Àpéjọ Àyíká Tó Máa Jẹ́ Ká Lè Máa Dáàbò Bo Ipò Tẹ̀mí Wa
1. Kí ni ọ̀kan lára àwọn ìpèsè Jèhófà tó ń jẹ́ ká lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere yanjú?
1 Tìfẹ́tìfẹ́ ni Jèhófà ń fún wa ní ìsọfúnni, ìdálẹ́kọ̀ọ́ àti ìṣírí tá a nílò ká lè ṣe iṣẹ́ tó gbé fún wa yanjú, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere kárí ayé. (Mát. 24:14; 2 Tím. 4:17) Àpéjọ àyíká tá à ń ṣe lọ́dọọdún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpèsè yìí. Ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àyíká wa ti ọdún 2010 ni, “Ẹ Dáàbò Bo Ipò Tẹ̀mí Yín.” A gbé ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí ka Róòmù 8:5 àti Júdà 17-19. A sì ti ṣètò pé kó bẹ̀rẹ̀ ní January 2, 2010.
2. (a) Àwọn àǹfààní wo la máa jẹ ní àpéjọ àyíká tó ń bọ̀? (b) Báwo ni àwọn àpéjọ àyíká tá a ti ṣe kọjá ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?
2 Àǹfààní Tó Ń Dúró Dè Wá: Àpéjọ yìí á jẹ́ ká wà lójúfò láti rí àwọn nǹkan tó lè wu wá léwu, irú bí àwọn nǹkan tó ń fa ìpínyà ọkàn tó sì ń fi àkókò ẹni ṣòfò, tó sì lè yí ọkàn wa kúrò nínú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì ní tòótọ́. A máa kọ́ bá a ṣe lè paná ohun tó máa ń mú kó wù wá láti fàyè gba ìwà àìtọ́, a ó sì mọ àwọn nǹkan tá a lè fi dá ẹni tẹ̀mí mọ̀. Àpínsọ àsọyé tó máa wáyé lọ́jọ́ Sunday á jẹ́ ká mọ ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan àtàwọn ìdílé lè ṣe láti mú kí ipò tẹ̀mí wọn lágbára sí i nígbà tí wọ́n bá dojú kọ ìṣòro tó lékenkà àti ìdánwò ìgbàgbọ́ tó lágbára. Àpéjọ yìí á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè dáàbò bo ọkàn-àyà wa, bá a ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run àti bá a ṣe lè jẹ́ kí àwọn ìbùkún tó ń dúró de àwọn tó bá pa ipò tẹ̀mí wọn mọ́ máa ṣe kedere lọ́kàn wa.
3. Ìgbà wo lẹ máa ṣe àpéjọ àyíká tó ń bọ̀, kí ló sì yẹ kó jẹ́ ìpinnu rẹ?
3 Gbàrà tó o bá ti mọ ìgbà tẹ́ ẹ máa ṣe àpéjọ àyíká yínàti ibi tẹ́ ẹ ti máa ṣe é, bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò láti wà níbẹ̀, kó o sì fetí sílẹ̀ sí gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà lọ́jọ́ méjèèjì. Mọ̀ dájú pé Jèhófà máa ń bù kún àwọn aláápọn.—Òwe 21:5.
4. Kí ló dá wa lójú pé a máa rí gbà ní àpéjọ àyíká wa tó ń bọ̀?
4 Kò sí àní-àní pé Jèhófà ni Olùpèsè ẹ̀bùn rere yìí. Oúnjẹ tẹ̀mí tí ẹrú olóòótọ́ ṣètò yìí á jẹ́ ká lè máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. A dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà nítorí bó ṣe ń fìfẹ́ pèsè àwọn ohun tó ń mú ká lè máa “di ìpolongo ìrètí wa ní gbangba mú ṣinṣin láìmikàn.”—Héb. 10:23-25; Ják. 1:17.