Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 2
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 2
Orin 123 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jl Ẹ̀kọ́ 14 sí 16 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Pétérù 1-5–2 Pétérù 1-3 (10 min.)
No. 1: 1 Pétérù 2:18–3:7 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Pa Wá Lára?—td 24B (5 min.)
No. 3: Ìdí Tó Fi Dá Wa Lójú Pé Jésù Ni Mèsáyà—Lúùkù 24:44; Gál. 4:4 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́. Àsọyé. Fún àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù December. Ní ṣókí, lo ẹ̀yìn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ láti ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè ṣe é.
15 min: Ǹjẹ́ O Ti Gbìyànjú Ẹ̀ Wò? Ìjíròrò. Ní ṣókí, sọ àwọn àbá tó jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìyẹn àwọn àbá tó jáde nínú àpilẹ̀kọ wọ̀nyí: “Ìkànnì Wa Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì—Ó Wúlò fún Àwa Àtàwọn Ẹlòmíì” (km 12/12), “Máa Fi Àwọn Fídíò Wa Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́” àti “Àwọn Wo Ló Máa Fẹ́ Ka Àpilẹ̀kọ Yìí?” (km 5/13). Ní kí àwọn ará sọ àwọn àǹfààní tí wọ́n rí nígbà tí wọ́n lo àwọn àbá tó wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ náà.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
Orin 12 àti Àdúrà