Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun
Iṣẹ́ ọnà àwòyanu ni ojú jẹ́. (Sm. 139:14) Síbẹ̀, ohun kan ṣoṣo ló lágbára láti rí kedere lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Bó sì ṣe rí nìyẹn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ tàbí ní tààràtà. Bí ojú ìríran tiwa náà bá máa ríran kedere tí kò sì ní máa ṣe bàìbàì, a gbọ́dọ̀ pa ọkàn wa pọ̀ sórí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Bá a bá fi ojú bí ayé Sátánì yìí ti ṣe ń pín ọkàn àwọn èèyàn níyà wò ó, ńṣe ni gẹ́gẹ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe wa ti ọdún 2006 yóò ṣe máa ṣàlàyé gbogbo ohun tó wé mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Ẹ . . . Jẹ́ Kí Ojú Yín Mú Ọ̀nà Kan”!—Mát. 6:22.
Kí la máa wá ṣe ká lè rí ìbùkún yìí gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà? (Òwe 10:22) Ìbéèrè yìí ni apá tó ní àkòrí náà, “Máa Jẹ́ Kí Ojú Rẹ Mú Ọ̀nà Kan Kó O Lè Rí Ìbùkún Gbà,” yóò jíròrò. Àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó wà nínú rẹ̀ á jẹ́ ká rí bá a ṣe lè jàǹfààní látinú fífi ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò. Ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ojú Rẹ Mú Ọ̀nà Kan Nínú Ayé Búburú Yìí,” ni ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tí olùbánisọ̀rọ̀ tí a rán wá yóò fi ṣèkìlọ̀ fún wa lórí àwọn nǹkan tó lè mú kí ìgbésí ayé wa lọ́jú pọ̀ tó sì lè fún ire tẹ̀mí tó wà lọ́kàn wa pa ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. A tún máa mọ ohun tó túmọ̀ sí láti “yan ìpín rere.”—Lúùkù 10:42.
Báwo làwọn òbí àtàwọn mìíràn ṣe lè fún àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ níṣìírí láti fi àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣe àfojúsùn wọn? Apá tó ní ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Àwọn Òbí Tó Ń Darí Ọfà Wọn Síbi Tó Dára” àti “Àwọn Èwe Tí Wọ́n Ń Lépa Àwọn Ohun Tẹ̀mí,” yóò ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó dá lórí ohun táwọn òbí àtàwọn èwe máa sọ lórí ìbéèrè yìí. (Sm. 127:4) Ọ̀rọ̀ àsọparí látẹnu olùbánisọ̀rọ̀ tí a rán wá yóò jíròrò bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, ìdílé lápapọ̀ àti ìjọ lódindi ṣe lè máa ṣísẹ̀ rìn ní ìyára kan náà pẹ̀lú ètò Jèhófà.
Ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ ‘kí ojú wa mú ọnà kan,’ kódà kó jẹ́ pé ńṣe la ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ òtítọ́ tàbí kẹ̀, ká ti máa sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe wa yìí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.