ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/12 ojú ìwé 1
  • Máa Ṣọ́ Èrò Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Ṣọ́ Èrò Rẹ
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpéjọ Àyíká Tó Máa Jẹ́ Ká Lè Máa Dáàbò Bo Ipò Tẹ̀mí Wa
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Máa Ṣọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Ìpèsè Tẹ̀mí fún Àwọn Kristẹni Òjíṣẹ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
km 12/12 ojú ìwé 1

Máa Ṣọ́ Èrò Rẹ

1. Kí ni ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àyíká ti ọdún 2013? Kí sì nìdí tá a fi ṣètò àpéjọ náà?

1 Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n fi gbogbo ọkàn-àyà wọn, gbogbo ọkàn wọn àti gbogbo èrò inú wọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Mát. 22:37, 38) A ṣètò àpéjọ àgbègbè tó kọjá àtàwọn àpéjọ tá a máa ṣe ní àyíká wa lọ́dún 2013, kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí irú ẹni tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún túbọ̀ máa wu Ọlọ́run. Tẹ́ ẹ bá rántí, ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àgbègbè wa ti ọdún 2012 ni “Máa Ṣọ́ Ọkàn Rẹ!” Ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àkànṣe ti ọdún 2013 ni “Máa Ṣọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ.” Nígbà tí ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àyíká tó máa bẹ̀rẹ̀ ní January 2013 jẹ́ “Máa Ṣọ́ Èrò Rẹ.” Ìwé Mátíù 22:37 la gbé ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àyíká náà kà. A ṣètò àpéjọ àyíká yìí kó lè jẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa kíyè sí bá a ṣe ń ronú kí èrò wa lè túbọ̀ máa múnú Jèhófà dùn.

2. Àwọn ìbéèrè wo la fẹ́ wá ìdáhùn sí nígbà àpéjọ náà?

2 Àwọn Ohun Tá A Máa Gbọ́: Tá a bá wà ní àpéjọ náà, a rọ̀ wá pé ká fetí sílẹ̀ dáadáa, ká lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó dá lórí àwọn kòkó pàtàkì tá a máa gbọ́. Àwọn ìbéèrè náà nìwọ̀nyí:

• Kí la lè ṣe tí a ó fi máa ní èrò Ọlọ́run dípò ti ènìyàn?

• Báwo la ṣe lè ká ìbòjú tó bó ojú inú àwọn aláìgbàgbọ́ kúrò?

• Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní?

• Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ṣàṣàrò bó ṣe yẹ?

• Báwo la ṣe lè jẹ́ kí Jèhófà máa darí ìrònú wa?

• Kí làwọn ọkọ, àwọn aya, àwọn òbí àtàwọn ọmọ lè ṣe tí ayọ̀ fi máa jọba nínú ìdílé?

• Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ Jèhófà?

• Kí ló túmọ̀ sí pé ká mú èrò inú wa gbára dì fún ìgbòkègbodò?

• Àǹfààní wo làwọn tó bá ń fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò máa ń rí?

3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká wà níbẹ̀ jálẹ̀ ọjọ́ méjèèjì, ká sì tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́? Kí nìdí tó fi yẹ ká fi ohun tá a bá kọ́ sílò?

3 Sátánì ń sapá gidigidi láti máa darí èrò wa. Ó sì ń wá bó ṣe máa sọ ọ́ dìbàjẹ́. (2 Kọ́r. 11:3) Torí náà, ó yẹ ká máa ṣọ́ ohun tá à ń rò lọ́kàn wa, ká má ṣe máa ro èròkerò. Ká jẹ́ kí èrò wa máa jọ ti Kristi. Ká má sì jẹ́ kí ayé búburú yìí nípa lórí wa. (1 Kọ́r. 2:16) Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé kó o wà níbẹ̀ jálẹ̀ ọjọ́ méjèèjì, kó o sì tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́. Tá a bá fi àwọn ohun tá a máa gbọ́ ní àpéjọ náà sílò, á jẹ́ ká lè múra ọkàn wa sílẹ̀ láti máa fìtara ṣe iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run.—1 Pét. 1:13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́