Àtúnyẹ̀wò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe
Kí ẹ lo ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn láti fi gbé ohun tẹ́ ẹ máa gbọ́ ní àpéjọ àkànṣe ti ọdún 2006 yẹ̀ wò nígbà tó bá kù díẹ̀ tẹ́ ẹ máa lọ, kẹ́ ẹ sì tún lò ó láti fi ṣe àtúnyẹ̀wò ohun tẹ́ ẹ gbọ́ ní àpéjọ àkànṣe náà láìpẹ́ sígbà tẹ́ ẹ bá dé. Kí alága àwọn alábòójútó ṣètò láti jíròrò ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí ṣáájú àti lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti ṣe àpéjọ àkànṣe yín bó ṣe wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 2004 ní ojú ìwé 4. Nígbà àtúnyẹ̀wò yìí, ẹ rí i dájú pé gbogbo ìbéèrè náà lẹ jíròrò, kí ẹni tó máa bójú tó àtúnyẹ̀wò náà rí i pé àwọn ará mọ bí wọ́n ṣe máa fi ohun tí wọ́n gbọ́ ní àpéjọ náà sílò.
ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ ÒWÚRỌ̀
1. Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ kí ojú ẹni mú ọ̀nà kan, kí sì lohun tó mú kó ṣòroó ṣe lónìí? (“Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Jẹ́ Kí Ojú Rẹ Mú Ọ̀nà Kan?”)
2. Ìbùkún wo là ń rí nínú mímú kí ojú wa mú ọ̀nà kan? (“Máa Jẹ́ Kí Ojú Rẹ Mú Ọ̀nà Kan Kó O Lè Rí Ìbùkún Gbà”)
3. Ewu wo ló wà nínú ọ̀pọ̀ ìgbòkègbodò táwọn èèyàn ò kà sí èyí tó burú? (“Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ojú Rẹ Mú Ọ̀nà Kan Nínú Ayé Búburú Yìí”)
ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ Ọ̀SÁN
4. Báwo làwọn òbí àtàwọn mìíràn ṣe lè fáwọn èwe níṣìírí láti fi nǹkan tẹ̀mí ṣe àfojúsùn wọn? (“Àwọn Òbí Tó Ń Darí Ọfà Wọn Síbi Tó Dára” àti “Àwọn Èwe Tí Wọ́n Ń Lépa Àwọn Ohun Tẹ̀mí”)
5. Báwo la ṣe lè máa bá ètò Jèhófà tẹ̀ síwájú (a) lẹ́nìkọ̀ọ̀kan? (b) bí ìdílé? (d) bí ìjọ lódindi? (“Bá A Ó Ṣe Máa Bá Ètò Jèhófà Tẹ̀ Síwájú Ló Yẹ Ká Gbájú Mọ́”)