ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/97 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 12/97 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní December: Gẹ̀ẹ́sì—New World Translation pẹ̀lú ìwé náà, The Bible—God’s Word or Man’s? Ìfilọni àfidípò: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí Iwe Itan Bibeli Mi. Yorùbá—Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun pẹ̀lú ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Ìfilọni àfidípò: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí. Àwọn èdè yòó kù—Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Ìfilọni àfidípò: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, Iwe Itan Bibeli Mi, tàbí ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí. January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí a tẹ̀ sórí bébà tí ó máa ń di yẹ́lò tàbí tí ó máa ń di ràkọ̀ràkọ̀ tàbí èyíkéyìí tí a tẹ̀ ṣáájú 1985 ni a lè fi lọni ní ẹ̀dínwó. Bí ìjọ èyíkéyìí bá ní Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ lọ́wọ́, wọ́n lè fi ìtẹ̀jáde yìí lọni ní ẹ̀dínwó pẹ̀lú. Àwọn ìwé olójú ewé 192 yòó kù tí a tẹ̀ jáde ṣáájú 1985 tí a tẹ̀ sórí bébà tí kì í ṣá tàbí tí kì í di ràkọ̀ràkọ̀ ni a kò gbọ́dọ̀ fi kún ìfilọni ẹlẹ́dìn-ínwó yìí. Ìfilọni àfidípò: Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia,” Isopọṣọkan ninu Ijọsin Ọlọrun Tootọ Kanṣoṣo Naa, Lilaaja Sinu Ilẹ-ayé Titun, tàbí True Peace and Security—How Can You Find It? February: Revelation—Its Grand Climax At Hand! Ìfilọni àfidípò: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí ó ti pẹ́, tí ó wà lọ́wọ́. March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Pọkàn pọ̀ sórí bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. ÀKÍYÈSÍ: Kí àwọn ìjọ tí yóò bá nílò àwọn ìwé ìgbétáásì tí a mẹ́nu kàn lókè yí béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.

◼ Àwọn ìjọ tí ó ṣì ní Ìròyìn Ìjọba No. 35 lọ́wọ́ lè fún àwọn akéde níṣìírí láti fi wọ́n lọni lọ́nà tí a gbà ń fi àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú lọni, yálà láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà tàbí níbòmíràn. Bí ó bá bọ́gbọ́n mu, àwọn akéde lè fi ọ̀kan sílẹ̀ fún àwọn kò-sí-nílé, kí wọ́n rí i dájú pé àwọn tí ń kọjá lọ kò lè rí i. Kí a lo ìsapá láti pín gbogbo ẹ̀dà tí ó ṣẹ́ kù nínú ìhìn iṣẹ́ pàtàkì yí.

◼ Ó yẹ kí àwọn alàgbà bẹ̀rẹ̀ sí wéwèé ṣáájú nísinsìnyí fún àkànṣe ìgbétásì ìwé ìròyìn jákèjádò orílẹ̀ èdè yí ní December 25 àti 26. Kí a fún gbogbo ìjọ níṣìírí láti kópa nínú àkànṣe ìgbòkègbodò yí.

◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí òun yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní December 1 tàbí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó yá tó lẹ́yìn náà. Ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣe èyí.

◼ Ìṣe Ìrántí fún 1999 yóò jẹ́ ní Thursday, April 1, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. A pèsè ìsọfúnni ṣáájú yìí kí àwọn ará lè ṣètò tàbí ṣe àdéhùn tí ó pọn dandan fún àwọn gbọ̀ngàn tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó bí ìjọ tí ó pọ̀ bá ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó sì di dandan fún wọn láti wá àwọn ilé mìíràn. Kí àwọn alàgbà ṣe àdéhùn pẹ̀lú onílé láti rí i dájú pé àwọn ìgbòkègbodò míràn nínú ilé náà kì yóò fa ìyọnu kí a lè ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí náà ní àlàáfíà àti létòletò. Nítorí ìjẹ́pàtàkì ayẹyẹ náà, nígbà tí a bá fẹ́ yan ẹni tí yóò sọ ọ̀rọ̀ àsọyé Ìṣe Ìrántí, kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà yan ọ̀kan lára àwọn alàgbà tí ó tóótun dáadáa, dípò wíwulẹ̀ lo gbogbo alàgbà ní ìtòtẹ̀léra tàbí lílo arákùnrin kan náà lọ́dọọdún.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́