Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run
Àtúnyẹ̀wò pípa ìwé dé lórí àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún àwọn ọ̀sẹ̀ September 1 sí December 22, 1997. Lo abala tákàdá ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.
[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bíbélì nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí fúnra rẹ. Nọ́ńbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́ka tí a ṣe sí Ilé Ìṣọ́.]
Dáhùn Òtítọ́ tàbí Èké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
1. Ẹ́kísódù 21:22, 23 ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Ọlọ́run wo ọmọ tí a kò tí ì bí gẹ́gẹ́ bí ìwàláàyè kan tí ó ṣe iyebíye. [kl-YR ojú ìwé 128 ìpínrọ̀ 21]
2. Ní Lúùkù 22:30, “ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá” ní ìtumọ̀ kan náà bíi ti Mátíù 19:28, níbi tí ìfisílò rẹ̀ ti gbòòrò ré kọjá àwọn àlùfáà ọmọ abẹ́ Jésù tí a fi ẹ̀mí bí láti ní gbogbo aráyé yòó kù nínú. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w87-YR 3/1 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 10; ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 12.]
3. Ìdí tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi ṣe kàyéfì ní ti pé ó ń bá obìnrin ará Samáríà kan sọ̀rọ̀ jẹ́ nítorí pé ipò àtilẹ̀wá obìnrin náà jẹ́ ti oníwà pálapàla. (Jòh. 4:27) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 7/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 1 àti 2.]
4. Gbólóhùn náà, “láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀,” ní Jòhánù 6:64 fi hàn pé Jésù mọ̀ nígbà tí a yan Júdásì gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì pé òun ni yóò da Òun. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo gt-YR orí 55 ìpínrọ̀ 9.]
5. Gbígbádùn ìgbésí ayé ìdílé Kristẹni wulẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn pípa ìwà pálapàla ìbálòpọ̀ tì, kí a sì forúkọ ìgbéyàwó sílẹ̀ lábẹ́ òfin. [uw-YR ojú ìwé 139 ìpínrọ̀ 1]
6. Yálà a wo àwọn aláṣẹ gẹ́gẹ́ bí olódodo tàbí gẹ́gẹ́ bí aláìṣòdodo, àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ fi orúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lọ́nà tí ó tọ́ lọ́dọ̀ wọn. [kl-YR ojú ìwé 122 ìpínrọ̀ 11]
7. “Àjọyọ̀ . . . tí í ṣe ti àwọn Júù” tí a mẹ́nu kàn ní Jòhánù 5:1 tọ́ka sí Ìrékọjá ti ọdún 31 Sànmánì Tiwa. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo gt-YR orí 29.]
8. Bí olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa bá ṣẹ̀ wá, kì yóò tọ̀nà láti sénà mọ́ ẹni tí ó ṣẹ̀ wá náà nínú ìgbésí ayé wa, ní yíyẹra fún níní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú rẹ̀. [uw-YR ojú ìwé 134 ìpínrọ̀ 7]
9. Gbogbo wa nílò ìmọ̀ràn àti ìbáwí. [uw-YR ojú ìwé 130 ìpínrọ̀ 12]
10. Lúùkù kọ ìwé Ìṣe nígbà tí ó wà ní Éfésù. [w90-YR 5/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 3, 4]
Dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e yìí:
11. Báwo ni ó ṣe yẹ kí a lo ipò orí Kristẹni? [uw-YR ojú ìwé 142 ìpínrọ̀ 7]
12. Ní ìbámu pẹ̀lú àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ará Éfésù ti ọ̀rúndún kìíní, kí ni ìgbésẹ̀ kan tí ó pọn dandan tí a gbọ́dọ̀ gbé láti dènà àwọn ẹ̀mí búburú? (Ìṣe 19:19) [kl-YR ojú ìwé 114 ìpínrọ̀ 14]
13. Èé ṣe tí Jésù fi kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú awuyewuye ogún? (Lúùkù 12:13, 14) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w97-YR 4/1 ojú ìwé 28.]
14. Kí ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn kò mọ̀ nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ Jésù bí òun yóò bá dá Ìjọba pa dà fún Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Ìṣe 1:6? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w90-YR 6/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 4.]
15. Dárúkọ àwọn kókó méjì tí ó lè fi kún ìgbéyàwó tí ó wà pẹ́ títí. [uw-YR ojú ìwé 140 ìpínrọ̀ 4]
16. Báwo ni àwọn áńgẹ́lì kan ṣe dẹ́ṣẹ̀ ní ọjọ́ Nóà? [kl-YR ojú ìwé 109 ìpínrọ̀ 4]
17. Ní ìbámu pẹ̀lú ìwé Ìṣípayá, ibo ni “àwọn wọnnì tí ń bá ẹ̀mí lò” yóò ti dé òpin wọn nígbẹ̀yìngbẹ́yín bí wọn kò bá ronú pìwà dà kí wọ́n sì yí àwọn ọ̀nà wọn pa dà? [kl-YR ojú ìwé 112 ìpínrọ̀ 8]
18. Báwo ni Òfin Mósè ṣe “mú kí àwọn ìrélànàkọjá fara hàn”? (Gál. 3:19) [uw-YR ojú ìwé 147 ìpínrọ̀ 4]
19. Níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ ẹni pípé tí òun sì jẹ́wọ́ ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olùkọ́, èé ṣe tí kò fi gba pípè tí a pè é ní “Olùkọ́ Rere”? (Lúùkù 18:18, 19) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 3/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 7.]
20. Kí ni ó jẹ́ tuntun nípa àṣẹ tí a kọ sílẹ̀ ní Jòhánù 13:34? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w90-YR 2/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 5, 6.]
Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí a nílò láti parí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
21. Bí a bá mọ̀ pé arákùnrin wa ní ohun kan lòdì sí wa, ó ń béèrè _________________________ àti _________________________ láti lo ìdánúṣe kí a sì sakun láti mú _________________________ pa dà bọ̀ sípò. [uw-YR ojú ìwé 135 ìpínrọ̀ 10]
22. “Mínà mẹ́wàá” náà dúró fún _________________________ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí a fẹ̀mí bí lè lò láti mú _________________________ Ìjọba ọ̀run púpọ̀ sí i jáde. (Lúùkù 19:13) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 10/1 ojú ìwé 8.]
23. Ẹ̀sùn èké mẹ́ta tí àwọn Júù fi kan Jésù lọ́dọ̀ Pílátù, gómìnà Róòmù ti Jùdíà, ní nínú, dídojú _________________________ dé, dídánilẹ́kun sísan _________________________, àti sísọ pé Òun alára jẹ́ _________________________. (Lúùkù 23:2) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w90-YR 12/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 1.]
24. Ìfẹ́ wa fún àwọn arákùnrin wa lè ga sí i bí a bá sakun láti bo _________________________ kéékèèké tí wọ́n ní mọ́lẹ̀, kí a wá _________________________ rere tí wọ́n ní, kí a sì kíyè sí bí _________________________ ṣe ń lò wọ́n. [uw-YR ojú ìwé 137 ìpínrọ̀ 15]
25. Gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ láti lo àwọn atọ́ka tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ṣàwárí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀, a kò gbọ́dọ̀ retí _________________________ tàbí _________________________ sí gbogbo ìbéèrè, a sì gbọ́dọ̀ ṣe _________________________ tí ń fi ìfẹ́ wa fún _________________________ àti fún àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa hàn. [uw-YR ojú ìwé 144 ìpínrọ̀ 13]
Mú ìdáhùn tí ó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
26. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì tàbí họlidé èyíkéyìí mìíràn tí a gbé karí ìgbàgbọ́ ìsìn èké nítorí wọ́n ń fún Jèhófà ní (ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gédégbé; ìjọsìn tí kò pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ; ìjọsìn jíjinlẹ̀) wọn kì í kíyè sí àwọn họlidé pẹ̀lú, tí ń ṣe (ìsọdòrìṣà; ìgbélárugẹ, ìkókìkí) àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí orílẹ̀-èdè. [kl-YR ojú ìwé 126 ìpínrọ̀ 16]
27. Òtítọ́ tí ń sọ àwọn ènìyàn di òmìnira jẹ́ òtítọ́ nípa (sáyẹ́ǹsì; ìsìn èké; Jésù Kristi) nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ nìkan ni a fi lè dòmìnira kúrò lọ́wọ́ (àwọn ẹ̀kọ́ èké; ìgbékèéyíde ti ayé; ẹ̀ṣẹ̀ tí ń ṣekú pani). (Jòh. 8:12-36) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 5/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 5.]
28. “Àwọn àgùntàn míràn” tí a mẹ́nu kàn ní Jòhánù 10:16 tọ́ka sí (àwọn kèfèrí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni; àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ Kristẹni; gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí ìwàláàyè nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé). [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 4/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 4.]
29. Nígbà tí Jésù béèrè lọ́wọ́ àpọ́sítélì Pétérù pé, “Ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi ju ìwọ̀nyí lọ bí?,” Òun ń béèrè lọ́wọ́ Pétérù bí ó bá nífẹ̀ẹ́ Òun ju (bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòó kù wọ̀nyí; bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòó kù wọ̀nyí ṣe nífẹ̀ẹ́ Jésù; bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí, irú bí ẹja). (Jòhánù 21:15) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 11/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 9.]
30. Àní bí ikú rẹ̀ ti sún mọ́lé pàápàá, Jésù gẹ́gẹ́ bí (Olùṣọ́ Àgùntàn Rere; Olùkọ́ Rere; Àjàrà Tòótọ́) fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́, ó sì gbàdúrà nítorí wọn. (Jòh. 10:1-11) [w90-YR 3/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 2]
So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó tẹ̀ lé e yìí mọ́ àwọn gbólóhùn tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ìsàlẹ̀ yìí:
Ẹ́kís. 31:12, 13; Lúùkù 13:4, 5; Òwe 3:9, 10; Róòmù 7:6, 7; 2 Tím. 3:12
31. Jésù jiyàn lòdì sí ìrònú tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àyànmọ́, ní títọ́ka sí ọ̀ràn ìbànújẹ́ kan tí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ mọ̀ bí ẹni mowó, tí ó sì hàn gbangba pé òun so ó pọ̀ mọ́ ìgbà àti èèṣì. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w96-YR 9/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 5.]
32. A kò ní in lọ́kàn láé pé kí Òfin Mósè de gbogbo aráyé. [uw-YR ojú ìwé 147 ìpínrọ̀ 5]
33. Gbígbé tí a ń gbé ìgbésí ayé ìwà-bí-Ọlọ́run kì í ṣe ẹ̀rí ìdánilójú pé àwọn ènìyàn yóò bá wa lò lọ́nà tí ó dára ní gbogbo ìgbà. [kl-YR ojú ìwé 118 ìpínrọ̀ 2]
34. Nígbà tí a fagi lé Òfin Mósè, ó kan Òfin Mẹ́wàá pẹ̀lú. [uw-YR ojú ìwé 147 ìpínrọ̀ 5]
35. Jèhófà yóò bù kún wa bí a ti ń lo àkókò wa, okun wa, àti àwọn ohun àmúṣọrọ̀ míràn, títí kan owó wa, láti gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ. [kl-YR ojú ìwé 120 ìpínrọ̀ 8]