Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun
Ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” tá a wà yìí, a gbọ́dọ̀ ní ọgbọ́n àtọ̀runwá tá a bá fẹ́ kí Jèhófà máa fi ojú rere wò wá. (2 Tím. 3:1) Ní àpéjọ àyíká wa ní ọdún 2005, a óò rí ìmọ̀ràn àti ìṣírí tá a lè máa lò nígbèésí ayé wa gbà. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni: “Jẹ́ Kí ‘Ọgbọ́n Tí Ó Wá Láti Òkè’ Máa Tọ́ Ọ Sọ́nà.”—Ják. 3:17.
Àkòrí àpínsọ àsọyé tá a máa kọ́kọ́ gbọ́ ni “Bí A Ṣe Lè Máa Lo ‘Ọgbọ́n Tí Ó Wá Láti Òkè.’” Nínú àpínsọ àsọyé yìí, a óò lóye àwọn ohun tá a ní láti ṣe ká lè jẹ́ ẹni tó mọ́ níwà, ẹlẹ́mìí àlàáfíà, ẹni tó ń fòye báni lò, àti ẹni tó múra tán láti ṣègbọràn. Lẹ́yìn èyí, alábòójútó àyíká yóò sọ̀rọ̀ lórí àwọn ànímọ́ mẹ́ta mìíràn lára ọgbọ́n tó wá láti òkè tó yẹ ká ní. Alábòójútó àgbègbè ni yóò sọ àsọyé tó gbẹ̀yìn ní ọjọ́ àkọ́kọ́. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, yóò ṣàlàyé bí àwa òjíṣẹ́ Ọlọ́run ṣe gbára dì láti sọ̀rọ̀ nípa ọgbọ́n Ọlọ́run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan kà wá sí “àwọn ènìyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù.”—Ìṣe 4:13.
Ní ọjọ́ kejì, àpínsọ àsọyé tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ “Máa Ṣe Àwọn Ohun Tí Ń Gbéni Ró” yóò jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó lè fà wá sẹ́yìn nípa tẹ̀mí àti ohun tá a lè ṣe kí wọ́n má bàa fà wá sẹ́yìn. Yóò tún jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè gbé àwọn ọmọnìkejì wa ró ní ìpàdé ìjọ, lóde ẹ̀rí àti nínú ìdílé. Àsọyé fún gbogbo èèyàn tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Bí Ọgbọ́n Ọlọ́run Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní,” yóò jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì àwọn ìbùkún tá à ń rí gbà bá a ṣe ń fi àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò nígbèésí ayé wa. Àsọyé tó gbẹ̀yìn tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Lílo Ọgbọ́n Ọlọ́run Ń Pa Wá Mọ́” yóò jẹ́ ká túbọ̀ rọ̀ mọ́ ìpinnu wa láti máa wá ọgbọ́n lọ́dọ̀ Jèhófà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí.
Ohun pàtàkì kan tó máa ń wáyé ní gbogbo àpéjọ wa ni ìrìbọmi àwọn ọmọlẹ́yìn tuntun. Ní àpéjọ àyíká yìí, a óò tún gbádùn Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ti ọ̀sẹ̀ yẹn. Jèhófà fẹ́ kí ọgbọ́n tí òun ń fúnni ṣe gbogbo wa láǹfààní. Nípa bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ràn àti ìṣírí tá a máa rí gbà ní àpéjọ àyíká wa tó ń bọ̀ yìí yóò jẹ́ ká túbọ̀ jàǹfààní nípa tẹ̀mí.—Òwe 3:13-18.