Àpéjọ Àkànṣe Tó Ń Bọ̀ Lọ́nà
Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́, àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ sapá gidigidi láti rí i pé àwọn wàásù ìhìn rere náà débi táwọn lè wàásù ẹ̀ dé nígbà yẹn. (Ìṣe 1:8; Kól. 1:23) Àpéjọ àkànṣe ti ọdún 2007 yìí tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ “Ẹ Jẹ́ Kí Ọwọ́ Yín Di Jọjọ Pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Náà” máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àtàtà tí wọ́n fi lélẹ̀.—Ìṣe 18:5.
Ohun tí Ọba Dáfídì sọ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní pé: “Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó ń sọ aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n.” (Sm. 19:7) Àpéjọ àkànṣe ti ọdún 2007 tá a fẹ̀sọ̀ ṣe yìí á túbọ̀ jẹ́ ká rí bí Ìwé Mímọ́ ṣe wúlò tó fún “mímú àwọn nǹkan tọ́,” ó sì máa gbà wá níyànjú láti máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wàásù ká má sì ṣe fi àkókò falẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù náà. (2 Tím. 3:16, 17) Àwọn ọ̀rọ̀ tá a máa gbọ́ ní àpéjọ náà á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè yàgò fún àwọn ọ̀fìn tá a sì máa rí àǹfààní jẹ látinú fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé wa. Ó tún máa ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bá a ṣe lè máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ran àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run.
Rí i pé o ti wà níkàlẹ̀ kí àpéjọ náà tó bẹ̀rẹ̀ kó o sì fetí sílẹ̀ dáadáa. Ṣe àkọsílẹ̀ àwọn kókó tó o máa fẹ́ láti mú lò. Fi ọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìtọ́ni àtàwọn ìránnilétí tó o bá gbọ́, kó o sì máa ṣàṣàrò lórí bí wàá ṣe máa ṣe ohun tó o bá gbọ́ ní àpéjọ náà.
Àpéjọ àkànṣe wa yìí á túbọ̀ fi kún bá a ṣe mọrírì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, á sì mú ká wà lójúfò ká lè máa bá a lọ ní fífi ìṣòtítọ́ wàásù Ìjọba Ọlọ́run pẹ̀lú ìtara, ó tún máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe máa ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ṣe ni kó o pinnu láti má ṣe pa èyíkéyìí jẹ lára àwọn ìtọ́sọ́nà àtàwọn ìlànà tí Jèhófà ń tipa àwọn àpéjọ pèsè!—Aísá. 30:20b, 21.