Àtúnyẹ̀wò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká
Àpilẹ̀kọ yìí la máa lò láti fi gbé àwọn ohun tá a máa gbádùn ní àpéjọ àyíká wa ọdún 2005 yẹ̀ wò, a ó sì tún lò ó láti fi ṣe àtúnyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà. Àpilẹ̀kọ tó ní àkọlé náà “Ọ̀nà Tuntun Tí A Ó Máa Gbà Ṣe Àtúnyẹ̀wò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká àti Àkànṣe,” èyí tó wà ní ojú ìwé kẹrin àkìbọnú yìí, ṣàlàyé bá a ṣe máa ṣe àtúnyẹ̀wò yìí. Nígbà tá a bá ń ṣe àtúnyẹ̀wò yìí, kí ẹni tó máa bójú tó o díwọ̀n àkókò tó máa lò lórí ìbéèrè kọ̀ọ̀kan kó bàa lè ráyè béèrè gbogbo ìbéèrè tó wà níbẹ̀. Kí ó bójú tó àtúnyẹ̀wò yìí lọ́nà táwọn ará á fi mọ bí wọ́n ṣe lè fi ohun tí wọ́n gbọ́ ní àpéjọ náà sílò.
ÌPÀDÉ ÒWÚRỌ̀ [TÀBÍ Ọ̀SÁN] ỌJỌ́ ÀKỌ́KỌ́
1. Kí ló máa jẹ́ ká lè ní ọgbọ́n tí Ọlọ́run ń fúnni?
2. Ìsapá wo làwọn tí wọ́n wà nínú àyíká wa máa ń ṣe kí wọ́n bàa lè wàásù ìhìn rere fún ọ̀pọ̀ èèyàn?
ÌPÀDÉ Ọ̀SÁN [TÀBÍ ÌRỌ̀LẸ́] ỌJỌ́ ÀKỌ́KỌ́
3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwa Kristẹni má ṣe gba ohunkóhun láyè láti sọ ọkàn wa di aláìmọ́? Báwo la ṣe lè ṣe èyí?
4. Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń fi ẹ̀mí àlàáfíà bá àwọn ará lò?
5. Kí ni jíjẹ́ olóye túmọ̀ sí, báwo la sì ṣe lè fi èyí hàn nínú bá a ṣe ń lo àkókò wa?
6. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Sọ́ọ̀lù àti Nóà? Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a “múra tán láti ṣègbọràn”? (Ják. 3:17)
7. Kí làwa Kristẹni lè ṣe tá ò fi ní máa hùwà àgàbàgebè, ìyẹn ni pé kéèyàn máa ṣe bí olóòótọ́ lójú ayé àmọ́ kó máa hùwàkiwà lábẹ́lẹ̀?
8. Báwo la ṣe lè máa sọ̀rọ̀ nípa ọgbọ́n Ọlọ́run bíi ti Pọ́ọ̀lù?
ÌPÀDÉ ÒWÚRỌ̀ ỌJỌ́ KEJÌ
9. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra nígbà tá a bá ń yan àwọn ìgbòkègbodò tá a fẹ́ ṣe, kí ló sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe èyí?
10. Kí làwọn ará tó wà nínú àyíká wa máa ń ṣe kí wọ́n bàa lè máa wá sí ìpàdé déédéé, báwo sì ni èyí ṣe ń ṣe wọ́n láǹfààní?
11. Báwo làwọn olórí ìdílé ṣe lè gbé agbo ilé wọn ró?
12. Kí làwọn ohun tá a gbọ́ pé ó ń fẹ́ àbójútó nínú àyíká wa?
ÌPÀDÉ Ọ̀SÁN ỌJỌ́ KEJÌ
13. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe gbọ́ nínú àsọyé fún gbogbo èèyàn, àwọn iṣẹ́ òdodo wo ni ọgbọ́n tí ó wá láti òkè máa ń ṣe?
14. Kí nìdí tó fi jẹ́ ìwà òmùgọ̀ láti gbẹ́kẹ̀ lé ara wa tàbí lé àwọn tí kì í ṣe ọgbọ́n Ọlọ́run ló ń tọ́ wọn sọ́nà? Àwọn ohun wo ló yẹ ká ṣọ́ra fún?
15. Àwọn ewu wo ni ọgbọ́n Ọlọ́run ò ní jẹ́ ká kó sí?
16. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fi ìmọ̀ràn tá a rí gbà ní àpéjọ àyíká yìí sílò?