nítorí pé wọ́n ti dojúlùmọ̀ ara wọn tẹ́lẹ̀, tàbí kí a ní kí àwọn akéde mìíràn ṣèrànwọ́. Ó lè jẹ́ pé àwọn akéde náà ló bá ẹni tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ yìí ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, inú wọn á sì dùn láti lo àǹfààní yìí láti ṣèrànwọ́ àkànṣe nígbà àìní yìí. A nírètí pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ ni a óò sún ṣiṣẹ́ láti máa wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kan sí i. Bí wọ́n bá tóótun, sáà Ìṣe Ìrántí yìí gan-an ló máa dára jù lọ fún wọn láti bẹ̀rẹ̀!—Wo Àpótí Ìbéèrè nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 2000 fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé.

16 Àwọn Mìíràn Ha Tóótun Láti Wàásù Bí? Jèhófà ń bá a nìṣó láti máa bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ nípa mímú “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè” wọlé wá. (Hág. 2:7) Lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló ń tóótun gẹ́gẹ́ bí àwọn akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Ta làwọn wọ̀nyí? Àwọn ni ọmọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti àwọn tá à ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń tẹ̀ síwájú. Báwo la ṣe lè mọ̀ bí wọ́n bá ti tóótun láti di akéde ìhin rere?

17 Àwọn Ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà: Ọ̀pọ̀ ọmọ ló ti ń tẹ̀ lé àwọn òbí wọn láti ilé dé ilé fún ọ̀pọ̀ ọdún, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò tíì di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. A lè lo oṣù March láti jẹ́ kí wọ́n di akéde. Báwo lo ṣe lè mọ̀ bí ọmọ rẹ bá ti tóótun? Ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa sọ ní ojú ewé 100 pé èyí jẹ́ “nigba tí ọmọ kan bá jẹ àwòfiṣàpẹẹrẹ ninu iwa tí ó sì lè ṣalaye igbagbọ ara rẹ̀ nipasẹ bíbá awọn ẹlomiran sọrọ nipa ihinrere naa, tí a sì sún un lati inu ọkàn-àyà wá lati ṣe bẹẹ.” Bó o bá ronú pé ọmọ rẹ tóótun, bá ọ̀kan nínú àwọn alàgbà tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ sọ̀rọ̀.

18 Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Wọ́n Tóótun: Lẹ́yìn tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá ti gba ìmọ̀ sínú tí ó sì ti ń wá sí àwọn ìpàdé fún sáà kan, ó lè fẹ́ láti di akéde Ìjọba. Bó o bá ń bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò: Ṣé ó ń tẹ̀ síwájú débi tí ọjọ́ orí rẹ̀ àti agbára rẹ̀ mọ? Ó ha ti ń ṣàjọpín ohun tó ń kọ́ láìjẹ́ bí àṣà pẹ̀lú àwọn mìíràn bí? Ṣé ó ń gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ? (Kól. 3:10) Ǹjẹ́ ó ha dójú ìlà àwọn ohun tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, tí a là lẹ́sẹẹsẹ sí ojú ewé 97 sí 99 nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, o ní láti sọ fún Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ kí wọ́n lè ṣètò fún àwọn alàgbà méjì láti pàdé pọ̀ pẹ̀lú ìwọ àti akẹ́kọ̀ọ́ náà. Bí ó bá tóótun, àwọn alàgbà méjì náà yóò sọ fún un pé ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba.

19 Oṣù April àti May Ńkọ́? Àwọn wọ̀nyí náà á jẹ́ oṣù àkànṣe fún ìgbòkègbodò púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March tún lè ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i ní oṣù April àti May, tàbí ọ̀kan nínú oṣù méjèèjì. Nínú oṣù April àti May, a óò jẹ́ kí fífi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ gba ipò àkọ́kọ́. Àǹfààní tí wọ́n ti ṣe nínú ìgbésí ayé àwọn tó ń kà wọ́n mà kúkú pọ̀ o! Àwọn ìwé ìròyìn yìí ti kó ipa tó jọjú gan-an nítorí wọ́n ti jẹ́ ká gbádùn ìbísí tó kàmàmà kárí ayé. A óò sapá lákànṣe ní oṣù April àti May láti fi àwọn ìwé ìròyìn yìí lọ ọ̀pọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Wéwèé nísinsìnyí láti lè kópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

