Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun
1 Bẹ̀rẹ̀ láti January, ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àyíká yóò jẹ́, “Fetí Sílẹ̀ Kí O sì Kọ́ Láti Ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.” Ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí, tí a gbé ka Deuteronomi 31:12, 13, pèsè ìpìlẹ̀ tí ó bá a mu fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà látòkèdélẹ̀ láti tẹnu mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tí a ní láti kọ́, kí a sì fi sílò.
2 Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí tilẹ̀ ń fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ ìsọjáde tí a mí sí, tí ń ṣini lọ́nà, ìdí ṣíṣe kókó wà fún gbogbo wa láti fetí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, kí a sì kọ́ láti ṣègbọràn sí i. (Luku 11:28; 1 Tim. 4:1) Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, a ti ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká láti pèsè ìṣírí àti ìrànlọ́wọ́ fún àwọn akéde, ìdílé, àwọn alàgbà, àti àwọn aṣáájú ọ̀nà. Ní Saturday, àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé alápá mẹ́rin yóò wà, lórí kókó ẹ̀kọ́ náà, “Kíkojú Àwọn Ìṣòro Wa—Nípa Fífiyè sí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.” Ní òwúrọ̀ Sunday pẹ̀lú, àpínsọ ọ̀rọ̀ tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Bí Ìwé Mímọ́ Ṣe Ń Báni Wí Nínú Òdodo,” yóò wà. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà látòkèdélẹ̀ yóò pèsè ìṣírí tẹ̀mí tí kò yẹ kí ìwọ àti ìdílé rẹ tàsé.
3 Ní Saturday àti Sunday, a óò pèsè àwọn àbá gbígbéṣẹ́ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, a óò sì ṣàṣefihàn wọn. A óò tún fúnni ní àwọn ìrírí àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí ń gbéni ró tí ó sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Nípa báyìí, nípa wíwà níbẹ̀ àti fífetí sílẹ̀ pẹ̀lú ète fífi ohun tí o kọ́ sílò, ìwọ yóò wà ní ipò tí ó túbọ̀ dára láti ṣègbọràn sí àṣẹ tí ó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní kíkún.
4 Ìbatisí àwọn arákùnrin àti arábìnrin, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ya ara wọn sí mímọ́, yóò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn kókó pàtàkì àpéjọ àyíká. Ṣáájú ìpolongo ìyàsímímọ́ wọn ní gbangban yìí, àwọn tí ó fẹ́ ṣe ìrìbọmi ní láti sọ ìfẹ́ ọkàn wọn láti ṣe ìrìbọmi fún alábòójútó olùṣalága, kí ó baà lè ṣètò fún àwọn alàgbà láti pàdé pọ̀ pẹ̀lú wọn.
5 A pe àkọlé ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn fún ọ̀wọ́ àpéjọ àyíká yìí ní, “Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí Bibeli Ṣamọ̀nà Rẹ?” Ké sí àwọn olùfìfẹ́hàn láti wà níbẹ̀. Ní fífojú sọ́nà fún ìṣírí àti ìrànlọ́wọ́ tí ìwọ àti ìdílé rẹ nílò gidigidi, tí ẹ óò sì rí gbà, ṣe ètò gúnmọ́ láti wà níbẹ̀ láti gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà látòkèdélẹ̀.