Àtúnyẹ̀wò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe
Àpilẹ̀kọ yìí la máa lò láti fi gbé àwọn ohun tá a máa gbádùn ní àpéjọ àkànṣe wa ọdún 2005 yẹ̀ wò, a ó sì tún lò ó láti fi ṣe àtúnyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà. Àpilẹ̀kọ tó ní àkọlé náà “Ọ̀nà Tuntun Tí A Ó Máa Gbà Ṣe Àtúnyẹ̀wò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká àti Àkànṣe,” èyí tó wà ní ojú ìwé kẹrin àkìbọnú yìí, ṣàlàyé bá a ṣe máa ṣe àtúnyẹ̀wò yìí. Nígbà tá a bá ń ṣe àtúnyẹ̀wò yìí, kí ẹni tó máa bójú tó o díwọ̀n àkókò tó máa lò lórí ìbéèrè kọ̀ọ̀kan kó bàa lè ráyè béèrè gbogbo ìbéèrè tó wà níbẹ̀. Kí ó bójú tó àtúnyẹ̀wò yìí lọ́nà táwọn ará á fi mọ bí wọ́n ṣe lè fi ohun tí wọ́n gbọ́ ní àpéjọ náà sílò.
ÌPÀDÉ ÒWÚRỌ̀
1. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gidigidi pé ká máa fetí sí ohun tí Jèhófà ń sọ? Kí ló túmọ̀ sí láti tẹ́tí sílẹ̀? (“Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Tẹ́tí sí Ohùn Jèhófà”)
2. Báwo làwọn ìdílé ṣe lè rí i pé ohunkóhun kò ṣèdíwọ́ fún ètò tí wọ́n ṣe nípa àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí? (“Àwọn Ìdílé Tó Ń Tẹ́tí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láìjẹ́ Kí Ohunkóhun Pín Ọkàn Wọn Níyà”)
3. Báwo làwọn ará tó wà ní àyíká wa ṣe ń lo àǹfààní tó bá yọ láti wàásù láìjẹ́ bí àṣà? (“Ṣíṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọ́run”)
4. Àwọn ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo la lè rí kọ́ nínú ìwé Hébérù orí kẹta àti orí kẹrin? Báwo ni Jèhófà ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀ lónìí? (“Títẹ́tí sí Ọlọ́run Nígbà Tó Bá Ń Sọ̀rọ̀ Ń Dáàbò Bò Wá”)
5. Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú àsọyé ìrìbọmi? (“Ìyàsímímọ́ àti Ìrìbọmi”)
ÌPÀDÉ Ọ̀SÁN
6. Kí la lè rí kọ́ lára Jésù nígbà tó wà lọ́mọdé, báwo làwọn ọ̀dọ́ tó wà ní àyíká wa sì ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? (“Bí Fífarabalẹ̀ Tẹ́tí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣe Ń Mú Káwọn Ọ̀dọ́ Wa Jẹ́ Alágbára”)
7. Kí ni díẹ̀ lára ohun táwọn òbí lè ṣe láti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn ìkókó àtàwọn ọmọ kéékèèké nípá Jèhófà? (“Àwọn Ọmọ Kékeré Tí Wọ́n Ń Fetí sí Ọlọ́run Tí Wọ́n sì Ń Kẹ́kọ̀ọ́”)
8. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà pàtó tó ti yẹ ká fiyè sí Jèhófà, Ọmọ rẹ̀, àti “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”? (Mát. 24:45) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ṣe bẹ́ẹ̀? (“Máa Fiyè sí Ìtọ́ni Ọlọ́run Nígbà Gbogbo”)