20 Bí a ṣe ń wéwèé láti mú kí ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù pọ̀ sí i, ǹjẹ́ ó yẹ kí o fi kún iye àwọn ìwé ìròyìn tó ò ń gbà nípasẹ̀ ìjọ? Jálẹ̀ gbogbo ọdún iṣẹ́ ìsìn, a máa ń fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni ní gbogbo ọjọ́ Saturday, tí ó jẹ́ Ọjọ́ Pínpín Ìwé Ìròyìn. Bó ti wù kó rí, níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ yóò ti nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, tí gbogbo wa yóò sì máa fi àwọn ìwé ìròyìn yìí lọni fún oṣù méjì gbáko, ó lè pọn dandan kí o fi kún iye ìwé ìròyìn tó ò ń gbà nípasẹ̀ ìjọ. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, jọ̀wọ́ sọ fún ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìwé ìròyìn ní ìjọ yín ní kánmọ́. Lákòókò kan náà, kí ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ rí i dájú pé àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tó bá àkókò yẹn mu wà lọ́wọ́, tí wọ́n sì pọ̀ tó fún gbogbo ìjọ láti lò.

21 Ọ̀pọ̀ ti fi ìmọrírì wọn hàn fún apá tí a pè ní “Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn” nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ṣé o ti ń jàǹfààní ìṣètò yìí nípa lílo àpẹẹrẹ ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a pèsè fún fífi ìwé ìròyìn lọni? Èé ṣe tó ò fi máa lo apá kan lára àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé yín lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fi àwọn ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wọ̀nyí dánra wò?

22 Lo Àǹfààní Sáà Ìṣe Ìrántí Yìí Dáadáa: Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ẹ jẹ́ ká fi han Jèhófa bí a ṣe mọrírì “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ aláìṣeé-ṣàpèjúwe” tó nípa kíkópa ní kíkún nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí tá a wéwèé fún sáà Ìṣe Ìrántí yìí. Àwọn ìgbòkègbodò ọ̀hún ni (1) lílọ sí ibi àṣeyẹ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ọdún, ìyẹn ni ayẹyẹ Oúnjẹ́ Alẹ́ Olúwa ní Thursday, March 28, 2002; (2) ríran àwọn tí wọ́n ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́ láti mú kí iná “ìfẹ́ tí [wọ́n] ní ní àkọ́kọ́” máa jó (Ìṣí. 2:4; Róòmù 12:11); (3) ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ wa àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n tóótun láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi; àti (4) nínípìn-ín nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere dé gbogbo ibi tá a bá lè ṣe é dé, kódà ká tún ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March àti láwọn oṣù tó máa tẹ̀ lé e.— 2 Tím. 4:5.

23 Àdúrà àtọkànwá wa ni pé kí gbogbo wa nípìn-ín kíkún nínú wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà ní sàá Ìṣe Ìrántí yìí, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn bí ìmọrírì wa ṣe jinlẹ̀ tó fún gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ara Ẹni fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Lóṣù March 2002

Sunday Monday Tuesday Wednesday Thursday Friday Saturday

1 2

Ọjọ́ Pínpín Ìwé Ìròyìn

3 4 5 6 7 8 9

Ọjọ́ Pínpín Ìwé Ìròyìn

10 11 12 13 14 15 16

Ọjọ́ Pínpín Ìwé Ìròyìn

17 18 19 20 21 22 23

Ọjọ́ Pínpín Ìwé Ìròyìn

24 25 26 27 28 29 30

Ọjọ́ Pínpín Ìwé Ìròyìn

ÌṢE ÌRÁNTÍ

LẸ́YÌN WÍWỌ̀ OÒRÙN

31

Ǹjẹ́ o lè ṣètò láti lo àpapọ̀ àádọ́ta wákàtí láti fi ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́