Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 10
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 10
Orin 32 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 2 ìpínrọ̀ 14 sí 19 àti àpótí tó wà lójú ìwé 25 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Sefanáyà 1–Hágáì 2 (10 min.)
No. 1: Hágáì 1:1-13 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Èèyàn Kò Lè Fojú Rí Ìpadàbọ̀ Kristi—td 26A (5 min.)
No. 3: Mímọ Èrò Inú Kristi Ń Jẹ́ Ká Túbọ̀ Mọ Jèhófà—Mát. 11:27 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2013. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ni kó sọ àsọyé yìí. Jíròrò àwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ yín látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti ọdún 2013. Fún àwọn ará níṣìírí láti máa fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tá a bá yàn fún wọn, kí wọ́n máa lóhùn sí Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, kí wọ́n sì máa fi àwọn àbá tí wọ́n bá rí gbà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ látinú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílò.
15 min: “Máa Ṣọ́ Èrò Rẹ.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Sọ ọjọ́ tẹ́ ẹ máa lọ sí àpéjọ àyíká yín, tẹ́ ẹ bá ti mọ̀ ọ́n.
Orin 70 àti Àdúrà