Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun
Bí a bá rí àmì ìkìlọ̀ tàbí a gbọ́ ìkìlọ̀ pé jàǹbá fẹ́ ṣẹlẹ̀ tá ò kọbi ara sí i, ohun tó sábà máa ń yọrí sí kì í dára rárá. Lọ́nà kan náà, ó túbọ̀ ṣe pàtàkì pé ká kọbi ara sí àwọn ìtọ́sọ́nà nípa tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè. Àpéjọ àkànṣe wa ní ọdún tó ń bọ̀ yóò jẹ́ kí kókó yìí yé wa yékéyéké. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni “Ẹ Máa Fiyè sí Bí Ẹ Ṣe Ń Fetí Sílẹ̀.”—Lúùkù 8:18.
Nínú àsọyé tí olùbánisọ̀rọ̀ tá a rán wá máa kọ́kọ́ sọ, yóò ṣàlàyé bí ìmọ̀ràn tó wà nínú àwọn orí tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Hébérù ṣe kàn wá lónìí. Nínú àsọyé tó máa sọ gbẹ̀yìn, tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Máa Fiyè sí Ìtọ́ni Ọlọ́run Nígbà Gbogbo,” yóò jẹ́ kí gbogbo wa ṣàyẹ̀wò ara wa ká lè mọ̀ bóyá lóòótọ́ là ń fetí sílẹ̀ sí Jèhófà, Ọmọ rẹ̀, àti “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.”—Mát. 24:45.
Àwọn àsọyé kan nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí á ṣe àwọn ìdílé láǹfààní gan-an. Àsọyé tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Àwọn Ìdílé Tó Ń Tẹ́tí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láìjẹ́ Kí Ohunkóhun Pín Ọkàn Wọn Níyà” yóò jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe kí àwọn nǹkan tó wà nínú ayé má bàa gbà wá lọ́kàn débi pé a ò ní ráyè fún àwọn nǹkan tẹ̀mí. Bákan náà, a óò fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn tó ti ṣe àwọn àtúntò kan nínú ìgbésí ayé wọn kí wọ́n lè fi àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣáájú. Ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé mìíràn ni “Bí Fífarabalẹ̀ Tẹ́tí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣe Ń Mú Káwọn Ọ̀dọ́ Wa Jẹ́ Alágbára.” Nínú àsọyé yìí, a óò fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn ọ̀dọ́ tó fi hàn pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin nílé ẹ̀kọ́, nígbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ àwọn ojúgbà wọn tàbí nígbà tí wọ́n wà lóde ẹ̀rí. Àsọyé tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Àwọn Ọmọ Kékeré Tí Wọ́n Ń Fetí sí Ọlọ́run Tí Wọ́n sì Ń Kẹ́kọ̀ọ́” yóò jẹ́ ká rí i pé kò yẹ ká fojú kéré àwọn ọmọ wa kéékèèké láé, ká máa rò pé wọn ò lè kẹ́kọ̀ọ́. A óò fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn ọmọ kékeré àtàwọn òbí wọn, èyí á sì jẹ́ ká rí àwọn àǹfààní tó máa ń jẹ yọ tá a bá kọ́ àwọn ọmọ nípa Jèhófà láti kékeré.
Nínú ayé tí Sátánì ti “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà” yìí, Jèhófà ń fi ọ̀nà tó yẹ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ máa rìn hàn wọ́n. (Ìṣí. 12:9; Aísá. 30:21) Bí a bá ń fiyè sí ìmọ̀ràn Ọlọ́run, tá a sì ń fi í sílò, yóò jẹ́ ká di ọlọgbọ́n, yóò fún wa láyọ̀, yóò sì jẹ́ ká ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Òwe 8:32-35.