Ìpèsè Tẹ̀mí fún Àwọn Kristẹni Òjíṣẹ́
1. Ètò tuntun wo ló bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1938, kí sì nìdí?
1 Ní ọdún 1938, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ ètò tuntun kan. A ṣètò pé kí àwọn ìjọ máa pàdé láti ṣe àpéjọ àyíká. Kí nìdí? Ìtẹ̀jáde Informant (tí a wá ń pè ní Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa báyìí) ti January 1939, ní èdè Gẹ̀ẹ́sì dáhùn pé: “Àwọn àpéjọ yìí jẹ́ ara ètò tí Jèhófà ṣe láti kọ́ wa bí a ó ṣe máa ṣe iṣẹ́ ìsìn Ìjọba rẹ̀. Àwọn ìtọ́ni tá à ń gbà níbẹ̀ ṣe pàtàkì, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́ bó ṣe yẹ.” Nígbà tá a ṣàyẹ̀wò ìbísí tó dé bá iye àwọn tó ń kéde Ìjọba Ọlọ́run tí iye wọn kò ju ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [58,000] lọ lọ́dún 1938, àmọ́ tí wọ́n ti wá lé ní mílíọ̀nù méje [7,000,000] lọ́dún 2009, ó ṣe kedere pé àpéjọ àyíká ń ran àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́ kí wọ́n lè ‘ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́.’
2. Àwọn ìsọfúnni wo la máa gbádùn ní àpéjọ àyíká tá a máa ṣe lọ́dún 2011?
2 Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Àpéjọ Àyíká ti Ọdún Tó Ń Bọ̀: À ń fojú sọ́nà láti gbádùn àpéjọ àyíká tó máa bẹ̀rẹ̀ ní oṣù January ọdún 2011, a sì ń fẹ́ láti gba ìṣírí níbẹ̀. Ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ náà ni, “Ẹ Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé.” A mú ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí jáde látinú Jòhánù 15:19. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àsọyé tó dájú pé ó máa ṣe àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ láǹfààní? Lọ́jọ́ Saturday, a máa gbọ́ àsọyé náà, “Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò-Kíkún Máa Ń Jẹ́ Ààbò fún Wa, Lọ́nà Wo?” A tún máa gbádùn àpínsọ àsọyé alápá mẹ́ta tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Má Ṣe Jẹ́ Kí Nǹkan Wọ̀nyí Kó Èèràn Ràn Ọ́ . . . ” “‘Ẹranko Ẹhànnà’ Náà,” “Aṣẹ́wó Ńlá Náà” àti “Àwọn Olówò Arìnrìn-Àjò.” Lọ́jọ́ Sunday, a máa gbọ́ àpínsọ àsọyé tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Jèhófà Ni Kó O Nífẹ̀ẹ́, Má Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Ayé.” Lára àwọn àsọyé míì tá a tún máa gbọ́ ni, “Ẹ Máa Jẹ́ ‘Àtìpó àti Olùgbé fún Ìgbà Díẹ̀’ Lọ” àti “Mọ́kàn Le! O Lè Ṣẹ́gun Ayé.”
3. Àwọn àǹfààní wo la máa jẹ tá a bá lọ sí àpéjọ àyíká náà?
3 Lẹ́yìn tí arábìnrin kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù dé láti àpéjọ àyíká kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó kọ̀wé pé àwọn nǹkan tí òun gbọ́ ní àpéjọ náà mú kí òun tún ipò òun gbé yẹ̀ wò, ó pinnu láti máa lọ sóde ẹ̀rí, ó sì jáwọ́ nínú ṣíṣe àwáwí. Ó dájú pé àwọn nǹkan tá a máa gbọ́ ní àpéjọ àyíká tá a máa ṣe ní ọdún 2011 á ran gbogbo wa lọ́wọ́ ká lè máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dípò ayé. (1 Jòhánù 2:15-17) Rí i dájú pé o wà níbẹ̀, kó o sì fetí sílẹ̀ dáadáa kó o lè jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ látinú ìpèsè tẹ̀mí tí Jèhófà fìfẹ́ pèsè fún àwọn Kristẹni òjíṣẹ́!