Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àyíká
“Fífi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn Pẹ́kípẹ́kí” ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún àpéjọ àyíká ọlọ́jọ́ méjì tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní January. (2 Pét. 3:12) A ṣètò rẹ̀ láti ru ìmọ̀lára ìjẹ́kánjúkánjú wa sókè. Àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé yóò nírìírí ìdájọ́ Jèhófà láìpẹ́. Ta ni yóò la “ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” já? Kìkì àwọn tí ó ń bá a nìṣó láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí tí wọ́n sì ń gbé ọ̀nà ìgbésí ayé “ìṣe mímọ́ ní ìwà àti àwọn ìṣe ìfọkànsin Ọlọ́run.”—Ìṣí. 16:14; 2 Pét. 3:11.
Batisí ṣe pàtàkì fún ẹnì kan láti la ọjọ́ Jèhófà já. (1 Pét. 3:21) Kí àwọn akéde tí ó bá fẹ́ láti ṣe batisí ní àpéjọ náà sọ fún alábòójútó olùṣalága, ẹni tí yóò ṣe àwọn ètò tí ó pọn dandan.
Ọ̀rọ̀ àpínsọ alápá mẹ́rin, “Irú Ènìyàn Tí Ó Yẹ Kí A Jẹ́,” yóò fi irú ìwà tí ó yẹ kí a máa hù ní fífi wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí, hàn lọ́nà tí ó ṣe kedere. Ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn, “Ẹ Fi Ọgbọ́n Gbégbèésẹ̀ Bí Ọjọ́ Jèhófà Tí Ń Sún Mọ́lé,” yóò ṣàlàyé ohun tí ó túmọ̀ sí láti ‘wá Jèhófà, òdodo, àti ọkàn tútù,’ kí a lè là á já.—Sef. 2:3.
Àpéjọ àyíká náà yóò parí pẹ̀lú àwọn àsọyé méjì tí ń súnni ṣiṣẹ́ láti ẹnu àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní: “Ìgbésí Ayé Rẹ Ha Rọ̀gbà Yí Òtítọ́ Ká Bí?” àti “Wíwéwèé Ṣáájú Pẹ̀lú Ọjọ́ Jèhófà Lọ́kàn.” Àwọn àwíyé yìí yóò sún wa láti yẹ ìgbésí ayé wa wò kí a sì ṣe àtúnṣe èyíkéyìí tí ó pọn dandan. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ayé fi hàn kedere pé ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ yìí yóò fún wa níṣìírí láti ‘pa agbára ìmòye wa mọ́, kí a sì kíyè sára.’ (1 Pét. 5:8) Ṣe àwọn ètò tí ó ṣe gúnmọ́ láti pésẹ̀ ní ọjọ́ méjèèjì.