Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ọjọ́ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun
1 ‘Ẹ Jẹ́ Àwọn Tí Jèhófà Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́’ (NW) ni ẹṣin ọ̀rọ̀ fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ àpéjọ àkànṣe tuntun tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní March. (Jòh. 6:45) Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ní tòótọ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbé ayé tí ń tẹ́ni lọ́rùn. Ó ń mú kí ìmọrírì jíjinlẹ̀ fún ogún ìní wa tẹ̀mí dàgbà sókè nínú wa. Ìsapá wa láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti gbọ́ ìhìn rere ń mú kí a jẹ́ mẹ́ńbà tí ó wúlò láwùjọ. Ọjọ́ àpéjọ àkànṣe yìí yóò tẹnu mọ́ àwọn ìbùkún tí àwọn tí Jèhófà kọ́ ń gbádùn.
2 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò fi ìyàtọ̀ tí ń bẹ láàárín àǹfààní ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá àti ewu ẹ̀kọ́ ayé hàn. A óò túbọ̀ rí i ní kedere bí Jèhófà ṣe ń pèsè ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó níye lórí jù lọ—ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí a gbé karí Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì. A óò tẹnu mọ́ apá ìjọsìn mẹ́ta nínú èyí tí a ti ń rí ìdùnnú ti jíjẹ́ ẹni tí Ọlọ́run kọ́. Ní àfikún sí i, a óò fún àwọn èwe níṣìírí láti fara wé àwọn àpẹẹrẹ Bíbélì títayọlọ́lá, irú bíi Dáfídì àti Tímótì, kí wọ́n sì kọ́ ìgbésí ayé wọn yí ká àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí. A óò fún ìgbàgbọ́ wa lókun bí a óò ti máa tan ìmọ́lẹ̀ sórí ìdúróṣinṣin àwọn àgbà ọlọ́jọ́ lórí pẹ̀lú. Yóò ṣeé ṣe fún àwọn ẹni tuntun tí wọ́n tóótun láti ṣe batisí. Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ọjọ́ àpéjọ àkànṣe náà, wọ́n gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ ọkàn yẹn tó alábòójútó olùṣalága létí.
3 Àkọlé àwíyé pàtàkì ti ọjọ́ àpéjọ àkànṣe náà ni “Jèhófà Kọ́ Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Inú Rẹ̀.” Yóò tẹnu mọ́ àwọn ìdí tí gbogbo wa fi ní láti máa bá kíkẹ́kọ̀ọ́ nìṣó, tí a fi ní láti dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, tí a sì fi ní láti máa bá a nìṣó láti tẹ̀ síwájú. A óò rọ̀ wá láti fara wé Jèhófà nípa kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn ní òtítọ́ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. A óò fi àwọn ìrírí tí ń gbéni ró kún un láti fi bí àwọn ìtẹ̀jáde Society ṣe ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti di ẹni tí Jèhófà kọ́ hàn. A óò tẹnu mọ́ àwọn àṣeyọrí rere tí ètò ẹ̀kọ́ kárí ayé ti Jèhófà ti ṣe.
4 Wéwèé tí ó ṣe pàtó láti wà níbẹ̀. Fún gbogbo olùfìfẹ́hàn níṣìírí láti wà níbẹ̀. Fojú sọ́nà fún dídi ẹni tí a kọ́ ní ọ̀pọ̀ ohun rere láti ọ̀dọ̀ Olùfúnni-Nítọ̀ọ́ni Gíga Jù Lọ wa.—Aísá. 30:20.